Namibia: The Struggle for Liberation
Namibia: The Struggle for Liberation | |
---|---|
Adarí | Charles Burnett |
Olùgbékalẹ̀ | Namibian Film Commission Pan Afrikan Center of Namibia |
Àwọn òṣèré | Carl Lumbly Danny Glover Chrisjan Appollus Lazarus Jacobs |
Orin | Stephen James Taylor |
Ìyàwòrán sinimá | John Njaga Demps |
Olóòtú | Edwin Santiago |
Déètì àgbéjáde | 2007 |
Àkókò | 161 minutes |
Orílẹ̀-èdè | Namibia United States |
Èdè | English Afrikaans Oshiwambo Otjiherero German |
Namibia: The Struggle for Liberation jẹ́ fíìmù ìlú Namibia tó jáde ní ọdún 2007. Fíìmù yìí dá lórí ìgbòmìnira orílẹ̀-èdè Namibia ní ìtako pẹ̀lú South Africa. Ó sọ ìtàn Sam Nujoma, tó jẹ́ olórí SWAPO, ìyẹn South West Africa People's Organisation àti Ààrẹ àkọ́kọ́ ti ìlú Namibia. Charles Burnett ló kọ fíìmù yìí, tó sì dárí rẹ̀. Lára àwọn ọ̀ṣèré fíìmù náà ni Carl Lumbly àti Danny Glover.[1] Ìjọba Namibia ló gbé gbogbo owó tí wọ́n fi ṣe fíìmù yìí.[2] Stephen James Taylor ló kọ orin tí wọ́n lò nínú fíìmù yìí. Fíìmù yìí gba àmì-ẹ̀yẹ fún fíìmù ilẹ̀ Africa tó dára jù lọ ní Kuala Lumpur International Film Festival, níbi tí ó sì gba àmì-ẹ̀yẹ fún orin inú fíìmù tó dára jù àti olùdarí tó dára jù.
Wọ́n tú fíìmù yìí sí èdè Gẹ̀ẹ́sì, Afrikaans, Oshiwambo, èdè Herero, Otjiherero, àti German.[3][4]
Àhunpọ̀ ìtàn
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Carl Lumbly ló ṣe ẹ̀dá-ìtàn ajà-fún-ètò-òmìnira ti ilẹ̀ Namibia, àti Ààrẹ̀ àkọ́kọ́, ìyẹn Sam Nujoma. Joel Haikali ni wọ́n lò láti ṣe ìgbà èwe Sam Nujoma. Danny Glover ló ṣe priest Elias, tó padà di ọ̀rẹ́ Sam Nujoma nínú erẹ́ náà.
Àgbéjáde
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Owó tí wọ́n fi gbé fíìmù yìí jáde tó 100 million, tí iye rẹ̀ ní dọ́là tó US$ 15 million. Ìjọba Namibia ló sì gbé gbogbo owó tí wọ́n fi ṣe fíìmù yìí.[5] Àwọn èdè tí wọ́n tú fíìmù náà sí ni èdè Gẹ̀ẹ́sì, Afrikaans, Oshivambo, Otjiherero àti German.
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "AML - support.gale". www.accessmylibrary.com. Retrieved 9 February 2018.
- ↑ "CNN.com - Transcripts". transcripts.cnn.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 9 February 2018.
- ↑ [1], Lauren Wissot, "Slant Magazine", 7 April 2008,
- ↑ Review: Namibia: The Struggle For Liberation, Robert Koehler, Variety, 29 June 2007.
- ↑ Uazuva Kuambi (November 2005), "Namibia: Where Others Wavered … the Filming of an Epic Movie on the Life of Former President Sam Nujoma and the Country's Liberation Struggle Has Just Been Completed", New African (Uazuva Kuambi, the Executive Producer, Reports on How It All Came about and the Obstacles His Production Team Encountered) (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì), 445, archived from the original on 10 December 2015, retrieved 2013-11-22