Jump to content

Mandera triangle

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Mandera triangle jẹ́ àgbègbè kan ní Ìlaòrùn Áfríkà níbi tí Ethiopia, Kenya àti Somalia ti pàdé.[1] Agbègbè náà wà ní ìlú ManderaMandera County.[2][3]

Ọ̀pọ̀lopọ̀ awọn olùgbé àgbègbè náà jé ará Somalia.[4] Àwọn olùsọ́ àgùntàn ma ń gbs ibè kọjá láti wá omi àti oúnjẹ fún àwọn ẹranko wọn.[5] Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìjà sì ni ó ma ń ṣẹlẹ̀ níbè nítorí ìjà abẹ́lé tí ó ń ṣẹlẹ̀ ní Somalia, ìjà láàrin àwọn ológun Ethopia àti àwọn agbẹ́bon ní Somalia, Ìjà láàrin ẹ̀yà, kíkó àwọn ǹkan ọ̀sìn láàrin àwọn ada ẹranko àti àwọn ǹkan míràn ló mú kí United States Department of State ṣe àgbéjáde pé ibè jẹ́ ara àwọn ibi tí wàhálà tí ń ṣẹlẹ̀ jù ní àgbáyé.[2]

Wọ́n ní pé àwọn ǹkan ogun tí wón gbé wá láti orílẹ̀ èdè Yemen dé sí Somalia, wọ́n sì gbé wọn gba Mandera triangle kí wọ́n tó gbé wọn lọ àwọn orílẹ̀ èdè Áfríkà miran.[1]

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. 1.0 1.1 Ward, Olivia (March 1, 2009). "Somalia a land of chaos, awash in weapons". TheStar.com. Toronto Star. Retrieved August 28, 2009. 
  2. 2.0 2.1 U.S. Department of State, Humanitarian Information Unit. WebVISTA Prototype 1: Greater Mandera Triangle Conflict Incident Vista Archived 2009-10-01 at the Wayback Machine.. Retrieved August 28, 2009.
  3. Library of Congress Map Collection. Retrieved August 28, 2009.
  4. Human Rights Watch. Bring the Gun or You'll Die: Torture, Rape, and Other Serious Human Rights Violations by Kenyan Security Forces in the Mandera Triangle. June 29, 2009. Retrieved August 28, 2009.
  5. USAID/East Africa. Regional Enhanced Livelihood in Pastoral Areas (RELPA)[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́] Retrieved August 28, 2009.