Mereb Estifanos
Mereb Estifanos | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | 1983 (ọmọ ọdún 40–41) Arareb |
Orílẹ̀-èdè | Eritrean |
Iṣẹ́ | Actress |
Ìgbà iṣẹ́ | 2002-present |
Mereb Estifanos (tí wọ́n bí ní ọdún 1983) jẹ́ òṣèrébìnrin ọmọ orílẹ̀-èdè Ẹritrẹ́à.
Ìsẹ̀mí rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Wọ́n bí Estifanos ní ọdún 1983 ní ìlú Arareb. Ó jẹ́ ọmọ Estifanos Derar àti Negesti Wolde-Mariam. Estifanos ní ètò-ẹ̀kọ́ girama rẹ̀ ní ìlú Asmara.[1] Ó ṣe àpèjúwe ararẹ̀ pé òún gbájúmọ́ ẹ̀kọ́ òun tí òún sì maá n tara láti peregedé nínu ẹ̀kọ́ òun. Estifanos maá n gbá bọ́ọ̀lù àfọwọ́gbá Volleyball ní ìgbà tí ó wà ní ilé-ìwé, ṣùgbọ́n ó dáwọ́ rẹ̀ dúró láti gbájúmọ́ iṣẹ́ òṣèré rẹ̀.[2]
Bótilẹ̀jẹ́pé Estifanos kọ́kọ́ fẹ́ láti di akọrin tàbí oníjọ́, ní ọdún 2002 ni Fessehaye Lemlem, ẹni tí ó kọ ìtàn eré Fermeley, fi lọọ Estifanos láti wá kópa nínu fíìmù rẹ̀. Nígbà náà, Estifanos síì wà ní ilé-ìwé girama kò sì tíì kó ipa eré kankan rí.[3] Èyí mú kí ó máa ṣeyèméjì ṣáájú kí ó tó padà wá faramọ́ láti kópa nínu eré náà. Ó kópa gẹ́gẹ́ bi ọmọ akẹ́kọ̀ọ́ ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga kan tí ó yó ìfẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ẹgbẹ́ rẹ̀ ṣùgbọ́n tí eré ìfẹ́ àwọn méjéèjì padà já sí ìkorò nígbẹ̀yìn. Lẹ́hìn ipa rẹ̀ nínu fíìmù náà, Estifanos pinnu láti dáwọ́ ẹ̀kọ́ rẹ̀ dúró náá láti lè gbájúmọ́ iṣẹ́ òṣèré, bótilẹ̀jẹ́pé ó ṣe ìpinnu láti padà sí ìdí ẹ̀kọ́ rẹ̀ bí kò bá rí ìtẹ́lọ́rùn nídi iṣẹ́ òṣèré náà.[4]
Estifanos lọ fún ìdánilẹ́kọ̀ọ́ nípa eré ṣíṣe fún oṣù mẹ́ta ní ilé-ẹ̀kọ́ Department of Cultural Affairs. Estifanos kó ipa ti Feruz nínu eré tẹlifíṣọ̀nù alátìgbà-dégbà tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Hareg gẹ́gẹ́ bi ọmọbìnrin kan tó ní àwọn olólùfẹ́ méjì. Ó ti kópa nínu ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn fíìmù míràn tó lórúkọ tó fi mọ́ Werasi Kidan, Gezie, Mezgeb, Shalom, Azmarino, Ketali Sehbet, ati Fekri Tsa'iru.[5]
Àṣàyàn àwọn eré rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- 2002: Fermeley
- 2012: Tigisti
- 2016: Zeyregefet Embaba