Jump to content

Meghan Trainor

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Meghan Trainor
Meghan Trainor, a woman, smiling and looking towards the screen
Trainor in 2020
Ọjọ́ìbíMeghan Elizabeth Trainor
22 Oṣù Kejìlá 1993 (1993-12-22) (ọmọ ọdún 31)
Nantucket, Massachusetts, U.S.
Iṣẹ́
  • Singer-songwriter
  • television personality
Ìgbà iṣẹ́2009–present
Works
Olólùfẹ́
Daryl Sabara (m. 2018)
Àwọn ọmọ1
AwardsFull list
Websitemeghan-trainor.com
Musical career
Ìbẹ̀rẹ̀North Eastham, Massachusetts, U.S.
Irú orin
InstrumentsVocals
Labels

Meghan Elizabeth Trainor (tí a bí ní ọjọ́ kejìlélógún oṣù Kejìlá, ọdún 1993) ọmọ orílẹ̀-èdè America, jẹ́ gbajúgbajà olórin. Ó di gbajú-gbajà lẹ́yìn tí ó fọwọ́ sí ìwé pẹ̀lú Epic Records ní ọdun 2014 tí ó sì ko orin rẹ̀ àkọ́kọ́ tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ "All About That Bass", ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn orin tí àwọn ará Amerika gbó jù ní ìgbà náà. Trainor tà tó mílíọ̀nù mọ́kànlá orin náà káàkiri àgbáyé. Trainor tí kó albumu orin márùn-ún láti ìgbà náà, ó sì ti gbà ọ̀pọ̀lọpọ̀ àmì ẹyẹ, ọkàn lára rẹ̀ ni àmì-ẹyẹ Grammy ni ọdun 2016 fún àwọn olórin titun tí ó dára jù lọ.

Trainor ti nífẹ̀ẹ́ sí orin láti ìgbà tí ó wà ní ọmọdé; o kọ àwọn orin àkọ́sítìkì mẹ́ta , Meghan Trainor (ọdún 2009), I'll sing with you, àti only 17 (ọdún 2010). O bẹ̀rẹ̀ kíkọ àti àgbéjáde àwọn orin fún àwọn akọrin mìíràn ní ọdun 2013. Ní ọdún 2015, Trainor ṣe àgbéjáde álíbọ̀mù pop ati hip hop rẹ̀, tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ Title, ó jẹ́ orin àkọ́kọ́ ní orí Billboard orílè-èdè Amẹ́ríkà nígbà tí ó jáde. Ó ṣe àgbéjáde àwọn orin mìíràn bi "No" àti "Thank you" (ní ọdun 2016) àwọn orin méjèèjì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn orin tí àwọn ènìyàn gbọ́ jù ni Amerika nígbà náà. Trainor ṣàgbẹ́ jáde álíbọ̀mù orin kẹta rẹ̀ pẹ̀lú Epic, "Treat Myself" (2020), ní ìgbìyànjú rẹ̀ láti tẹ̀lé àwọn àṣà orin tí ó nlọ lọ́wọ́, ó se àgbéjáde álíbọ̀mù orin mìíràn tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ A very Trainor Christmas. Trainor ṣe àgbéjáde álíbọ̀mù karùn-ún orin rẹ̀ ní ọjọ́ kọkànlélógún Oṣù Kẹ̀wá (21 Oct), Ọdún 2022, ọkàn nínú àwọn orin inú álíbọ̀mù náà “ Made You Look ” jẹ́ ọ̀kan lára àwọn orin márùn-ún tí àwọn ènìyàn gbọ́ jù nígbà náà ní àwọn orílè-èdè bi UK, Ireland, Australia àti New Zealand.

Àwọn orin Trainor ma ń sábà dá lórí obìnrin, bí ènìyàn se rí ara rẹ̀, ati ìfiagbára fún ara ẹni, bótilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ sọ wípé àwọn orin rẹ̀ ń lòdì sí jíjà fún ẹ̀tọ́ obìnrin. Yàtọ̀ sí kíkọrin, ó fọ òhun nínú àwọn fíìmù bí Smurfs: The Lost Village (2017) àti Playmobil: the movie (2019). Ó ti jẹ́ onídajọ́ lórí àwọn ìtàgé fífi tálẹ̀ǹtì hàn bí the four: battle of Stardom (2018), Voice UK (2020) àti Australian idol (2023). Trainor ti gbà ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀yẹ bi Aami Eye Grammy kan, ẹ̀bùn ASCAP mẹrin, ati Awọn ẹbun Orin billboard meji.