Nafisa Abdullahi

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Nafisat Abdullahi
Ìbí23 Oṣù Kínní 1992 (1992-01-23) (ọmọ ọdún 32)
Jos, Plateau State
Iṣẹ́Actor

business woman

photographer
Websitehttp://www.nafisatu.com[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]

Nafisat Abdulrahman Abdullahi ti gbogbo eniyan mọ si Nafisat Abdullahi (bii ni ojo ketalelogun, osu kiini, odun 1992), jẹ oṣere[1], adari, oluyaworan ati oniṣowo lati ilu Jos, ni ipinle Plateau ni orile ede Naijiria[2][3]. Nafisat gboye ninu eko ere ori itage lati ile eko giga ti University of Jos. O ti gba ọpọlọpọ awọn ẹbun bi Afro Hollywood Award (2017), MTN Award (2016), AMMA Award (2015) ati City People Entertainment Entertainment Award ni ọdun 2013 fun oṣere ti o dara julọ. O gba ẹbun lati owo Kannywood Award ni odun 2014 fun oṣere obirin ti o dara julọ ni Kannywood.[4][5][6] Nafisat bere si ni se ere ori itage lati igba ti o ti wa ni omo odun mejidilogun, o si ko ipa to tayo julo ninu ere Sai Wata Rana ni odun 2010. Ni odun 2012, Nafisat kopa ninu ere Blood and Henna won si pe fun ebun mefa ni ayeye Africa Movie Academy Awards. o kopa ninu ere Lamiraj eyi ti o je ki o fi gba ebun osere obirin ti o dara julo ni odun 2013.

Iberepepe aiye re[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Won bi Nafisa si ilu Plateau ni orile ede Naijiria. Oun ni omobirin kerin fun ogbeni Abdulrahman Abdullahi ti o je onisowo onimoto. O lo si ile eko ti Air Force Private School ni ilu Jos ki o to tesiwaju si ile eko Government Girl Secondary School ni ilu Dutse ni ipinle Abuja. O lo si ile eko giga ti University of Jos ni ibi ti o ti gboye ninu ere ori itage.

Awon Itokasi[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. PremiumTimes Newspaper. "Nafisa Abdullahi Suspended from acting". Retrieved 21 April 2015. 
  2. PremiumTimes Newspaper. "Kannywood Producers Lift Suspension On Nafisa". Retrieved 21 April 2015. 
  3. Premiumtimesng.com. "Nafisa Abdullahi confirms romance with Adam Zango". Retrieved 16 June 2015. 
  4. "Actress Nafisa Abdullahi Full Biography (Kannywood)". 17 March 2017. 
  5. tns.org. "Ali Nuhu, Nafisa Abdullahi, late Ibro shine at Kannywood awards". Retrieved 21 April 2015. 
  6. "KANNYWOOD AWARD 2015 The full event".