Love for Health Organisation (LHO)
Ìrísí
Love for Health Organisation (LHO) jẹ́ ajọ́ tí ó ń ṣe ìgbẹ́lárugẹ ìpoloi lórí ìlera láwùjọ. [1] Ó jẹ́ ajọ́ àkójọpọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ ètò-ìlera, ẹlẹ́yinjú-àánú, tí kìí ṣe ti ìjọba l'órílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, tí wọ́n máa ń ṣe ìgbẹ́lárugẹ ìpolongo lórí ìlera àti ìrànlọ́wọ́ ètò-ìlera ọ̀fẹ́ fún àwọn obìnrin àti àwọn aláìní láwùjọ káàkiri àgbáyé àti l'órílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Dókítà Yusuf Haroun, ọmọ orílẹ̀-èdè Nigeria tí ó fi America ṣ'èbùgbé ló dá a sílẹ̀ láti ma ṣe iìgbélárugẹ ètò ìlera àti ìrànlọ́wọ́ ètò ìlera fún àwọn obìnrin.[2][3][4] Ṣùgbọ́n ní báyìí, bí wọ́n ṣe ń ṣe ìrànlọ́wọ́ fún àwọn obìnrin, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń ṣe ìrànlọ́wọ́ fún àwọn aláìní káàkiri àgbáyé.
Love for Health Organization | |
---|---|
Abbreviation | LHO |
Legal status | Active |
Ibùjókòó | Amẹ́ríkà |
Yusuf Haroun | |
Website | lho-life.com/ |
Àwọn ètò wọn
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- Ìpèsè ètò ìlera ọ̀fẹ́ láti jẹ́ kí àwọn ènìyàn ní àǹfàní tó dára sí ètò ìlera àti ìbájáde rẹ̀.
- Ìṣègbè fún àwọn alámójútó ìwà-ipá sí obìnrin nípa ìmọ̀ràn, ìtọ́jú àti ìrànlọ́wọ́ ètò òfin.
- Ìpolongo fun ètò ìlera ìbímọ, èmi-ò-jùọ́-ìwọ-ò-jùmí takọtabo àti àwọn ẹ̀tọ́ obìnrin
- Pèsè àyè tó láàbò fún pínpín nǹkan, ìrànlọ́wọ́ àti àwọn ètò àti irinse ìlera
- Ní àjọṣepọ̀ láti ṣe iìgbélárugẹ ètò ìlera àti ṣe ìgbégidínà ìwà ipá sí obìnrin
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ Edema, Grace (2023-09-28). "Leadership empowerment aids creativity, says medical expert". Punch Newspapers. Retrieved 2024-02-18.
- ↑ Akinrefon, Dapo (2023-09-09). "Why FG must fund Biomedical Research in Nigeria---Medical Expert". Vanguard News. Retrieved 2024-10-02.
- ↑ "Love for health organisation unveils plan to address public health Issues in rural communities". The Nation Newspaper. 2024-08-24. Retrieved 2024-10-02.
- ↑ Koiki, Olusegun (2024-02-12). "Yusuf Haroun Shows Commitment to Health Equity, Catalysing Change – Independent Newspaper Nigeria". Independent Newspaper Nigeria – Breaking News from Nigeria and the World. Retrieved 2024-10-02.