Letekidan Micael

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Jump to navigation Jump to search
Letekidan Micael
Ọjọ́ìbíLetekidan Micael
1997
Eritrea
Orílẹ̀-èdèEritrean
Iṣẹ́Actress, choreographer, composer
Ìgbà iṣẹ́1995–present

Letekidan Micael (tí wọ́n bí ní ọdún 1997) jẹ́ òṣèrébìnrin ọmọ orílẹ̀-èdè Ẹritrẹ́à.[1] Ó gbajúmọ̀ fún ipa rẹ̀ tí ó kó gẹ́gẹ́ bi 'Awet' nínu fíìmù kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Feuerherz.[2][3][4]

Ọ̀rọ̀ ayé rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bi ní ọdún 1997 ní ìlú Asmara, orílẹ̀-èdè Ẹritrẹ́à.[5] Lẹ́hìn tí ó kópa nínu eré ológun tí a pe àkọ́lé rẹ̀ ní Feuerherz, àwọn ènìyàn kan fi ìwé ránṣẹ́ sí àwọn ẹbí rẹ̀ láti ṣe wọ́n ní ìjàmbá, èyí tí ó mú kí àwọn ìjọba orílẹ̀-èdè kan ní ilẹ̀ Yúróòpù ṣe ètò ààbò fún wọn.[6]

Iṣẹ́ ìṣe rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ní ọdún 2008, Micael kópa nińu eré tí a pe àkọ́lé rẹ̀ ní Feuerherz lọ́mọ ọdún mẹ́wàá.[7][8] Wọ́n kọ́kọ́ gbé fíìmù náà jáde ní Ọjọ́ 25 Oṣù Kẹẹ̀sán Ọdún 2008. Fíìmù náà dá lóri ogun tí orílẹ̀-èdè Ẹritrẹ́à jà pẹ̀lú Ethiópíà láti gba òmìnira. Àwọn ènìyàn sọ dáada nípa fíìmù náà tí wọ́n sì tún gbóríyìn fún Micael fún ipa rẹ̀ tí ó kó gẹ́gẹ́ bi 'Awet'.[9][10]

Àṣàyàn àwọn eré rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ọdún Fíìmù Ipa Ìtọ́kasí
2008 Feuerherz Awet

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "First sight: Letekidan Micael". The Guardian. Retrieved 19 October 2020. 
  2. "Letekidan Micael: Filmography". British Film Institute. Retrieved 19 October 2020. 
  3. "Letekidan Micael". MUBI. Retrieved 19 October 2020. 
  4. "Letekidan Micael: Schauspielerin". filmstarts. Retrieved 19 October 2020. 
  5. "First sight: Letekidan Micael". The Guardian. Retrieved 19 October 2020. 
  6. "First sight: Letekidan Micael". The Guardian. Retrieved 19 October 2020. 
  7. "Letekidan Micael films". epd-film. Retrieved 19 October 2020. 
  8. "Heart of Fire". Hollywood Reporter. Retrieved 19 October 2020. 
  9. "First sight: Letekidan Micael". The Guardian. Retrieved 19 October 2020. 
  10. "Letekidan Micael: Ratings". Rotten Tomatoes. Retrieved 19 October 2020.