Muhammad Adil Khan

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Mawlāna, Dr.

Muhammad Adil Khan
Rector of Jamia Farooqia
In office
15 January 2017 – 10 October 2020
AsíwájúSaleemullah Khan
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbí1957
Aláìsí10 October 2020(2020-10-10) (ọmọ ọdún 62–63)
Karachi, Sindh, Pakistan
Cause of deathAssassination
BàbáSaleemullah Khan
Alma materJamia Farooqia, University of Karachi
AwardsFive Star Ranking Award, 2018 from Malaysia Higher Education

Muḥammad Adil Khan tàbí Adil Khān (1957 10 October 2020) jẹ́ onímọ̀ Mùsùlùmí ti orílẹ̀-èdè Pakistan, òun sì ni ọ̀gá ilé-ìwé Jamia Farooqia. Wọ́n mọ̀ ọ́n gẹ́gẹ́ bíi gbajúgbajà onímọ̀ Mùsùlùmí ní Pakistan.[1]

Khan jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ gboyè ti ilé-ìwé Jamia Farooqia àti University of Karachi, ó sì kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní International Islamic University Malaysia fún ọdún mẹ́jọ, láti ọdún 2010 wọ ọdún 2018. Àwọn agbanipa kan ni wọ́n pa á ní ìtòsí ilé-ìtajà kan ní Shah Faisal Colony, Karachi ní ọjọ́ kẹwàá, oṣù kẹwàá, ọdún 2020.

Ìtàn ìgbésíayé rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bí Muhammad Adil Khan ní ọdún 1957.[2] Òun ni ọmọkùnrin tí Saleemullah Khan bí.[3] Ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè ní ilé-ìwé dars-e-nizami láti ọwọ́ Jamia Farooqia ní ọdún 1973; ó gba B.A nínú ẹ̀kọ́ human science ní ọdún 1976, àti M.A nínú ẹ̀kọ́ Arabic ní ọdún 1978 àti òye PhD nínú ẹ̀kọ́ Islamic culture ní ọdún 1992 láti University of Karachi.[4]

Khan ṣe ìdásílẹ̀ ilé-ìwé Islam ní Lodi, California fún àwọn ọ̀jẹ̀ wẹ́wẹ́. Àwọn ọlọ́pàá ti ìlú US gbé òun àti ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, wọ́n sì ṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò fún wọn kí wọ́n tó dá wọn padà sí ìlú wọn ní ọdún 2005.[5]

Khan ni akọ̀wé fún ilé-ìwé Jamia Farooqia seminary ní ìlú Karachi láti ọdún 1986 wọ 2010.[6] Òun ni ọ̀jọ̀gbọ́n International Islamic University Malaysia from 2010 to 2018.[4] Ó padà lọ sí ìlú Pakistan, lẹ́yìn ikú bàbá rẹ̀ Saleemullah Khan, ní ọjọ́ karùn-úndínlógún, oṣù kìíní, ọdún 2017, ó sì di ọ̀gá ilé-ìwé àti ọ̀jọ̀gbọ́n Hadīth ní Jamia Farooqia.[4][3] Lẹ́yìn náà, ó fi àbúrò rẹ̀, Ubaidullāh Khālid sípò olùdarí ẹ̀ka Shah Faisal Colony ti Farooqia seminary.[7]

Àwọn Àmì-̀ẹ̀yẹ[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Khan gba àmi ẹyẹ ti irawọ mààrun lati ọdọ ilè iwe giga ti Malaysia ni ọdun 2018.[4]

Àwọn ìwé lítíreṣọ̀ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ìwé mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí Khan kọ lórí ìmọ̀ àti ọ̀làjú Islam, Ofin ati Fiqh fun gbógbó èniyan àti Ìwó àgbàyè Islam, wà lára àwọn ìwé tí ó kọ, tí ó wà nínú kòríkúlọ́ọ̀mù Ilè iwè giga ti Islam Malaysia.[2] Àwọn ìwé rẹ̀ mìíràn ni:[2]

  • Tārīkh Islāmi Jamhūriya-e-Pākistān
  • Islām awr Tasawwur-e-Kā'ināt
  • Islām awr Ikhlāqiyāt
  • Ikkīswī Sadī mai Islām
  • al-Maqālāt al-Mukhtārat fī al-Kitāb wa al-Sunnah
  • Islam ati imọ
  • Ófim Islam awr

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "पाकिस्तान के कराची में धर्मगुरू मौलाना आदिल खान की हत्या, इमरान खान ने कहा- भारत शिया और सुन्नी समुदायों में हिंसा कराना चाहता है". Dainik Bhaskar. 11 October 2020. https://www.bhaskar.com/international/news/pakistan-religious-scholar-maulana-adil-khan-shot-dead-in-karachi-imran-khan-blame-india-127802000.html. Retrieved 11 October 2020. 
  2. 2.0 2.1 2.2 Khān, Bādshah (12 October 2020). "Mawlāna Dr Adil Khan". Jeevey Pakistan. https://jeeveypakistan.com/archives/72923. Retrieved 12 October 2020. 
  3. 3.0 3.1 "وزیراعلیٰ سندھ مراد علی شاہ نے جامعہ فاروقیہ کے مہتمم ڈاکٹر عادل خان پر قاتلانہ حملے کا نوٹس لے لیا۔". Geo TV. 10 October 2020. https://urdu.geo.tv/latest/232322-. Retrieved 10 October 2020. 
  4. 4.0 4.1 4.2 4.3 Dogar, Afzal Nadeem. "کراچی میں شہید کیے گئے مولانا عادل خان کون تھے؟". Daily Jang. https://jang.com.pk/news/830314. Retrieved 11 October 2020. 
  5. Gul, Ayaz (10 October 2020). "Top Pakistani Sunni Muslim Cleric Assassinated". Voice of America. https://www.voanews.com/south-central-asia/top-pakistani-sunni-muslim-cleric-assassinated. Retrieved 11 October 2020. 
  6. Khan, Faraz (11 October 2020). "Maulana Adil shot dead in Karachi". The News International. https://www.thenews.com.pk/print/727800-maulana-adil-shot-dead-in-karachi. Retrieved 11 October 2020. 
  7. Dogar, Afzal Nadeem. "شاہ فیصل کالونی میں فائرنگ، معروف عالم دین مولانا عادل ساتھی سمیت شہید". Daily Jang. https://jang.com.pk/news/830297. Retrieved 10 October 2020.