Jump to content

Louis Joseph César Ducornet

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Àwòrán Louis Joseph Cesar Ducornet, ní ọdún 1852

Louis Joseph César Ducornet (tí wọ́n bí ní ọjọ́ kẹwàá oṣù kìíní ọdún 1806 ní Lille, tí ó sì kú ní ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n oṣù kẹrin ọdún 1856 ní Paris) jẹ́ ayàwórán ti ìlú France, tó máa ń fi ẹsẹ̀ rè ya àwòrán.[1] Ó gbajúmọ̀ fún àwòrán rẹ̀ nípa ìwé Bíbélì àti àwòrán tó ní ṣe pẹ̀lú àwọn ẹ̀dá-ìtàn inú rẹ̀.

Ìgbésíayé rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bí Ducornet sínú ìdílé tálákà ní ọjọ́ kẹwàá oṣù kìínì ọdún 1806.[2] Bàbá Ducornet, tí ń ṣe Alexandre jẹ́ aránbàtà.[3] Ó ní àbàwọ́n ìbí tí àwọn olóyìnbó mọ̀ sí phocomelia, èyí tó jẹ́ pé kò ní apá tàbí itan, àfi ọmọ-ìka ẹsẹ̀ mẹ́rin sí ẹsẹ̀ ọ̀tún. Àbàwọ́n yìí ò jẹ́ kó lè rìn àfi tí wọ́n bá gbe. Àmọ́ bí ọ̀rọ̀ ṣe rí yìí, ó máa ń fi ẹsẹ̀ rẹ̀ mú èédú, tí á sì máa fi ya oríṣiríṣi nǹkan. Láti ìgbà èwe rẹ̀ ní àwọn òbí rẹ̀ tí ṣàkíyèsi ẹ̀bùn yìí. Èyí sì mú kí àwọn ènìyàn ní àdúgbò rẹ̀ fojú si lára, tí wọ́n á sì máa tọ́ ọ sọ́nà. [4]

Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ìṣèjọba agbègbè Lille, wọ́n rán an lọ Paris ní ọdún 1824,[5] níbi tí ó ti kẹ́kọ̀ọ́ lábẹ́ ìṣàkóso Guillaume Guillon-Lethière,[6] François Louis Joseph Watteau àti François Gérard. Lásìkò ìṣèjọba King Charles X, ó gba owó ìfẹ̀yìnti ọlọ́dọọdún, ti iye rẹ̀ wọ 1,200 francs.[6] Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àìlera ara rẹ̀ ò gbà á láyè láti kópa nínú ìdíje Prix de Rome, ó gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àmì-ẹ̀yẹ ní Salon. Kódà ó ní ọmọ ilé-ìwé tó ń kọ́, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Auguste Allongé. Ó ya àwòrán ẹsẹ̀ bàtà mọ́kànlá kan tí ó ga ti Mary Magdalene ní ẹsẹ̀ Jésù lẹ́yìn àjíǹde tí ìjọba ilẹ̀ France rà.

Ó kú ni Paris, ní ọdún 1856, ní ọmọdún àádọ́ta (50).[7]

Àwọn iṣẹ́ rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Lára àwọn àwòrán rẹ̀ tó gbajúmọ̀ ni:

  • Repentance. 1828.
  • The Parting of Hector and Andromaque. (Lille Museum.)
  • St. Louis administering Justice. (Lille Museum.)
  • Death of Mary Magdalen. 1840. ( Église Saint-André de Lille)
  • The Repose in Egypt. 1841.
  • Christ in the Sepulchre. 1843.
  • Edith finding the body of Harold. 1855.

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. "Paris, July 30". English Chronicle and Whitehall Evening Post: p. 4. 3 August 1824. 
  2. Ripley, George; Dana, Charles. A, eds (1874). The American Cyclopaedia: A Popular Dictionary of General Knowledge, Volume VI. New York: D. Appleton And Company. p. 292. https://books.google.com/books?id=ltYXAQAAIAAJ&pg=PA292. Retrieved 10 January 2024. 
  3. "Alexandre Amand Joseph Ducornée Mentioned in the Record of Louis Cesar Joseph Ducornée , in France, Nord, Parish and Civil Registration, 1524-1893: Lille. Birth Records 1805–1806, image 494,". 11 January 2024. Retrieved 11 January 2024 – via FamilySearch. 
  4. Ottley, Henry; Bryan, Michael, eds (1875). A Biographical And Critical Dictionary Of Recent And Living Painters And Engravers. Piccadilly: Chatto & Windus. p. 56. https://books.google.com/books?id=T5ZpAAAAcAAJ&pg=PA56. Retrieved 10 January 2024. 
  5. "Paris, Oct.22". Morning Herald: p. 2. 26 October 1824. 
  6. 6.0 6.1 Hardwicke's Annual Biography For 1857. London. 1857. p. 179. 
  7. "Died". Glasgow Courier: p. 3. 6 May 1856.