Jump to content

MaameYaa Boafo

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
MaameYaa Boafo
Orílẹ̀-èdèPakistani-Ghanaian
Iléẹ̀kọ́ gígaHood College
Rutgers University
Iṣẹ́Actress, comedian
Ìgbà iṣẹ́2012–present

MaameYaa Boafo Abiah (tí wọ́n bí ní ọdún 1980) jẹ́ òṣèrébìnrin àti apanilẹ́rìn-ín ọmọ orílẹ̀-èdè Pakístàn àti Ghánà.

Wọ́n bí Boafo ní orílẹ̀-èdè Pakístàn. Bàbá rẹ̀ ṣiṣẹ́ fún United Nations High Commissioner for Refugees.[1] Ó jẹ́ ẹ̀yà ti Ashanti ní orílẹ̀-èdè Ghánà.[2] Ó lo àwọn ìgbà ayé rẹ̀ ní àwọn orílẹ̀-èdè bíi Sudan, Ethiópíà, Geneva àti Kẹ́nyà.[3] Ní ọdún 2001, lẹ́hìn tí ó parí ẹ̀kọ́ girama rẹ̀, Boafo lọ sí Amẹ́ríkà láti kẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ èdè Faransé àti ìbáraẹnisọ̀rọ̀. Lẹ́hìn tí ó gba oyè-ẹ̀kọ́ láti Hood College ní ọdún 2005, ó tún gba owó ìrànlọ́wọ́ ìwé kíkà kan láti kẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ eré-ìtàgé ṣíṣe ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga Rutgers University. Ó gba oyẹ̀ gíga rẹ̀ ní ọdún 2019.[4] Boafo tún kẹ́kọ̀ọ́ fún bi oṣù mẹ́rin ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga Marc Bloch University tí ó wà ní ìlú Strasbourg, orílẹ̀-èdè Fráǹsì.

Boafo kó àkọ́kọ́ ipa rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi òṣèré nínu eré kan ti ọdún 2012 tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Asa, A Beautiful Girl.[5] Ní ọdún 2014, Boafo darapọ̀ mọ́ àwọn olùkópa eré An African City, níbi tí ó ti kó ipa Nana Yaa tí ó jẹ́ òṣìṣẹ́ agbéròyìn kan tí yíyálégbé rẹ̀ ní ìlú Accra nira fun gidigan. Ipa náà farapẹ́ ti Carrie Bradshaw nínu eré Sex and the City. Orí ẹ̀rọ ayélujára ni wọ́n ti gbé ṣe àyẹ̀wò Boafo fún ipa náà.[6] Ní ọdún 2014, Boafo kópa nínu eré oníṣókí kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Bus Nut. Wọ́n kọ́kọ́ gbé eré náà jáde níbi ayẹyẹ San Francisco Film Festival.[1]

Ní ọdún 2015, Boafo kó ipa kékeré kan nínu eré tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ The Family Fang. Ní ọdún 2016, ó kópa nínu àwọn eré oníṣókí kan tí àkọ́lé wọn jẹ́ New York, I Love You àti Olive.[7] Láti ọdún 2017 sí 2018, ó kó ipa bi Paulina nínu eré School Girls, èyítí wọ́n ṣe láti farapẹ́ eré míràn tí àkọ̀lé rẹ̀ jẹ́ Mean Girls.[8] Fún iṣẹ́ takuntakun rẹ̀, wọ́n yan Boafo fún àmì-ẹ̀yẹ Lucille Lortell Award àti Los Angeles Drama Circle Award fún òṣèré tí ó dára jùlọ, ó sì gba àmì-ẹ̀yẹ ti Drama Desk Award.[9] Ó kó ipa Abena Kwemo gẹ́gẹ́ bi alárùn HIV kan nínu eré Chicago Med.[10] Ní ọdún 2019, ó kópa gẹ́gẹ́ bi olùṣèwádìí kan nínu eré tẹlifíṣọ̀nù tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Bluff City Law.[11] Boafo tún kó ipa Zainab nínu eré tẹlifíṣọ̀nù ti ọdún 2020 tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ̀ Ramy.[12]

Boafo ti ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú Jeremiah Abiah, ó sì n gbé ní Ìlú New York.[13] Ó fẹ́ràn bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá. Boafo maá n sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì àti èdè Twi.[2]

Àṣàyàn àwọn eré rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  • 2012: Asa, A Beautiful Girl (Short film)
  • 2012: Tied and True (Short film)
  • 2012: Azure II (Short film)
  • 2013–2018: Thru 25 (TV series)
  • 2014: When It All Falls Down... (Short film)
  • 2014: Madam Secretary (TV series)
  • 2014–present: An African City (TV series)
  • 2014: Bus Nut (Short film)
  • 2014–2015: Deadstar (TV series)
  • 2015: American Odyssey (TV series)
  • 2015: The Family Fang
  • 2015: The Blacklist (TV series)
  • 2015: The Mysteries of Laura (TV series)
  • 2016: New York, I Love You (Short film)
  • 2016: Olive (Short film)
  • 2016: Conversating While Black (TV series)
  • 2016: Beyond Complicated (TV series)
  • 2017: Where Is Kyra?
  • 2017: Iron Fist (TV series)
  • 2017: The Blue Car (Short film)
  • 2017: Ibrahim (Short film)
  • 2018: Chicago Med (TV series)
  • 2019: Theater Close Up (TV series)
  • 2019: Bluff City Law (TV series)
  • 2020: Ramy (TV series)
  • 2021: The Mysterious Benedict Society (TV series)

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. 1.0 1.1 "MaameYaa Boafo, la diva de la websérie " An African City "". https://www.lemonde.fr/afrique/article/2015/05/15/maameyaa-boafo-la-diva-de-la-webserie-an-african-city_4634409_3212.html. Retrieved 2 November 2020. 
  2. "An African "Sex and the City"". http://amsterdamnews.com/news/2014/oct/13/african-sex-and-city/?harlem-focus. Retrieved 2 November 2020. 
  3. "MaameYaa Boafo Bio". Broadway World. Retrieved 2 November 2020. 
  4. "Briana Johnson". NBC. Retrieved 2 November 2020. 
  5. "Interview: 'An African City' Star MaameYaa Boafo". https://www.okayafrica.com/an-african-city-maameyaa-boafo-interview/. Retrieved 2 November 2020. 
  6. Forson, Viviane (7 March 2016). "Diaspora - Télévision - MaameYaa Boafo : il faut s'affirmer tel que l'on est" (in French). Le Point. http://afrique.lepoint.fr/culture/television-ghana-maameyaa-boafo-une-femme-aux-antipodes-07-03-2016-2023519_2256.php. Retrieved 2 November 2020. 
  7. Green, Jesse (16 November 2017). "Review: 'School Girls' Is a Gleeful African Makeover of an American Genre". The New York Times. https://www.nytimes.com/2017/11/16/theater/school-girls-or-the-african-mean-girls-play-review.html. Retrieved 2 November 2020. 
  8. Isama, Antoinette (19 May 2019). "'An African City' and 'School Girls' Star MaameYaa Boafo Lands Role in New NBC Legal Drama". OkayAfrica. https://www.okayafrica.com/an-african-city-and-school-girls-star-maameyaa-boafo-lands-role-in-new-nbc-legal-drama/. Retrieved 2 November 2020. 
  9. Coulston, John Connor (3 January 2018). "'Chicago Med' Takes on HIV in Latest Episode". Popculture.com. https://popculture.com/tv-shows/news/chicago-med-hiv-episode-mountains-and-molehills/. Retrieved 2 November 2020. 
  10. Isama, Antoinette (19 May 2019). "'An African City' and 'School Girls' Star MaameYaa Boafo Lands Role in New NBC Legal Drama". OkayAfrica. https://www.okayafrica.com/an-african-city-and-school-girls-star-maameyaa-boafo-lands-role-in-new-nbc-legal-drama/. Retrieved 2 November 2020. 
  11. Ali, Lorraine (17 June 2020). "Struggling Ramy character makes for smart humor amid questions of faith, commitment". Los Angeles Times. https://www.latimes.com/entertainment-arts/tv/story/2020-06-17/ramy-youssef-mahershala-ali-hulu. Retrieved 2 November 2020. 
  12. "2005: Summer Update 2014". Hood College. Retrieved 2 November 2020. [Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]

Àwọn ìtakùn Ìjásóde

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]