Maria Stepanova (Akewi)

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Àwòrán Maria Mikhailovna Stepanova

Maria Mikhailovna Stepanova (ọmọ orílẹ̀-èdè Russia: Мари́я Миха́йловна Степа́нова; tí a bí ní osù kẹfà ọjọ́ 9, ọdún 1972) jẹ́ akéwì ará ìlú Russia, òǹkọ̀wé, àti oníròyìn. Ó jẹ́ olóòtú ti Coltra.ru lọ́wọ́lọ́wọ́, èyí tó jẹ́ ìwé àtẹ̀jáde orí ayélujára tí ó dá lórí àṣà àti iṣẹ́-ọnà. Ní ọdún 2005, ó gba àmì-ẹ̀yẹ Andei Bely fún ewì kíké. Láìpẹ́, ó tún gba ẹ̀bùn ti 2017-2018 oníwèé ńlá fún ìtàn àròsọ rẹ̀, tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ In Memory of Memory (Pamyati pamyati) .

Ìtàn Ìgbésíayé rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Stepanova tí a bí ní Moscow ní oṣù kẹfà ọjọ́ 9, ọdún 1972, kàwé gboyè ní Maxim Gorky Literature Institute, lọ́dún 1995. Ó ṣe àtẹ̀jáde àwọn ewì nínú àwọn ìwé-ìròyìn pẹ̀lú èdè Russia. Àpẹẹrẹ irú́fẹ́ ewì bẹ́ẹ̀ ni Zerkalo, Znamya, Kriticheskaya massa, àti Novoe Literaturnoe Obozreniye, àti nínú àwọn ìtàn òwúlẹ̀wútàn bíi Babylon, Urbi, àti Ulov. Stepanova ti gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹ̀bùn pàtàkì fún ìwé-kíkọ ti ìlú Russia, pẹ̀lú ẹ̀bùn Pasternak àti ẹ̀bùn Andrei Bely ní ọdún 2005, ati ẹ̀bùn ti ìlú Moscow ní ọdún 2006, 2009, àti 2018.[1][2]

Ní ọdún 2007, Stepanova ṣe ìdásílẹ̀ Openspace.ru, tó jẹ́ ìwé-ìròyìn orí ayélujára tí ó ṣe ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ fún àṣà àti iṣẹ́-ọnà Russiae. Per Stepanova, ìwé ìròyìn náà "yóò pèsè àwọn olùgbọ́ pẹ̀lú ohun-èlò ìgbàlódé, to pé, àti èyí tó ṣe é fìtara wò lórí ohun tí ń ṣẹlẹ̀ nínú àṣà Russia àti ní ìta lọ́hùnún."[3] Ó ṣiṣẹ́ olóòtú-àgbà ní Openspace.ru títí di ọdún 2012, nígbà tí ó yọwọ́ kúrò nínú àtẹ̀jáde náà pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ olóòtú rẹ̀ nítorí ìṣòro àìrónídòókòwò, láti àwọn ilé-iṣẹ́ àdáni.[4]

Wọ́n ti ṣe ògbufọ̀ àwọn iṣẹ́ Stepanova sí èdè Gẹ̀ẹ́sì, Hebrew, Spain, Italy, German, Finnish, French àti àwọn èdè mìíràn. Wọ́n tún yàn àn gẹ́gé bíi ọ̀jọ̀gbọ́n àlejò ti Siegfried-Unseld ní Humboldt Universität ni Berlin fún ọdún 2018 – 2019.[5]

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Maria Stepanova – Joseph Brodsky". www.josephbrodsky.org. Retrieved 2020-11-11. 
  2. "Мария Степанова | Новая карта русской литературы". www.litkarta.ru. Retrieved 2020-11-11. 
  3. University, Stanford (2016-03-29). "Moscow journalist Maria Stepanova to speak about Russia's future". Stanford News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-11-11. 
  4. "Colta.ru | Всё о культуре и духе времени". www.colta.ru. Retrieved 2020-11-11. 
  5. "Berliner Künstlerprogramm". www.berliner-kuenstlerprogramm.de. Archived from the original on 2020-11-18. Retrieved 2020-11-11.