Jump to content

Medina of Sousse

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Àdàkọ:Infobox historic site Medina of Sousse ni ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìpín mẹ́rin ilẹ̀ Medina Sousse, Governorate of Sousse, ní orílẹ̀-èdè Tunisia. Àjọ UNESCO sọ ibẹ̀ di World Heritage Site ní ọdún 1988. Ìlú yí fi àpẹẹrẹ ìṣèjọba ẹ̀sìn Mùsùlùmí hàn pẹ̀lú àwọn ilé aláràmbara tí wọ́n ti kọ́ ní aìmọye ọdún ẹ́yìn ní agbègbè Maghreb. Lára rẹ̀ ni: Kasbah, fortification àti Great Mosque of Sousse. Lóde òní, ìlú Medina ni ilé ìṣẹ̀mbáyé Archaeological Museum of Sousse wà.

Ìlú Median ti Sousse ni ó wà ní Tunisian Sahel tí ó sì ní àwọn ilé àwòdamiẹnu tí wọ́n dá dúró tí wọ́n sì dá yàtọ̀, èyí rí bẹ́ẹ̀ látàrí wọ́n ti kọ́ àwọn ilé wọ̀nyí láti ìgbà tí ọ̀làjú ẹ̀sìn Islam kọ́kọ́ dé ni , èyí ni ó fi jẹ́ kí ó wà lára àwọn ilé tí ti pẹ́ jùlọ nínú ìtàn tí ó sì tún sọ bí ìtàn ẹ̀sìn Islam ṣe tàn ká. ní agbègbè Maghreb. Ìdí tún ni wípé ìlú MedIna nílò ààbò tó péye lọ́wọ́ àwọn adàlúrú àti àwọn olè nígbà náà .[1] Ìṣọwọ́ gbé ilé kíkọ́ kalẹ̀ ní ìlú náà fi bí ọ̀làjú tí ẹ̀sìn Islam mú wá nígbà náà ti láyéòde òní nlbí ó ṣe lágbára tó. Àwọ ọnà àti ọ̀nà ìkọ́lé nígbà Aghlabid ni ó fi hàn wípé wọ́n mú lele lórí ààbò nípa kíkọ́ ilé ìṣọ́ fún àwọn ọmọ ogun láti lè dojú kọ àwọn ọlọ̀tẹ̀ tàbí ọ̀tá tí wọ́n bá fẹ́ kọ lù wọ́n.


Àwọn ìtọ́ka sí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àdàkọ:World Heritage Sites in Tunisia