Muka Ray
Mukadas Ray Eyiwumi tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Muka Ray ni ó jẹ́ ọmọ bíbí gbajú-gbajà òṣèré orí-ìtàgé Ray Èyíwùnmí tí wọ́n bí ní ọjọ́ kọkàndínlógún oṣù Kẹrin ní òpópónà "Olúsọjí" ní Ìlú Bàrígà ní Ìpínlẹ̀ Èkó, àmọ́ tí ó àwọn òbí rẹ̀ jẹ́ ọmọ bíbí agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ Ìrẹ́pọ̀ọ́dùn ní Ìpínlẹ̀ Kwara jẹ́ òṣèré orí-ìtàgé, ati sinimá àgbéléwò ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[1]
Ètò-ẹ̀kọ́ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Muka lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ti AUD, ní ìlúÒṣogbo, ó sì lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ girama Aran Orin Comprehensive High School ní Ìpínlẹ̀ Kwara, ṣáájú kí ó tó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ gíga gbogbonìṣe ti Ìpínlẹ̀ Kwara.
Iṣẹ́ rẹ̀.gẹ́gẹ́ bí òṣèré
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Muka bẹ̀rẹ̀ eré ṣiṣẹ́ láti ìgbà èwe.rẹ̀.nígbà tí.ó ti wà.ní ilé-ẹ̀kọ́ girama lábẹ́.ìtọ́ni bàbámrẹ̀.tí ó jẹ́ òṣèré ní àsìkò.ọdún 1970, tí babá rẹ̀ sìa ń fun ní àádọ́ta kọ́bọ̀ nígbà náà gẹ́gẹ́ bí owó ọ̀yà ipa tí ó kó ninú eré. Ó ti kópa nínú eré gẹ́gẹ́ onírànṣẹ́ fún ọba nínú eré Ẹdìẹ bà lókùn.
Àwọn àṣàyàn eré rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- Abọrẹ̀,
- Ọbalúayé,
- 36 Kìnìún,
- Ìyá lalá bàárò àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Muka ti ṣeré pẹ̀lú àwọn òṣèré jànkàn-jànkàn bíi: Alex Usifo, ]Olú Jacobs àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Ẹbí rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Àwọn òbí rẹ̀ ni olóògbé Pa ati abilékọ Ray Èyíwùnmí tí wọ́n bí Muka àti àwọn mẹ́wàá tókù yí:
- Kinsley Ray,
- Lofty Ray,
- Murphy Ray,
- Lasun Ray,
- Moshood Ray
- Waheed Ray,
- Sefifat Ray,
- Shadiat Ray,
- Adijat Ray àti
- Biola Ray.
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Muka Ray". Modern Ghana. 2008-07-23. Retrieved 2020-11-29.