Marjorie Lee Browne
Marjorie Lee Browne | |
---|---|
Fáìlì:Marjorie Lee Browne.jpg | |
Ọjọ́ìbí | Atlanta, Georgia | Oṣù Kẹ̀sán 9, 1914
Aláìsí | October 19, 1979 Durham, North Carolina | (ọmọ ọdún 65)
Orílẹ̀-èdè | American |
Iléẹ̀kọ́ gíga | Howard University (BS) University of Michigan (PhD) |
Marjorie Lee Browne (September 9, 1914 – October 19, 1979) ó jẹ́ olùkọ́ ẹ̀kọ́ -ìṣírò. Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn obìnrin àkọ́kọ́ tí ó jẹ́ ará Amẹ́ríkà-Adúláwọ̀ tó ti gba oyè ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ Dókítà ẹ̀kọ́ ìmọ̀-ìṣirò.
Early life and educati Ìbẹ̀rẹ̀ Ayé Rẹ̀ àti Ètò-Ẹ̀kọ́
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Marjorie Lee Browne jẹ́ gbajúmọ̀ onímọ̀ ẹ̀kọ́-ìṣírò, ní ọdún 1949, ó di obìnrin kẹta tó jẹ́ ọmọ Amẹ́ríkà-Adúláwọ̀ kẹta tó gba oyè ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ Dókítà nínú iṣẹ́ tó yàn láàyò. Oṣù kẹsàn-án, Ọjọ kẹsàn-án, ọdún 1914 ni a bí Browne, ní ìlú Memphis, Tennessee, àwọn òbí rẹ̀ ni Mary Taylor Lee àti Lawrence Johnson Lee. Bàbá rẹ̀, ẹni tó jẹ́ akọ̀wé ilé-iṣẹ́ reluwé ni ó tún fẹ́ ìyàwó mìíràn lẹ́yìn ikú tà kọ́kọ́, nígbà tí Browne jẹ́ ọmọ ọdún méjì. Òun àti ìyàwó rẹ̀ kejì, Lottie, olùkọ́ ilé-ẹ̀kọ́, ó gba ọmọ rẹ̀ ní ìyànjú láti kọjú mọ́ ẹ̀kọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí akẹ́kọ̀ọ́ tó peregedé. Browne lọ sí ilé - ẹ̀kọ́ gírámà LeMoyne High School, ilé-ẹ̀kọ́ aládàáni tí a bẹ̀rẹ̀ lẹ́yìn ogun àgbáyé, ilé-ẹ̀kọ́ Mẹ́tọ́díìsì. Nígbà ẹ̀kọ́ rẹ̀ yìí, ó gba àmì-ẹ̀yẹ "Memphis City Women's Tennis Singles Championship" NÍ ọdún 1929, lẹ́yìn ọdún méjì ni ó jáde ní ilé-ẹ̀kọ́ LeMoyne High School.
Ó lọ sí Howard University, ó sì kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìmọ̀ ìṣirò. Ó kẹ́kọ̀ọó gboyè ní ọdún 1935.[1] Lẹ́yìn tó gba ìwé-ẹ̀rí yìí, ó ṣiṣẹ́ olùkọ́ fún ìgbà díẹ̀, ní àwọn ilé-ìwé bí i Gilbert Academy, ní New Orleans.[1]
Notes
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- Patricia Clark Kenschaft, "Black Men and Women in Mathematical Research," Journal of Black Studies, vol. 18, no. 2 (December 1987), pp. 170–190.
- Scott W. Williams, "Black Women in the Mathematical Sciences," (SUNY Buffalo Math Dept.)
- E. Fogg, C. Davis, and J. Sutton, "Profile of Marjorie Lee Browne." Retrieved from the World Wide Web, Agnes Scott College's "Biographies of Women Mathematicians" Web Site on 28 July 2004.
- "MiSciNet's Ancestors of Science, Marjorie Lee Browne," Science, September 10, 2004.
- Charlene Morrow and Teri Perl (eds), Notable Women in Mathematics, a Biographical Dictionary, Greenwood Press, 1998. pp. 17–21.
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ 1.0 1.1 Krapp, Kristine, ed (1990). Notable black American scientists. NY: Gale. ISBN 0-7876-2789-5. https://archive.org/details/notableblackamer0000unse.