Jump to content

Michelle Dede

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Michelle Dede
Ọjọ́ìbíMichelle Dede
Germany
Orílẹ̀-èdèNaijiria
Ìgbà iṣẹ́2006 – iwoyi

Michelle Dede jẹ́ atọ́kùn ètò orí tẹlifíṣọ̀nù Nàìjíríà àti òṣèré. Ó ṣe àjọgbéjáde fíìmù tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Flower Girl, ó sì tún kópa nínu eré tẹlifíṣọ̀nù alátìgbà-dègbà kan, Desperate Housewives Africa àti fíìmù aṣaragágá tí ọduń 2017, What Lies Within.[1]

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé àti ẹ̀kọ́ rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

A bí Dede ní orílẹ̀-èdè Jẹ́mánì. Ó dàgbà ní ìdílé olókìkí. Bàba rẹ̀ ni Brownson Dede, aṣojú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà kan si orílẹ̀-èdè Ethiopia. Ó ní ètò ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ rẹ̀ ní Ìlú Brasil, ó sì parí ẹ̀kọ́ girama àti ẹ̀kọ́ gíga rẹ̀ ní Australia àti Ethiopia. Lẹ́hìn náà, ó tẹ̀síwájú sí Ìlú Gẹ̀ẹ́sì láti kẹ́ẹ̀kọ́ Fashion Design áti Marketing ní Ilé-ẹ̀kọ́ gíga American College ní Ìlú Lọ́ndọ̀nù, UK. Ó tún ní oyè-ẹ̀kọ́ gíga nínu ìmọ̀ ìbáraẹnisọ̀rọ̀ láti Ilé-ẹ̀kọ́ yìí kan náà.[2]

Iṣẹ́ òṣèré rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ lẹ́hìn tí ó wá fún ìsinmi kan ní Nàìjíríà. Nígbà náà ló di ẹni tó ní ànfààní láti máa ṣiṣẹ́ lágbo eré ìdárayá. Ní ọdún 2006, ó jẹ́ alájọṣe pẹ̀lú Olisa Adibua fún ti àkọ́kọ́ ìkéde ti Big Brother Nigeria, eré tẹlifíṣọ̀nù Nàìjíríà kan tí ó dá lóri eré Big Brother.[2] Lẹ́hìn náà, ó ṣe àjọgbéjáde fíìmù Flower Girl ti ọdún 2013 ṣááju kí ó tó tẹ̀síwájú láti kó ipa Tari Gambadia nínu fíìmù Desperate Housewives Africa. Ó tọ́ka sí Oprah Winfrey gẹ́gẹ́ bi àwòkọ́se rẹ̀ fún iṣẹ́ olùgbàlejò lóri ètò tẹlifíṣọ̀nù [3] Ní ọdún 2017, Dede kópa nínu fíìmù aṣaragágá kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ What Lies Within pẹ̀lú àjọṣepọ̀ Paul Utomi, Kiki Omeili àti Tọ́pẹ́ Tedela.[4] Ní ọdún 2018, ó tún kópa nínu eré Moms at War.[5]

Àṣàyàn àwọn eré rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  • Flower Girl (2013)
  • Desperate Housewives Africa (2015)
  • What Lies Within (2017)
  • Moms at War (2018)

Dede jẹ́ ẹ̀jẹ̀ apanilẹ́ẹ̀rín Najite Dede. Ó sì n ṣe aṣojú ìpolówó ojà fún ilé-iṣẹ́ kan tó rí sí ǹkan amúsẹwà, Emmaus Beauty. [6][7]

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]