Lynn Whitfield
Ìrísí
Lynn Whitfield | |
---|---|
Whitfield in 1999 | |
Ìbí | Lynn Butler-Smith 8 Oṣù Kejì 1953 Baton Rouge, Louisiana, U.S. |
Iṣẹ́ | Actress |
Awọn ọdún àgbéṣe | 1981–present |
(Àwọn) ìyàwó | Vantile Whitfield (m. 1974–1978) Brian Gibson (m. 1990–1992) |
Àwọn ọmọ | 1 |
Lynn Whitfield (orúkọ ìdílé Butler-Smith; ọjọ́ìbí February 8, 1953) ni òṣeré àti olóòtú ará Amẹ́ríkà. Whitfield bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìṣeré rẹ̀ ní orí tẹlifísàn àti tíátà, kó tó bẹ̀rẹ̀ sí ní seré nínú fílmù. Ó gba Ẹ̀bùn Primetime Emmy kan, wọ́n sì pè é lórúkọ fún Ẹ̀bùn Golden Globe fún idọ́n rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi Josephine Baker nínú eré dírámà tẹlifísàn The Josephine Baker Story (1991).
Whitfield ti kópa nínú àwọn fílmù bíi A Thin Line Between Love and Hate (1996), Gone Fishin' (1997), Eve's Bayou (1997), Stepmom (1998), Head of State (2003), Madea's Family Reunion (2006) àti The Women (2008). Ní 2016, bẹ̀rẹ̀ síní seré bíi Lady Mae Greenleaf nínú dírámà eré tẹlifísàn Oprah Winfrey Network tó únjẹ́ Greenleaf. Whitfield ti gba Ẹ̀bùn NAACP mẹ́je.