Jump to content

Monthly Darul Uloom

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Monthly Darul Uloom (Urdu: ماہنامہ دارالعلوم) jẹ́ ìwé ìròyìn ìgbàdégbà Urdu tí Darul Uloom Deoband kọ láti ọdún1941.[1] TÍ wọ́n ìfilọ́lẹ̀ lábẹ́ àmójútó Muhammad Tayyib Qasmi, pẹ̀lú Abdul Wahid Ghazipuri gẹ́gẹ́ bíi olóòtú ìbẹ̀rẹ̀, Salman Bijnori ni ó ṣe àtúnṣe ìwé ìròyìn náà báyìí ,tí Abul Qasim Nomani sì darí rẹ̀.ìwé ìròyìn yìí kún fún àyọkà tí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ onímọ̀ tàbí àwọn tí wọ́n tí wọn tí kàwé gboyè ni ilé ẹ̀kọ́ gíga kọ,[2] àfojúsùn títẹ́ ìwé ìròyìn yí kọjá a àtúnṣe orílẹ̀ èdè àti àwùjọ Mùsùlùmí, ó tọ́ka sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àkọlé tí ó ní ṣe pẹ̀lú ipò tí ẹṣin, ìbáraeni-gbépọ̀ àwùjọ,Ọgbọ́n àti eto ìṣèlú, wà báyìí , tí ó pèsè òǹkáwe tí yóò fi ojú inú wò ipò àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó báyému,síbẹ̀ yóò tún máa ṣe Ìtanijí fún àwọn musulumi sì àwọn ìdojúkọ tí wọn lè kojú.[3] Ìwé ìròyìn ìgbàdégbà yìí ni ìwòye akọ̀ròyìn tí ó yàtọ̀ lórí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì tí ó ní ṣe pẹ̀lú Deobandi movement.[4] bí ó tilẹ̀ jẹ̀ wípé àjọ náà koju ìfòpinsí ní ọ̀wọ́ ọdún 1940, Azhar Shah Qaiser ṣe ìmúpadà bọ̀sìpò rẹ̀,lábé ìjẹ́olóòtú ọgbọ́n ọdún rẹ́,ajo yìí wá di èyí tí ó ó ṣe àtẹ̀jáde ìwé onírúurú, ó sì fi ogún rere lélẹ̀ pẹ̀lú ẹri tí ó nípa nínú àwọn ibi ẹ̀kọ́ mìíràn,tí ó sì,èyí ni ó jẹ́ ìwúrí ìṣẹ̀dá ìwé ìròyìn Bayyināt tí ó tẹ̀lé àwòkọ́ṣe rẹ̀.[5]

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ àti ìtànkálẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Odùn mẹ́rìndínlógún kọjá , Darul Uloom Deoband gbèrò ìfilọ́lẹ̀ ìwé ìròyìn olóṣooṣù tuntun ni èdè urdi lẹ́yìn ìgbátí Al-Qasim and Al-Rashid di kúrò lẹ́nu iṣẹ́.[6] Tí Muhammad Tayyib Qasmi atí Abdul Wahid Ghazipuri darí rẹ̀, àjọ náà tùṣọ lójú ìfilọ́lẹ̀ rẹ̀ ni May-June 1941.[6]ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bíi olóòtú títí di ọdún 1944, nígbà tó yá,ó yapa kúrò lára Monthly Darul Uloom ó sì kó lọ sí Delhi. Qazi Khaliq Ahmad bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ olóòtú náà ṣùgbọ́n nítorí ìdojúkọ àìsí àkókò, ó fi ipò náà sílẹ̀ ni ọdún 1948.[7]

Ní ọdún 1949, Abdul Hafeez Balyawi gba ipò olóòtú yẹn ṣùgbọ́n àìlówó lọ faa tí ó fi jẹ pe ìwé títẹ́ wọn dá lé kókó ọ̀rọ̀ méje ní ìgbà rẹ̀.[7] Monthly Darul Uloom tún di ilé iṣẹ́ ìwé ìròyìn òní ẹ̀ẹ̀mẹrin lọ́dún. Ní òpin ọdún 1949, lábẹ́ àmójútó Azhar Shah Qaiser àjọ naa bọ́ ipò ọ̀mọ̀we sìlẹ̀ láti ṣàmúlò ìlànà ìgbéṣẹ́ga .[7] Lẹ́yìn ìdádúró ráńpẹ́, ilé iṣẹ́ ìròyìn náà bẹ̀rẹ̀ àtẹ̀jáde oṣooṣù ní April 1951 ìjẹ́olóòtú Qaiser,[8] ó tẹ̀sìwàjù di ọdún 1982.[9] Ní gbogbo ìgbà tí ó fi jẹ olóòtú yìí,ó lo ipa rẹ̀ láti fi mú ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ọ̀mọ̀wé, òǹkọ̀wé,akéwì,àti oníròyìn wá sí ilé iṣẹ́ ìròyìn naa, bíi Zafeeruddin Miftahi àti ní ṣókí Nadeem al-Wajidi,n ṣíṣe ninu àṣeyọrí pẹlu òye àti ìjáfáfá ibi tí àkóónú rẹ dé.[8]

Lẹ́yìn Azhar Shah Qaiser, Riyasat Ali Zafar Bijnori gba ipò olóòtú ,[9] Habibur Rahman Azami sì jẹ leyin rẹ̀,òun di ipo náà mú láti October 1984 di November 2016.[10] Nayab Hasan Qasmi sọ wípé ni gbogbo igba ti Azami fi wá ní ipò, ògo àtẹ̀yìnwá ilé iṣẹ́ náà kò kan dúró lásán,ó tún ní ìrírí àwọn ìdàgbàsókè tí ó fojú hànde, kò wá ń ṣe orílẹ̀ èdè India nìkan ni wọn ti ń ka ìwé náà mọ ṣùgbọ́n wọn ń ka ni àwọn orílẹ̀ èdè Asia mìíràn .[9] Salman Bijnori gba ipò gẹ́gẹ́ bíi olóòtú keje lẹ́yìn tí kúrò nibẹ.[10]

Darul Uloom Deoband ní ọ́fíìsì tí ó ń mójútó Monthly Darul Uloom, wọ́n tẹ ìwé jáde lórí ìkànnì ayára-bí-àṣá ni ìkànnì ilé iṣẹ́ náà fún àìmọye ọdún.[11] Àwọn òńkọ̀wé alálọpẹ̀ bíi Shabbir Ahmad Usmani, Ahmad Saeed Dehlavi, Muhammad Tayyib Qasmi, Izaz Ali Amrohi, Hifzur Rahman Seoharwi, Muhammad Shafi Deobandi, Saeed Ahmad Akbarabadi, Muhammad Miyan Deobandi, Idris Kandhlawi, Yusuf Banuri, Manazir Ahsan Gilani, Manzoor Nomani, ati Habibur Rahman Azami.[12]

Ìtẹ̀jáde àwọn àsọyé

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Monthly Darul Uloom begins bẹ̀ẹ̀rẹ̀ pẹlu abala ìgbìmọ̀ olóòtú tí wọ́n pé àkọlé rẹ̀ ni "Rashhāt," tí àfojúsùn rẹ̀ dá lé ẹ̀sìn àti àtúpalẹ̀ ẹ̀kọ́ nípa ẹ̀sìn pẹlú ìwòye lórí ìṣẹ̀lẹ̀ orílè èdè àti agbaye. Ìwé ìròyìn náà ṣàfihàn lára àwọn ìṣe àwọn oníwàádí orílẹ̀ èdè àti ti àwọn orílẹ̀ èdè mìíràn. Abala tí ó gbẹ̀yìn ṣàfihàn ìgbòkègbodò olórí Darul Uloom Deoband lábẹ́ orúkọ "Darul Uloom."

Ohun tí Azhar Shah Qaiser kọ, tí àkọlé rẹ̀ jẹ́ "Harf-e-Aghaz," mẹ́nuba, ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́,oyè ìwádìí, ìwé àti ìṣèlù. Tí ó kọ láti Zafeeruddin Miftahi àti lẹ́ẹ̀kànkan Nadim Al-Wajdi náà máa ń wà níbẹ̀. Ipele "Adabiyyat" máa ń fi ṣe àfihàn ghazals léraléra láti inú ewì Mahir ul Qadri, Jigar Moradabadi, àti àwọn mìíràn .[8]

Ní oṣooṣù ,ayé tó wà fún àyẹ̀wò ìbẹnuàtẹ́lù àti ìgbóríyìn fún ìwé tuntun tí onírúurú òńkọ̀wé kọ, tí ó sọ nípa ìgbéjàde ọ̀pọ̀ ìwé ni ìgbà kan náà. Pẹ̀lú Azhar Shah Qaiser, àwọn òńkọ̀wé bíi Anzar Shah Kashmiri, Abdul Rauf Aali, àti Qamar Ahmed Usmani dáwọ́lé kíkọ ohunkan nípa ìṣe ẹlòmíràn, pẹ̀lú Aali and Usmani ìtì wọ́n gba ìdánimọ̀ ni Urdu Academy nitori ìwé tí wọ́n kọ.[8]

Lábẹ́ ìjẹ́olóòtú Azhar Shah Qaiser, Monthly Darul Uloom di ilé iṣẹ́ tí ó tẹ ìwé tí ó ní òye,tí ó sọ nípa ètò ẹ̀kọ́,ẹ̀sìn,ìwé kíkọ,àti àwọn àkọlé tí ó nípọn fún onírúurú òǹkáwe.[13] Àyè Habibur Rahman," Àyè Nigarishat Ka," ń ṣàmúlò àwọn ohun ti awon ọ̀mọ̀we ṣẹ̀dá àti àti ohun tí wọ́n kọ bẹẹ, wọn kò àwọn ohun tí ó ń kọ nínú Monthly Darul Uloom pọ̀ sí ọ̀nà mẹ́ta onípele-ìpele tí a pe àkọlé rẹ̀ ní "Maqalat-e-Habib," tí ó dẹ̀ tí gba ìbọwọ́lù ní agbọn ètò ẹ̀kọ́ .[9]

Àyẹ̀wò kókó ọ̀rọ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Níbi ìbúra olootu rẹ, olóòtú Monthly Darul Uloom ṣàlàyé àwọn àfojúsùn ilé iṣẹ́ náà.[6]ile ìṣe ìwé ìròyìn yìí níi lọ́kàn láti fi ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ àtọ̀runwá àti ẹ̀kọ́ nípa ìsọtẹ́lẹ̀ hàn ní ọ̀nà tí yóò rọrùn láti rí,ní èyí tí yóò tayọ ẹ̀kọ́ ayélujára .[14]àwọn iṣẹ́ rẹ̀ ni lati yànnàná òpó ẹ̀sìn ìsìlámù, ṣe ìwádìí ẹ̀kọ́ nípa ẹ̀sìn ìsìlámù,àti pípèsè ìdáhùn tí ó yèkoro sì àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú ìtàn àti àríyànjiyàn yálà láti inú ìbẹnuàtẹ́lù ẹṣin ìsìlámù tí ó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́ àti èyí tí ó wà nínú ìtàn.o ń ṣíṣe láti ṣàfihàn ẹwà tí ìgbàgbọ́, láti pé àwọn tí wọn tí wọ́n faramọ́ àti àwọn tí wọn tako ìdàgbàsókè ọkàn ìjọsìn laarin awọn Mùsùlùmí ni àkókò àìnígbàgbọ́ àti àìjọ́sìn tí a wà yí.o ń tẹpẹlẹ mọ àwọn ohun tí ó jẹ́ mọ́ òfin láàárín ẹṣin ìsìlámù. Ìwé ìròyìn yìí máa ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìwé kíkọ láàárín ìgbàgbọ́ ìsìlámù nìkan, láì mú òńkọ̀wé láti inú ẹ̀sìn mìírà

Ìjẹ́wọ̀ ẹ̀kọ́

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ìwé ìròyìn yìí tí gba onírúurú ìdáhùn láti jẹ́wọ́ rẹ̀ pé ó dára. Wasim Ahmad lati Jamia Hamdard sọ pé ó ń dáhùn sì ohun tí àwọn musulumi, pẹ̀lú pé ó tẹpẹlẹ mọ̀ àwọn kókó ọ̀rọ̀.[2]ọ̀mọ̀we to Ó ti kàwé gboyè dókítà ni fasiti Delhi University , Muhammad Sirajullah, yin ipò àti ipele Ìlò èdè rẹ̀ tí ó múná dòko.[3] Mohammad Moosa, Dokita ọ̀mọ̀we láti Panjab University, tẹnumọ́ ìfarajìn ìwé ìròyìn náà sì sísọ fún àwùjọ Mùsùlùmí nípa àwọn ọ̀rọ̀ tí ó ti tàn ká. Nayab Hasan Qasmi, tí ó kọ Darul Uloom Deoband Ka Sahafati Manzarnama,sọ nípa àwọn ohun pàtàkì tí ìwé ìròyìn yìí ṣe sí kíkọ àti kíka ìròyìn ìsìlámù.[12] Muhammadullah Qasmi, ọ̀mọ̀we tí ó kàwé gboyè dókítà láti Jamia Hamdard dúpẹ́ fún bí ìwé ìròyìn yìí ṣe ń gbé oríṣiríṣi jáde, ó ń ṣe àkáálẹ̀ ọ̀mọ̀we, àyípadà, àti bí ìwé ìròyìn náà ṣe máa ń dá ọkàn líle sì ẹṣin ìsìlámù, ìṣèlú àti eto ìṣèjọba lámù

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. Freitag, Ulrike, ed (2010). Translocality: the study of globalising processes from a southern perspective. Studies in global social history. Leiden: Brill. p. 330. ISBN 978-90-04-18605-7. https://books.google.com/books?id=lN55DwAAQBAJ. Retrieved 19 December 2023. 
  2. 2.0 2.1 Singh, Rajendra Pal; Rana, Gopal (2002) (in en). Teacher Education in Turmoil: Quest for a Solution. Sterling Publishers Pvt. Ltd. pp. 28. ISBN 978-81-207-2431-0. https://books.google.com/books?id=QI2bShxV36IC. Retrieved 19 December 2023. 
  3. 3.0 3.1 Sirajullah, Muhammad (2017) (in ur). Urdu Sahafat Ke Farogh Mein Madaris Ka Hissa. New Delhi: Educational Publishing House. pp. 109. ISBN 978-93-86624-58-1. https://www.rekhta.org/ebooks/urdu-sahafat-ke-farog-mein-madaris-ka-hissa-dr-muhammad-sirajullah-ebooks. Retrieved 19 December 2023. 
  4. Qasmi, Nayab Hasan (2013) (in ur). Darul Uloom Deoband Ka Sahafati Manzarnama. India: Idara Tahqueeq-e-islami Deoband. pp. 116. https://archive.org/details/DarulUloomDeobandKaSahafatiManzarNamah. 
  5. Qasmi, Muhammadullah (2020) (in ur). Darul Uloom Deoband Ki Jame O Mukhtasar Tareekh (3rd ed.). India: Shaikh-Ul-Hind Academy. p. 413. OCLC 1345466013. https://archive.org/download/dar-al-aloom-deoband-ki-jame-aor-mukhtasar-tareekh/Dar%20al%20aloom%20deoband%20ki%20jame%20aor%20mukhtasar%20tareekh%20%D8%AF%D8%A7%D8%B1%D8%A7%D9%84%D8%B9%D9%84%D9%88%D9%85_%D8%AF%DB%8C%D9%88%D8%A8%D9%86%D8%AF_%DA%A9%DB%8C_%D8%AC%D8%A7%D9%85%D8%B9_%D9%88_%D9%85%D8%AE%D8%AA%D8%B5%D8%B1_%D8%AA%D8%A7%D8%B1%DB%8C%D8%AE_%D8%AF%D8%A7%D8%B1%D8%A7%D9%84%D9%85%D8%A4%D9%84%D9%81%DB%8C%D9%86.pdf. 
  6. 6.0 6.1 6.2 Qasmi 2013, p. 114.
  7. 7.0 7.1 7.2 Qasmi 2013, p. 117.
  8. 8.0 8.1 8.2 8.3 Qasmi 2013, p. 118.
  9. 9.0 9.1 9.2 9.3 Qasmi 2013, p. 120.
  10. 10.0 10.1 Qasmi, Khursheed Alam Dawood (28 July 2021). "Prolific Writer and Popular Teacher: Maulana Habibur Rahman Azami Qasmi". Millat Times. https://millattimes.com/opinion-prolific-writer-and-popular-teacher-maulana-habibur-rahman-azmi-qasmi. 
  11. Qasmi 2020, p. 231.
  12. 12.0 12.1 Qasmi 2013, p. 116.
  13. Qasmi 2013, p. 119.
  14. Qasmi 2013, p. 115.