Jump to content

Majdouline Idrissi

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Majdouline Idrissi
Ọjọ́ìbí10 Oṣù Kẹta 1977 (1977-03-10) (ọmọ ọdún 47)
Rabat
Orílẹ̀-èdèMoroccan
Iṣẹ́Actress, comedian
Ìgbà iṣẹ́2003-present
Olólùfẹ́Aziz Hattab (m. 2019)

Majdouline Idrissi (tí wọ́n bí ní 10 Oṣù Kẹẹ̀ta, Ọdún 1977) jẹ́ òṣèrébìnrin àti apanilẹ́ẹ̀rín ọmọ orílẹ̀-èdè Mòrókò.

Wọ́n bí Idrissi ní ìlú Rabat ní ọdún 1977.[1] Idrissi fẹ́ràn láti máa jíjó ballet, èyí tí ó mú kí ó forúkọsílẹ̀ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ nípa ijó ballet náà ní àkókò ìgbà tí ó wà lọ́mọ ọdún mẹ́rin. Nígbà tí ó pé ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún, ó lọ sí ìlú Montreal láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìṣàkóso òwò. Ó bẹ̀rè sí ní ìfẹ́ sí ṣíṣe eré sinimá lẹ́hìn tí ó tẹ̀lé ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan lọ sí ibi ìdíjẹ eré ìtàgé kan.[2] Ní ọdún 2003, ó kó àkọ́kọ́ ipa fíìmù rẹ̀ nínu eré El Bandia.[3] Ó kópa gẹ́gẹ́ bi Habiba nínu fíìmù ti ọdún 2006 kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ La Symphonie marocaine tí olùdarí eré náà síì jẹ́ Kamal Kamal.[4] Idrissi kó ipa Jamila nínu fíìmù ti ọdún 2009 kan tí Souad Hamidou ṣe tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Camille and Jamila. Ó kó ipa Rihanna, gẹ́gẹ́ bi ọmọbìnrin aláìsàn kan nínu eré Pégase ní ọdún 2010, èyítí ó ṣokùn fa gbígba àkọ́kọ́ àmì-ẹ̀yẹ rẹ̀. Ní ọdún 2016, Idrissi tún kó ipa Myriam, nínu eré Divines, eré tí Houda Benyamina darí. Eré náà gba àmì-ẹ̀yẹ ti Caméra d'Or níbi ayẹyẹ Cannes Film Festival.[5]

Ní Oṣù Kọkànlá, Ọdún 2019, Idrissi ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú òṣèrékùnrin Aziz Hattab . Àwọn méjéèjì ti dìjọ ṣiṣẹ́ papọ̀ rìí ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà nínu àwọn eré tẹlifíṣọ̀nù àti sinimá àgbéléwò tó fi mọ́ La Symphonie marocaine àti Daba tazyan, níbi tí wọ́n ti kópa gẹ́gẹ́ bi tọkọtaya.[6]

Àṣàyàn àwọn eré rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  • 2003 : El Bandia
  • 2006 : La Symphonie marocaine : Habiba
  • 2009 : Camille and Jamila : Jamila
  • 2010 : Pégase : Rihanna
  • 2011 : Sur la route du paradis : Leila
  • 2013 : Sarirou al assrar
  • 2013 : Youm ou lila
  • 2014 : L'Orchestre des aveugles : Fatima
  • 2014 : Itar el-layl : Nadia
  • 2016 : Divines : Myriam
  • 2017 : Au pays des merveilles
  • 2019 : Doumoue Warda
  • 2020 : Daba tazyan (TV series)

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. "Majdouline Idrissi". Africultures (in French). Retrieved 22 October 2020. 
  2. "Majdouline Idrissi : «Je cherche un vrai homme plein de virilité»". 21 February 2010. https://aujourdhui.ma/culture/majdouline-idrissi-je-cherche-un-vrai-homme-plein-de-virilite-91270. Retrieved 22 October 2020. 
  3. "Majdouline Idrissi". Africultures (in French). Retrieved 22 October 2020. 
  4. Chabaa, Qods (5 November 2019). "L'acteur Aziz Hattab et la comédienne Majdouline Idrissi convolent en justes noces". Le360 (in French). Retrieved 22 October 2020. 
  5. "Majdouline Idrissi". Africultures (in French). Retrieved 22 October 2020. 
  6. Chabaa, Qods (5 November 2019). "L'acteur Aziz Hattab et la comédienne Majdouline Idrissi convolent en justes noces". Le360 (in French). Retrieved 22 October 2020. 

Àwọn ìtakùn Ìjásóde

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]