Jump to content

Munkoyo

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Munkoyo [1][2][3] tàbí ibwatu[4] jẹ́ ohun mímu tí ó gbajúgbajà ní ìgbèríko Zambia. Ó jẹ́ ohun mímu tí a máa ń fún tí a ṣe láti ara àsáró àgbàdo àti Rhynchosia venulosa gígún (ní ìbílẹ̀ tí a mọ̀ sí munkoyo) gbòǹgbò.[5] Àpòpọ̀ yìí máa wá di ṣíṣè.[6] Ó lè wá di mímu ní ẹsẹ̀kesẹ̀ lẹ́yìn ṣíṣe tàbí fífi sílẹ̀ láti tọró fún ọjọ́ díẹ̀. Wọ́n sábàá máa ń pè é ní "ọtí dídùn" ní Zambians. Ó tún di rírí ní àwọn orílẹ̀-èdè ààrin gbùngbùn ilẹ̀ Áfíríkà bí Congo níbi tí wọ́n ti ń lò ó gẹ́gẹ́ bí ohun mímu níbi ayẹyẹ ìbílẹ̀ àti gẹ́gẹ́ bí ohun mímu lásán.

Munkoyo ni ó di mímọ̀ pé ó ní ipa ìlera tí ó dára, àti ṣíṣe àlékún ìlera àti vitamin B.

Ìṣẹ̀lẹ̀ ìlera

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ní gbígba gbòǹgbò munkoyo, àwọn olùwágbòǹgbò kan tún máa ń wú àwọn gbòǹgbò tó ní májèlé. Èyí ti fa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn di èrò ilé-ìwòsàn.[7] Irú ìṣẹ̀lẹ̀ báyìí kan ṣẹlẹ̀ ní Solwezi District, tí ènìyàn mẹ́tàdínlógún di èrò ilé-ìwòsàn tí ènìyàn méjì sì di èrò ọ̀run,[8] àti ìṣẹ̀lẹ̀ mìíràn tí ó ṣẹlẹ̀ nítòsí Kitwe èyí tí ó sọ ènìyàn méjìdínlọ́gọ́rùn-ún di èrò ilé-ìwòsàn.[9][6]

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. Keith Steinkraus (4 May 2018). Handbook of Indigenous Fermented Foods, Revised and Expanded. CRC Press. pp. 528–530. ISBN 978-1-351-44251-0. https://books.google.com/books?id=AUxaDwAAQBAJ&pg=PT528. 
  2. Everlon Rigobelo (3 October 2012). Probiotics. BoD – Books on Demand. pp. 176–. ISBN 978-953-51-0776-7. https://books.google.com/books?id=ZG2fDwAAQBAJ&pg=PA176. 
  3. Françoise Malaisse (2010). How to live and survive in Zambezian open forest (Miombo ecoregion). Presses Agronomiques de Gembloux. pp. 289–295. ISBN 978-2-87016-106-7. https://books.google.com/books?id=FcXW4MJUGYkC&pg=PA289. 
  4. Phiri, Sydney; Schoustra, Sijmen E.; Heuvel, Joost van den; Smid, Eddy J.; Shindano, John; Linnemann, Anita (2019-10-22). "Fermented cereal-based Munkoyo beverage: Processing practices, microbial diversity and aroma compounds" (in en). PLOS ONE 14 (10): e0223501. Bibcode 2019PLoSO..1423501P. doi:10.1371/journal.pone.0223501. ISSN 1932-6203. PMC 6805097. PMID 31639127. //www.pubmedcentral.nih.gov/articlerender.fcgi?tool=pmcentrez&artid=6805097. 
  5. Lukwesa Burak (24 December 2018). "World News Today". World News Today (in English). BBC World News. Retrieved 28 May 2024. 
  6. 6.0 6.1 Jongeling, Coretta (13 November 2019). "Beating malnourishment with traditional drinks". Resource online (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 15 July 2024. 
  7. Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named BBCWN2
  8. "Zambia: Munkoyo Kills 2, 17 Hospitalised". Retrieved 31 May 2024. 
  9. Kabaila, Moses. "Times of Zambia | 98 mourners poisoned after drinking munkoyo". Times of Zambia. Retrieved 31 May 2024.