Marina Niava
Marina Niava | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | 1985 (ọmọ ọdún 38–39) |
Orílẹ̀-èdè | Ivorian |
Iṣẹ́ | Film director, producer, screenwriter |
Ìgbà iṣẹ́ | 2009-present |
Marina Niava (tí wọ́n bí ní ọdún 1985) jẹ́ olùdarí eré, agbéréjáde àti ònkọ̀tàn ọmọ orílẹ̀-èdè Côte d'Ivoire.
Ìsẹ̀mí rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Niava ni àbígbẹ̀yìn àwọn òbí rẹ̀ tí wọ́n ṣe Pierre àti Cécile Niava. Olùkọ́ akọ́nilédè ni àwọn òbí rẹ̀ méjéèjì.[1] Ó gba oyè-ẹ̀kọ́ láti ilé-ẹ̀kọ́ gíga Lycée Sainte Marie d'Abidjan, tó sì tún gba àmì-ẹ̀yẹ Series A Excellence Award fún píparí ẹ̀kọ́ rẹ̀ lọ́nà tó peregedé. Lẹ́hìn tí ó gba oyè-ẹ̀kọ́ nínu ìmọ̀ ìgbéróyìn láti ilé-ẹ̀kọ́ gíga Institut des Sciences et Techniques de la Communication, Niava gbégbá orókè níbi ìdíje kan tí ilé-iṣẹ́ Radio JAM ṣe ní ìlú Abidjan. Ó ṣiṣẹ́ agbéròyìn fún ilé-iṣẹ́ Africa 24.[2] Niava bẹ̀rẹ̀ sí ní ní ìfẹ́ sí iṣẹ́ sinimá nígbà kan tí ó fi ṣiṣẹ́ lóri ìpolówó ọjà kan.[3]
Láti ọdún 2009 sí 2010, Niava ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́bi ònkọ̀tàn fún abala àkọ́kọ́ ti eré tẹlifíṣọ̀nù alátìgbà-dègbà tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Teenager, èyítí ó gba àmì-ẹ̀yẹ gẹ́gẹ́ bi eré alátìgbà-dègbà tí ó dára jùlọ ní ilẹ̀ Áfríkà níbi ayẹyẹVues d'Afrique Festival tí ó wáyé ní ìlú Montreal. Ó kó lọ sí ìlú Oslo, ní orílẹ̀-èdè Nórwèy ní ọdún 2010 tó sì di ọ̀gá ní ẹ̀ka ìbaraẹnisọ̀rọ̀ ti ilé-iṣẹ́ African Cultural Center. Niava ṣe aláàmójútó àjọ̀dún Kino Afrika Film Festivals ti ọdún 2010 àti 2011 ní ìlú Oslo.[4] Ó gba àmì-ẹ̀yẹ níbi ètò BENIANH International Foundation's Excellent Scholarship Program ní ọdún 2012.[5]
Ní Oṣù Kẹẹ̀wá ọdún 2012, ó ṣe adarí fíìmù ìrírí fún ìgbà àkọ́kọ́ rẹ̀. Àkọ́lé fíìmù náà ni Noirs au soleil levant, èyí tí ó dá lóri ìgbésí ayé àwọn ọmọ akẹ́kọ̀ọ́ ilẹ̀ Áfríkà ní ìlú Tsukuba, orílẹ̀-èdè Japan. Àkọ́kọ́ fíìmù àròṣe rẹ̀ tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ 21 jáde ní Oṣù kejìlá ọdún 2013.[6] Ààjọ kan tí wọ́n pè ní Organisation internationale de la Francophonie ló ṣe onígbọ̀wọ́ fíìmù náà.[7] Niava tún ṣe adarí eré táa pe àkọ́lé rẹ̀ ní Worse ní ọdún 2014.[8] Ó tún ṣiṣẹ́ lóri fíìmù ọdún 2015 kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Advantageous.[9]
Niava gba oye gíga nínu ìmọ̀ nípa Fíìmù àti Tẹlifíṣọ̀nù láti ilé-ẹ̀kọ́ gíga Academy of Art University.[10] Ní ọdún 2017, Niava kọ àkọ́kọ́ ìwé-ìtàn rẹ̀ tí ó pe àkọ́lé rẹ̀ ní, American Dreamer. Ìwé náà jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìwé tí ó wà níbi àṣekágbá ti ìdíje 10th Prix Ivoire pour la Littérature Africaine d'Expression Francophone. [11]
Àṣàyàn àwọn eré rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- 2009-2010: Teenager (TV series, co-writer)
- 2012: Noirs au soleil levant (short film, director)
- 2013: 21 (short film, writer/director)
- 2014: Worse (short film, writer/director)
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "[Interview Marina Niava, réalisatrice et cinéaste ivoirienne"] (in French). Ayanawebzine. 25 July 2014. https://ayanawebzine.com/en-vedette/marina-niava-realisatrice-cineaste-notre-cinema-est-vegetatif-et-ici-il-nexiste-pas-dindustrie-du-cinema/. Retrieved 18 October 2020.[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
- ↑ "Marina Niava Cinéaste". Abidjan.net (in French). Archived from the original on 13 May 2021. Retrieved 18 October 2020.
- ↑ "Marina Niava : la cinéaste ivoirienne qui perce aux USA". Africatopsuccess.com (in French). 12 August 2014. Archived from the original on 29 February 2016. Retrieved 18 October 2020.
- ↑ "Marina Niava Cinéaste". Abidjan.net (in French). Archived from the original on 13 May 2021. Retrieved 18 October 2020.
- ↑ "Caravane de L’excellence : La fondation Benianh lance l’étape de EMPT". Abidjan.net (in French). 26 October 2017. Retrieved 18 October 2020.
- ↑ "Marina Niava Cinéaste". Abidjan.net (in French). Archived from the original on 13 May 2021. Retrieved 18 October 2020.
- ↑ Motte, Sophie (28 February 2018). "Télévision : les séries africaines crèvent l’écran" (in French). Le Monde. https://www.lemonde.fr/afrique/article/2018/02/28/television-les-series-africaines-crevent-l-ecran_5263576_3212.html. Retrieved 18 October 2020.
- ↑ "Marina Niava : la cinéaste ivoirienne qui perce aux USA". Africatopsuccess.com (in French). 12 August 2014. Archived from the original on 29 February 2016. Retrieved 18 October 2020.
- ↑ "Young Media Professionals". CommDev. Retrieved 18 October 2020.
- ↑ "Portrait/Marina Niava: écrivaine et cinéaste dans l'âme". Presse Cote d'Ivoire (in French). 26 October 2019. Retrieved 18 October 2020.
- ↑ Effoumy, Yannick (2 August 2017). "LA LISTE DES OUVRAGES FINALISTES DU PRIX IVOIRE 2017" (in French). Life Mag. Archived from the original on 30 November 2021. https://web.archive.org/web/20211130134520/https://lifemag-ci.com/la-liste-des-ouvrages-finalistes-du-prix-ivoire-2017/. Retrieved 18 October 2020.