Jump to content

Lilian Bach

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Lilian Bọlá Bach
Ọjọ́ìbí1970s
Erékùṣù Èkó, Nigeria
Ọmọ orílẹ̀-èdèNàìjíríà
Iléẹ̀kọ́ gígaUniversity of Lagos
Iṣẹ́Òṣèré-bìnrin, afẹwà ṣiṣẹ́ nígbà kan rí
Ìgbà iṣẹ́Ọdún 1997 sí 2013

Lilian Bọlá Bach jẹ́ gbajúmọ̀ ọ̀ṣẹ̀rè-bìnrin àti afẹwà ṣiṣẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[1]

Ìgbé ayé rẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ àti ìkẹ́kọ̀ọ́[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bí Bọlá tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Lilian ní Erékùṣù Èkó. Yorùbá ni màmá rẹ̀, tí bàbá rẹ̀ sìn jẹ́ ọmọ Poland.[2][3] Nítorí iṣẹ́ bàbá rẹ̀, ó gbé ní onírúurú ìlú lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà nígbà èwe rẹ̀. Ó kàwé àkọ́bẹ̀rẹ̀ ní Army Children's school, ní ìlú Port Harcourt, bẹ́ẹ̀ náà kàwé ní Ìdí Àràbà Secondary School, ní Ìpínlẹ̀ Ẹ̀kọ́. Ó kàwé gbàwé ẹ̀rí nínú ìmọ̀ iṣẹ́ tíátà ní University of Lagos [4][5] Bàbá rẹ̀ kú nígbà tí ó wà lọ́mọ ọdún mẹ́wàá [5]

Iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí afẹwà-ṣiṣẹ́ àti iṣẹ́ tíátà[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Lilian di gbajúmọ̀ afẹwà-ṣiṣẹ́ àwọn ọdún òǹkà 1990. Ó wà lára àwọn adíje àwọn Omidan tó rẹwà jùlọ ní Nàìjíríà, bẹ́ẹ̀ náà ló kópa nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìpolówó ọjà lórí ẹ̀rọ tẹlifíṣàn, èyí ló sọ ọ́ di Delta. Lọ́dún 1997 ló bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ sinimá àgbéléwò, tí ó sìn kópa nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ sinimá àgbéléwò lédè Yorùbá àti Gẹ̀ẹ́sì ni Nàìjíríà.[6]

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Lilian Bach exclusive". Golden icons. Retrieved 25 June 2014. 
  2. "Lilian Bach". Ghana visions. 4 November 2012. Retrieved 25 June 2014. 
  3. Ajibade Alabi (22 June 2014). "How I grew up in Lagos Ghetto-Lilian Bach". Daily Newswatch. Archived from the original on 26 June 2014. https://archive.is/20140626012708/http://www.mydailynewswatchng.com/grew-lagos-ghetto-lilian-bach/. Retrieved 25 June 2014. 
  4. "Celebrity Birthday:Lilian Bach". Nigeria films. Archived from the original on 25 July 2014. Retrieved 25 June 2014.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  5. 5.0 5.1 Ajibade Alabi (August 22, 2015). "Why I never won any beauty pageant – Lilian Bach". http://www.mynewswatchtimesng.com/why-i-never-won-any-beauty-pageant-lilian-bach/. Retrieved 1 September 2015. [Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
  6. "Lilian Bach. I have no regrets". Staerbroak news. Retrieved 25 June 2014.