Michael Costello
Michael Costello | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | January 20, 1983 Sherman Oaks, Los Angeles |
Iṣẹ́ | Fashion Designer |
Gbajúmọ̀ fún | Designing clothes |
Website | https://michaelcostello.us/ |
Michael Costello (tí a bí ní Oṣù Kìíní Ọjọ́ Ogún, Ọdún 1983) jẹ́ oníṣẹ́ àrà nípa aṣọ ìlú Amẹ́ríkà àti ènìyàn pàtàkì orí tẹlifíṣàn. Ó fara hàn ní ìgbà kẹjọ ti Project Runway àti ìgbà àkọ́kọ́ ti Project Runway All Stars.
Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ Ayé
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Wọ́n bí Michael Costello ní Oṣù Kìíní Ọjọ́ Ogún, Ọdún 1983, ní Sherman Oaks, Los Angeles. Bàbá Costello jẹ ará Italy-Hungary ìyá rẹ̀ sì jẹ ọmọ Gíríìkì Romani àti ọmọ Russia. Nígbà tó pé ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, ó kó lọ sí Palm Springs, California.[1]
Iṣẹ́
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Costello bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àwọn aṣọ nígbà tí ó wà ní ọmọ ọdún méjì nípa fífi àwọn aṣọ ṣe àwòrán sára ògiri yàrá rẹ̀. Nígbà tó pé ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, ó ṣí ilé ìtajà rẹ̀ àkọ́kọ́ ní 286 North Palm Canyon Drive ní Palm Springs.[1] Ó jẹ́ ilé ìtajà àkọ́kọ́ rẹ̀ ní Palm Springs níbi tí Costello ti bẹ̀rẹ̀ ṣíṣe àwọn ègé àṣà fún àwọn olókìkí tí ó pẹ̀lú Céline Dion, Jennifer Lopez, Toni Braxton, Barry Manilow, Suzanne Somers, Faye Dunaway, Florence Henderson, àti àwọn mìíràn. Costello ṣe àkọlé fún ṣíṣe orí àṣíborí àti aṣọ fún "rapper" Cardi B fún Paris Fashion Week.[2] Kylie Jenner wọ ọ̀kan lára àwọn aṣọ rẹ̀ fún ojú àkọ́kọ́ ìwé ìròyìn ọjọ́ ìbí rẹ̀ àti Costello ti bá Lady Gaga ṣe ayẹyẹ.[3]
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ 1.0 1.1 Brassart, Scott (November 22, 2010). "Fashion designer Michael Costello reveals intimate details of his life and his "Project Runway" experience". San Diego Gay & Lesbian News. http://www.sdgln.com/bottomline/2010/11/22/haute-couture-holiday-interview-fashion-designer-michael-costello.
- ↑ Bailey, Alyssa (September 25, 2018). "Here's Cardi B Literally Peacocking In A Massive Michael Costello Dress At Paris Fashion Week". Elle Magazine. https://www.elle.com/fashion/celebrity-style/a23459515/cardi-b-peacock-michael-costello-dress-paris-fashion-week/.
- ↑ Hoffman, Ashley (May 25, 2016). "Designer Michael Costello on Strong Women, Partying With Gaga and the Evolution of Kylie Jenner". RunwayRiot (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on October 1, 2019. Retrieved April 23, 2020. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help)