Jump to content

Magaajyia Silberfeld

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Magaajyia Silberfeld
Silberfeld in 2019
Ọjọ́ìbí30 Oṣù Kẹjọ 1996 (1996-08-30) (ọmọ ọdún 28)
Paris
Orílẹ̀-èdèFrench-Nigerien
Iṣẹ́Film director, actress

Sarah Magaajyia Silberfeld (tí a bí ní 30 Oṣù Kẹẹ̀jọ, Ọdún 1996) jẹ́ òṣèrébìnrin àti olùdarí eré ọmọ orílẹ̀-èdè Nijer àti Fránsì

Silberfeld jẹ́ ọmọ sí olùdarí eré táa mọ̀ sí Rahmatou Keïta àti oníṣẹ́ ìròyìn Antoine Silber.[1] Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ eré ìtàgé ní agbègbè rẹ̀ nígbà tó wà lọ́mọ ọdún mọ́kànlá. Silberfeld dàgbà ní orílẹ̀-èdè Fránsì, ṣùgbọ́n ó maá n rìn ìrìn-àjò nígbàgbogbo lọ sí orílẹ̀-èdè Gíríìsì, Nìjẹ̀r, àti Málì, bẹ́ẹ̀ ló sì tún gbé ní ìlú Los Angeles fún ọdún mẹ́ta.[2] Ó kó àkọ́kọ́ ipa fíìmù rẹ̀ ní ọdún 2011 nínu eré tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ La Lisière.[3] Silberfeld kẹ́kọ̀ọ́ eré ṣíṣe ní ilé-ẹ̀kọ́ <i>Lee Strasberg Institute</i> ní ọdún 2013, àti ní Playhouse West Repertory Theatre ní ọdún 2014 àti ní Susan Batson Studio ní ọdún 2015.[4][5] Nígbà tó wà lọ́mọ ọdún méjìdínlógún, ó kọ àkọ́kọ́ eré oníṣókí rẹ̀ tó sì tún darí rẹ̀. Yàtò sí eré rẹ̀ tí ó kọ tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Me There, ó tún darí eré Ride or Die, èyítí ó ṣàfihàn Piper de Palma àti Roxane Depardieu.[6]

Ní ọdún 2016, Silberfeld ní àkọ́kọ́ ipa Olú-ẹ̀dá-ìtàn nínu eré The Wedding Ring, eré tí ìyá rẹ̀ darí. Ó kópa gẹ́gẹ́ bi Tiyaa, ọmọbìnrin kan tí ó lọ kàwé ní Ìlú Fránsì níbití ó ti pàdé tó sì yó fún ìfẹ́ ọmọkùnrin kan.[7] Fíìmù náà jẹ́ àkọ́kọ́ fíìmù ti orílẹ̀-èdè Nìjẹ̀r tó jẹ́ wíwò níbi àwọn ayẹyẹ Academy Awards.[8] Ní ọdún 2017, ó ṣe adarí fíìmù oníṣókí kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Vagabonds, èyítí ó ṣàfihàn Danny Glover.[9] Ní ọdún kan yìí náà ní Silberfeld gba oyè-ẹ̀kọ́ láti ilé-ẹ̀kọ́ gíga Sorbonne.[10] Ní àkókò ìgbà tó fi wà ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga, ó kọ èdè Gẹ̀ẹ́sì nípasẹ̀ wíwo àwọn fíìmù Amẹ́ríkà.[11]

Àṣàyàn àwọn eré rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  • 2011: La Lisière (actress)
  • 2014: Me There (short film, co-writer/director)
  • 2015: Ride or Die (short film, co-director)
  • 2016: The Wedding Ring (actress)
  • 2017: Vagabonds (short film, writer/director)

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. Arnaud, Megan (18 March 2019). "Le fardeau de la couleur de peau" (in French). https://www.letemps.ch/culture/fardeau-couleur-peau-0. Retrieved 4 October 2020. 
  2. Movia, Léa (26 January 2017). "Interview de Magaajyia Silberfeld, réalisatrice et actrice". Les Petits Frenchies (in French). Archived from the original on 21 October 2020. Retrieved 4 October 2020. 
  3. "Magaajyia Silberfeld". Africultures (in French). Retrieved 4 October 2020. 
  4. "Comédiennes - Magaajyia Silberfeld". FilmTalents.com (in French). Archived from the original on 22 February 2018. Retrieved 4 October 2020. 
  5. Martin, Marie-Claude (18 March 2019). "Le FIFF offre une carte blanche à 16 actrices noires et métisses". RTS (in French). Retrieved 4 October 2020. 
  6. "Magaajyia Silberfeld". African Film Festival. Retrieved 4 October 2020. 
  7. Movia, Léa (26 January 2017). "Interview de Magaajyia Silberfeld, réalisatrice et actrice". Les Petits Frenchies (in French). Archived from the original on 21 October 2020. Retrieved 4 October 2020. 
  8. Faivre, Agnès (12 April 2018). "Cinéma - Oscars 2019 : « Zin'naariyâ ! » de Rahmatou Keïta dans la course" (in French). https://www.lepoint.fr/culture/cinema-oscars-2019-zin-naariya-de-rahmatou-keita-dans-la-course-03-12-2018-2276300_3.php. Retrieved 4 October 2020. 
  9. Movia, Léa (26 January 2017). "Interview de Magaajyia Silberfeld, réalisatrice et actrice". Les Petits Frenchies (in French). Archived from the original on 21 October 2020. Retrieved 4 October 2020. 
  10. Karolle, Vane (3 April 2017). "Radar - Magaajyia Silberfeld". Archived from the original on 23 October 2020. https://web.archive.org/web/20201023235546/https://www.globetrottermag.com/news-features/2017/4/3/magaajyia-silberfeld. Retrieved 4 October 2020. 
  11. Movia, Léa (26 January 2017). "Interview de Magaajyia Silberfeld, réalisatrice et actrice". Les Petits Frenchies (in French). Archived from the original on 21 October 2020. Retrieved 4 October 2020. 

Àwọn ìtakùn Ìjásóde

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]