Jump to content

Mare Dibaba

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Mare Dibaba
Dibaba in the 2014 Boston Marathon
Òrọ̀ ẹni
Ọjọ́ìbí20 Oṣù Kẹ̀wá 1989 (1989-10-20) (ọmọ ọdún 35)
Oromia Region, Ethiopia
Height1.51 m (4 ft 11+12 in)
Weight38kg
Sport
Orílẹ̀-èdè Ethiopia
Erẹ́ìdárayáAthletics (sport)
Event(s)Marathon

Mare Dibaba Hurrsa ni a bini ọjọ ogun, óṣu October ni ọdun 1989 jẹ elere sisa lóbinrin to da lori ọna jinjin[1][2][3].

Ni ọdun 2007, Dibaba kopa ninu idije ti ilẹ Ethiopia to si gbe ipo kẹfa ni bi to ti sare fun ọlọpa ti Oromia. Ni ọdun 2008, Dibaba kopa ninu Idaji Marathon ti New Delhi to si gbe ipo kẹjọ pẹlu wakati 1:10:28. Ni ọdun 2009, Dibaba kopa ninu Idaji Marathon ti Delhi to si gbe ipo kẹfa pẹlu wakati 1:08:45[4]. Ni óṣu February, Mare pari pẹlu ipo kẹta ninu Idaji Marathon ti Ras Al Khaimah[5]. Ni ọdun 2011, Dibaba ṣoju fun órilẹ ede rẹ ninu ere gbogbo ilẹ Afirica to si gba ami ẹyẹ ti ọla ti wura pẹlu wakati 1:10:47[6]. NI óṣu October, ọdun 2011, Dibaba kopa ninu Marathon ti Toronto to si pari pẹlu ipo keji pẹlu wakati 2:23:25[7]. Ni ọdun 2012, Mare kopa ninu Marathon ti ilẹ Dubai pẹlu wakati 2:19:52 to si pari pẹlu ipo kẹta. Ni ọdun 2012, Dibaba kopa ninu Idaji Marathon ti Philadelphia to si pari pẹlu ipo keji[8]. Ni ọdun 2014, Mare yege ninu Marathon ti ile ifowopamọ ilẹ America ti Chicago pẹlu wakati 2:25:37. Mare kopa ninu Marathon ti idije agbaye to waye ni ọdun 2015 ni ilẹ Beijing.

  1. Mare Biography
  2. Mare Dibaba
  3. Mare Dibaba Profile
  4. New Delhi Half Marathon
  5. Ras Al Khaimah Marathon
  6. All Africa Games Results
  7. Toronto Marathon
  8. Philadelphia Half Marathon