Leila Hadioui
Leila Hadioui | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | 16 Oṣù Kínní 1985 Casablanca, Morocco |
Orílẹ̀-èdè | Moroccan |
Iṣẹ́ | Actress, model, television presenter |
Ìgbà iṣẹ́ | 2007-present |
Leila Hadioui (tí wọ́n bí ní 16 Oṣù Kínní, Ọdún 1985) jẹ́ òṣèrébìnrin, afẹwàṣiṣẹ́ àti atọ́kùn ọmọ orílẹ̀-èdè Mòrókò.
Ìsẹ̀mí rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Wọ́n bí Hadioui ní ìlú Casablanca ní ọdún 1985.[1] Bàbá rẹ̀ tí n ṣe Noureddine Hadioui ni ó maá n pe ìrun fún mọ́ṣáláṣí Hassan II tí ó wà ní ìlú Casablanca.[2] Ó fẹ́ràn oge ṣíṣe láti ìgbà kékeré rẹ̀, tó sì maá wo àwọn ètò tẹlifíṣọ̀nù tí ó dá lóri oge ṣíṣe. Nígbà tí ó pé ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún, ó ṣe àkọ́kọ́ iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi afẹwàṣiṣẹ́. Hadioui fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ aṣàpẹẹrẹ fún ti ètò ìfihàn Caftan 2007. Ni ́ọdún 2007, ó dá ilé-ìtajà aṣọ àwọn obìnrin sílẹ̀.[3]
Ní ọdún 2010, Hadioui kópa nínu eré tẹlifíṣọ̀nù tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Les Enfants Terribles de Casablanca, èyítí Abdelkarim Derkaoui darí. [4] Ó ti ṣe atọ́kùn ti ètò oge kan tí wọ́n pè ní Sabahiyate. Ní ọdún 2014, ó kópa nínu sinimá tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Sara, èyítí Said Naciri darí. Ó ti hàn nínu àwọn sinimá àgbéléwò, eré alátìgbà-dègbà àti àwọn ètò ìfihàn lóri tẹlifíṣọ̀nù. Hadioui ti tarí síta pé òun kò fẹ́ràn láti máa ṣiṣé ní èyíkéyìí agbègbè tí ó bá tayọ ilẹ̀ Mòrókò.[5]
Hadioui ti ṣe ìgbéyàwó, ó sì ti bí ọmọbìnrin kan tí orúkọ rẹ̀ jẹ́ Ines ní ọdún 2005.[6][7]
Àṣàyàn àwọn eré rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- 2009 : 37 Kilomita Celsius
- Ọdun 2010 : Les Enfants Terribles de Casablanca
- 2011-2018 : Sabahiyat (TV jara)
- 2011 : Une Heure Enfer (jara TV)
- Ọdun 2014 : Sara
- 2017 : Awon Alake ajo
- 2017 : l'khawa (jara TV)
- 2018 : koriko lbehja
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ Saadi, Meryem (27 January 2014). _10705 "Leïla Hadioui : « Je suis bent darhoum »". Telquel (in French). Retrieved 2 November 2020.
- ↑ Dieseldorff, Karla (16 October 2015). "Moroccan Model Leila Hadioui Denounces Fake Social Media Profiles". Morocco World News. https://www.moroccoworldnews.com/2015/10/170554/moroccan-model-leila-hadioui-denounces-fake-social-media-profiles/. Retrieved 2 November 2020.
- ↑ "Leila Hadioui". 100 Femmes. Retrieved 2 November 2020.
- ↑ "Leila Hadioui". 100 Femmes. Retrieved 2 November 2020.
- ↑ Saadi, Meryem (27 January 2014). _10705 "Leïla Hadioui : « Je suis bent darhoum »". Telquel (in French). Retrieved 2 November 2020.
- ↑ Saadi, Meryem (27 January 2014). _10705 "Leïla Hadioui : « Je suis bent darhoum »". Telquel (in French). Retrieved 2 November 2020.
- ↑ Djebbar, Ghania (5 August 2020). "LA TOILE ACCUSE INES, FILLE DE LEILA HADIOUI, D'ÊTRE LESBIENNE, ELLE DÉMENT" (in French). Le360. https://fr.le360.ma/people/la-toile-accuse-ines-fille-de-leila-hadioui-detre-lesbienne-elle-dement-220661. Retrieved 2 November 2020.