Jump to content

Nasiru Kabara

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Nasiru Muhammad Al-Muktar Kabara' tí àwọn kan tún mọ̀ sí Nasiru Kabara, (18 April 1924 - 1996) jẹ́ onímọ̀ Islam, àti onímọ̀ ti Qadiriyya, bẹ́ẹ̀ sì ni ó jẹ́ olùdásílẹ̀ Darul Qadiriyya ní Kano, òun sì ni adarí Qadiriyya ní West Africa nígbà kan rí.[1] Lẹ́yìn tí ó kúrò lórí ipò yìí, ọmọ rẹ̀ Qaribullahi Nasiru Kabara ló gorí oyè náà. Bákan náà, òun ni bàbá onímọ̀ Islam kan, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Abduljabbar Nasiru Kabara.[2]

Wọ́n bí Nasiru Muhammad Al-Muktar Kabara ní Guringawa ní Ipinle Kano.[1] Bàbá bàbá-bàbá rẹ̀ ni a gbọ́ pé ó wá láti Kabara kan tó súnmọ́ odò Niger lẹ́yìn ti Jihad ti Usman Dan Fodio ní (1804-8), ibẹ̀ sì ni wọ́n ti ṣí wá sí ilẹ̀ Hausa, tí wọ́n sì lọ sí Kano emirate ní eighteenth century, níbi tí wọ́n wá tẹ̀dó sí gẹ́gẹ́ bí ọba, nígbà tí wọ́n yan ibìkan fún un láti dé sí. Agbègbè náà sì ni ó di Kabara ward "Unguwar Kabara" lóni.[3]

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. 1.0 1.1 "Sheikh Nasir Muhammad Kabara". www.rumbunilimi.com.ng. Retrieved 2021-08-03. 
  2. "Ku San Malamanku tare da Sheikh Abduljabbar Kabara". BBC News Hausa (in Èdè Hausa). 2020-11-06. Retrieved 2021-08-03. 
  3. "Teachings and writings of Nasuru Kabara" (PDF).