Lola Akinmade Åkerström

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Jump to navigation Jump to search
Lola Akinmade Åkerström
Lolaakerstromheadshot-392x450.jpg
IbùgbéStockholm, Sweden
Iṣẹ́Photographer Travel writer

Lola Akinmade jẹ ayàwòrán àti akọ̀wé ọmọ Nàìjíríà.[1] Òun ni alatunse fún ilé iṣẹ́ Slow Travel Stockholm.[2] Àwọn iṣẹ́ rẹ tí farahàn nínú National Geographic Traveler, BBC àti CNN.[3][4]

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé àti ètò-ẹ̀kọ́ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ó gbé ní èkó ni Nàìjíríà nígbà di ìgbà tí ó pè ọmọ ọdún mẹẹdogun tí ó wà fi lọ sí orílẹ̀ èdè United States of America.[5] Ó gboyè master's nínú Information System ni ilé ẹ̀kọ́ gíga tí University of Maryland.[6][7] Ní ìgbà tí ó pé ọmọ ọdún mọ́kàndinlógún, wọn mú ní ilé ẹ̀kọ́ gíga tí University of Oxford, ṣùgbọ́n kò lọ nítorí kò rí owó san.[5] Ní ọdún 2006, ó lọ sí orile-ede Sweden pẹ̀lú ọkọ rẹ.

Iṣẹ́[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ó bẹ́ẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí oníróyìn orí pápá ni Eco-Challenge.[8] Ó si ṣẹ́ fún ọdún méjìlá pẹ̀lú GIS kí ó tó di ogbontarigi ayàwòrán. Ní ọdún 2006, ó darapọ̀ mọ́ Matador Network gẹ́gẹ́ bí alatunse. Ní oṣù kẹwàá ọdún 2009, ó fi ìṣe lẹ̀ ni GIS. Ní osu kẹfà ọdún 2011, ó kópa nínú ìdíje tí Quark Expedition gbé kalẹ̀ láti lè mú akọ̀wé tí ó má lọ sí Òpó tí ó wà ní Àríwá láti lè lọ kọ ìtàn nípa rẹ̀.[9] Ní ọdún 2012, ó kópa nínú eré tí wọn sá ni Fiji.[10]

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]