Nadwatul Ulama

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Nadwatul Ulama
Ìdásílẹ̀1893; ọdún 130 sẹ́yìn (1893)
TypeNonprofit organization
IbùjókòóLucknow, India
ManagerBilal Abdul Hai Hasani Nadwi
Websitenadwa.in
Nadwatul Ulama ni Lucknow

Nawatul Ulama jẹ igbìmọ ti awọn ónimọ nipa ẹsin musulumi ti ilẹ India ti a da silẹ ni ọ̀dun 1893 ni Kanpus. Alabóju akọkọ fun ìgbìmọ naa ni Muhammad Ali Mungeri ti Bilal Abdul Hai Hasani Nadwi jẹ̀ Alabójutó isin. Ìgbìmọ naa da ilè ẹkọ Darul Uloom Nadwatul Ulama silẹ̀ ni ọjọ kẹrin dinlọgbọn óṣu September, ọdun 1898[1].

Ìtan[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ni ọ̀dun 1893, Ni agbèjọ ajọdun ti Madrasa Faiz-e-Aam ni Kanpur, awọn ónimọ ẹsin musulumi sowọpọ da igbimọ Nadwatul Ulama silẹ ti wọn si pinu lati ṣè ipade akọkọ ni ọdun to tẹle. Awọn to lọsi ipade naa ni Mahmud Hasan Deobandi, Ashraf Ali Thanwi, Khalil Ahmad Saharanpuri, Muhammad Ali Mungeri, Sanaullah Amritsari, Fakhrul Hasan Gangohi, Aḥmad Ḥasan Kanpuri ati bẹbẹlọ[2].

Ìdi ti agbèkalẹ igbimọ naa bẹrẹ ni lati yii ètọ ẹkọ pada ati lati dena órìsíriṣi ija ẹsin larin musulumi pẹlu iyatọ[3]. Muhammad Ali Mungeri, jẹ àlàbójutó akọkọ ti ó da igbimọ naa silẹ[4].

Ìgbade akọkọ ti ìgbimọ Nadwatul Ulama waye larin ọjọ keji lèèlogun ati ọjọ kẹrin lèèlogun, óṣu April ọdun 1894 ni Madrasa Faiz-e-Aam. Muhammad Ali Mungeri mu àbà dida Darul Uloom silẹ labẹ àkósó Nadwatul Ulama nibi to ti fi iwè naa lelẹ ni ọjọ kejila, óṣu Muharram 1313 AH gẹgẹbi "Musawwada-e Darul Uloom"[5].

Iwè yii wọn fi ọwọ si ni óṣu April,ọdun 1896 ni igbade apapọ kẹta ti Nadwatul Ulama ni Bareilly. Darul Uloom ti wọn dasilẹ̀ labé àkósó Nadwatul Ulama ni a peni Darul Uloom Nadwatul Ulama.

Ìdasilẹ Darul Uloom[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Muhammad Ali Mungeri lọsi Lucknow pẹlu awọn ònimọ ẹsin Habibur Rahman Khan Sherwani ati Zahoorul Islam Fatehpuri lati wa ilẹ fun idasilẹ Darul Uloom Nadwatul Ulama[6].

Munshi Ehtesham Ali yanda ilẹ rẹ fun ilè ẹkọ naa. Koti pè idasilẹ rẹ bẹrẹ, arakunrin naa ra ilè nla ni Gola Ganj to di file ọwọ Nadwatul Ulama, èyi lo mu ki ibi iṣẹ ìgbimọ naa yipada si Lucknow ni ọjọ kèji, óṣu September, ọdun 1898[6].

Ilè iwe akọ bẹrẹ ni ọjọ kẹrin dinlọgbọn, óṣu september ni ọdun 1898 bẹrẹ sini ṣiṣẹ̀. Darul Uloom Nadwatul Ulama jẹ ọkan lara ilẹ iwè ónimọ ẹsin musulumi to gbajumọ ni ilẹ̀ India[7].

Awọn Àlabojuto[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Muhammad Ali Mungeri ni alàbojutọ akọkọ fun Nadwatul Ulama ni igba ti wọn kọkọ dasilẹ ti Masihuzzaman Khan si dele rẹ gẹ̀gẹbi alabojuto ti Interim fun ọdun mẹta nibi to fi ipo naa silẹ ni ọjọ ọkan dinlogun, óṣu July, ọdun 1903[8][9].

Khalilur Rahman Saharanpuri di alabojuto lati ọdun 1905 si óṣu July, ọdun 1905 ti Abdul Hai Hasani si di alabojutó. Ali Hasan Khan di alabojuto lẹyin iku Hasani to si dari ipade mẹrin to waye ni Nadwatul Ulama[10].Ni ọjọ kẹsan, óṣu June ọdun 1931, Hakeem Abdul Ali di àlàbójutó fun ọgbọn ọdun[11].

Abul Hasan Ali Hasani Nadwi dèlè Abdul Ali gẹ̀gẹbi alabojutó ni ọdun 1961[12] . Rabey Hasani Nadwi di alabojutó ti Nadwatul Ulama ni ọdun 2000[13] ti Bilal Abdul Hai Hasani Nadwi si dèlè rẹ lẹyin to ku ni ọjọ kẹtala, óṣu April, Ọdun 2023[14].

Awọn Itọkasi[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

al-Hasani, Sayyid Muḥammad (May 2016). Sīrat Hadhrat Mawlāna Muḥammad Ali Mungeri: Bāni Nadwatul Ulama (in Urdu) (4 ed.). Lucknow: Majlis Sahāfat-o-Nashriyāt, Nadwatul Ulama.

Khan, Shams Tabrez (2015). Tārīkh Nadwatul Ulama (in Urdu). Vol. 2. Lucknow: Majlis Sahāfat-o-Nashriyāt.

al-Hasani, Sayyid Muḥammad (May 2016). Sīrat Hadhrat Mawlāna Muḥammad Ali Mungeri: Bāni Nadwatul Ulama (in Urdu) (4 ed.). Lucknow: Majlis Sahāfat-o-Nashriyāt, Nadwatul Ulama.

  1. "Darul Uloom Nadwatul Ulama Lucknow India". Nadwatul Ulama. 2022-11-11. Retrieved 2023-09-13. 
  2. al-Hasani 2016, p. 107-108.
  3. Khan, Ghazanfar Ali (2001). "Nadvat_al_Ulama: a centre of islamic learning". Aligarh. Retrieved 2023-09-13. 
  4. al-Hasani 2016, p. 109.
  5. al-Hasani 2016, p. 130.
  6. 6.0 6.1 al-Hasani 2016, p. 169-170.
  7. Ḵh̲ān, Ẓafarul-Islām (2012-04-24). "Nadwat al-ʿUlamāʾ". Brill. Retrieved 2023-09-13. 
  8. Khan 2015, p. 31.
  9. al-Hasani 2016, p. 238.
  10. Khan 2015, p. 242.
  11. Khan 2015, p. 402.
  12. "Nadwi on Maududi: a traditionalist maulvi's critique of Islamism". Two Circles. 18 May 2008. https://twocircles.net/2008may17/nadwi_maududi_traditionalist_maulvi_s_critique_islamism.html. 
  13. AFM Sulaiman (2011). Indian contributions to Arabic literature - a study on Mohd Rabe Hasani Nadwi. p. 82. https://shodhganga.inflibnet.ac.in/handle/10603/92992. Retrieved 6 July 2021. 
  14. "Nadwatul Ulama appoints Maulana Bilal Abdul Hai Hasani as new nazim". The Chenab Times. 15 April 2023. https://thechenabtimes.com/2023/04/15/nadwatul-ulama-appoints-maulana-bilal-abdul-hai-hasani-as-new-nazim/.