Jump to content

Meseret Defar

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Meseret Defar
Defar in 2016
Òrọ̀ ẹni
Ọmọorílẹ̀-èdèEthiopian
Ọjọ́ìbí19 Oṣù Kọkànlá 1983 (1983-11-19) (ọmọ ọdún 41)
Addis Ababa, Derg
Height155 cm (5 ft 1 in)
Weight42 kg (93 lb)
Sport
Orílẹ̀-èdè Ethiopia
Erẹ́ìdárayáAthletics (sport)
Event(s)3000 metres, 5000 metres

Meseret Defar Tola ni a bini ọjọ ọkan dinlọgbọn, óṣu November, Ọdun 1983 jẹ elere sisa lóbinrin to da lori ayẹyẹ ti metres ẹgbẹrun mẹta ati metres ti ẹgbẹrun maarun[1][2][3].

Ni ọdun 2003, Defar gba ami ẹyẹ ti ọla ti wura ti metres ti ẹgbẹrun maarun. Ni ọdun 2004, Defar kopa ninu olympics ti summer ni Athens pẹlu wakati 14:45.65 Ni ọdun 2008, Defar kopa ninu olympics ti Beijing to si gba ami ẹyẹ ti ọla ti silver[4]. Ni ọjọ akọkọ, óṣu September, ọdun 2007, Defar kopa ninu idije agbaye ni Osaka ti metres ti ẹgbẹrun maarun to si gba wura pẹlu wakati 14:57.91[5]. Ni 2007, Defar gba ami ẹyẹ gẹgẹbi obinrin to pegede julọ ninu IAAF agbaye lori ere sisa ninu ọdun naa. Ni ọdun 2005, Meseret kopa ninu idije agbaye to si gba ami ẹyẹ ti ọla ti silver to waye ni Helsinki. Ni ọdun 2006, Defar kopa ninu idije agbaye ti inule ti metres ti ẹgbẹrun mẹta. Ni ọdun 2008, Defar kopa ninu idije agbaye ti inule ti metres ti ẹgbẹrun mẹta to si gba ami ẹyẹ ti ọla ti wura[6]. Ni ọdun 2009, Defar kopa ninu idije agbaye lori ere sisa ti metres ti ẹgbẹrun mẹwa pẹlu wakati 29:59.20. Ni ọdun 2009, Defar kopa ninu idije agbaye lori ere sisa ti metres ti ẹgbẹrun mẹta pẹlu wakati 8:30.15. Ni ọdun 2010, Meseret kopa idije ilẹ Afirica ti metres ti ẹgbẹrun to si gba ami ẹyẹ ti ọla ti silver. Ni ọdun 2010, Defar kopa ninu Cup ti IAAF ti metres ti ẹgbẹrun mẹta[7]. Ni ọdun 2010, Defar kopa ninu idaji Marathon ti Philadelphia pẹlu wakati 1:07:44. Ni ọdun 2011, Defar kopa ninu idije agbaye lori ere sisa ti metres ti ẹgbẹrun mẹwa ati ẹgbẹrun maarun. Ni ọdun 2012, Meseret kopa ninu idije agbaye ti inule pẹlu ipo keji. Ni ọdun 2012, Defar kopa ninu Olympics ti London ti metres ti ẹgbẹrun maarun. Ni ọdun 2013, Meseret yege ninu Idaji Marathon ti New Orleans pẹlu wakati 8:35.28 ti metres ti ẹgberun mẹta. Defar yege ninu idije agbaye ni Moscow pẹlu wakati 14:50:19 ti metres ti ẹgbẹrun maarun.

  1. World Championships
  2. Meseret Defar
  3. Meseret Profile
  4. Silver Medal
  5. Osaka 2007
  6. Defar in 3000m
  7. IAAF 300m Race