Margaret Legum
Margaret Jean Roberts Legum (tí wọ́n bí ní ọjọ́ kẹjọ oṣù kẹwàá ọdún 1933, sí ìlú Pretoria, South Africa, tí ó sì ṣaláìsí ní ọjọ́ kìíní oṣù kọkànlá ọdún 2007, sí ìlú Cape Town, South Africa) fìgbà kan jẹ́ ajàfétọ̀ọ́ ẹlẹ́yàmẹyà ti orílẹ̀-èdè South African àti a-tún-àwùjọ-ṣe, tí iṣé rẹ̀ dá lórí ìmọ̀ ìṣòwò.
Legum lọ sí Rhodes University àti Newnham College, níbi tí ó ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìmọ̀ ìṣòwò.[1] Orúkọ ọkọ Legum ni Colin Legum, wọ́n sì fé ara wọn ni ọdún 1960, tí wọ́n sì kó lọ sí ìlú London.[1]
Margaret Legum kú ní ọdún 2007, ní ọmọdún mẹ́rìnléláàádọ́rin (74), látàrí àrùn jẹjẹrẹ. Ó ní àwọn ọmọbìnrin mẹ́ta àti ọ̀pọ̀ ọmọ-ọmọ.[2]
Iṣẹ́ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Legum ni olùdásílẹ̀ South African New Economics Network.[3] Ìwẹ́ rẹ̀, ìyẹn, It Doesn't Have To Be Like This: Global Economics - A New Way Forward (2003), jẹ́ èyí tó kọ látàrí àwọn ìdánilẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ní University of Cape Town.[4]
Ó gbajúmọ̀ fún ìwé tí ó kọ ní ọdún 1963, tó dá lórí pàtàkì ìjẹniníyà ajẹmówò tó ń bá South Africa jìjà kadì. Àkọ́lé rẹ̀ ni South Africa: Crisis for the West, tí ó kọ pẹ̀lú ọkọ rẹ̀, Colin.[5]
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ 1.0 1.1 Herbstein, Denis (16 November 2007). "Margaret Legum". The Guardian. https://www.theguardian.com/news/2007/nov/16/guardianobituaries.southafrica.
- ↑ Kharsany, Zahira (2 November 2007). "Journalist Margaret Legum Passes Away". Mail & Guardian. http://mg.co.za/article/2007-11-02-journalist-margaret-legum-passes-away.
- ↑ Àdàkọ:Cite ODNB
- ↑ Hudson, Marc (December 2005). "Margaret Legum, 'It doesn't have to be like this: Global economics - a new way forward'". Peace News. http://peacenews.info/node/5001/margaret-legum-it-doesnt-have-be-global-economics-new-way-forward.
- ↑ "Margaret Legum". The Scotsman. 7 November 2007. http://www.scotsman.com/news/obituaries/margaret-legum-1-698625.