Ngardy Conteh George
Ngardy Conteh George | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Ngardy Conteh Freetown, Sierra Leone |
Orílẹ̀-èdè | Sierra Leonean-Canadian |
Iléẹ̀kọ́ gíga | University of New Orleans |
Iṣẹ́ | Film director, film producer, editor |
Ìgbà iṣẹ́ | 2004-present |
Olólùfẹ́ | Philman George |
Àwọn ọmọ | 2 |
Ngardy Conteh George (tí a bí ní ọdún 1979) jẹ́ olùdarí eré àti olóòtú ọmọ orílẹ̀-èdè Siẹrra Léónè àti Kánádà
Ìsẹ̀mí rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ìlú Freetown ni wọ́n bí George sí, ṣùgbọ́n ó lọ sí ìlú Kánádà ní àsìkò ìgbà èwe rẹ̀. Ó lọ sí Yunifásitì ìlú New Orleans pẹ̀lú owó-ìrànlọ́wọ́ ìwé kíkà.[1] Lẹ́hìn ìparí ẹ̀kọ́ rẹ̀, ó gbájúmọ́ iṣé fíìmù ṣíṣe tó sì n sọ àwọn ìtàn nípa fífọ́nká àwọn ọmọ ilẹ̀ Áfríkà.[2] Ní ọdún 2004, ó ṣe adarí fíìmù fún ìgbà àkọ́kọ́ rẹ̀ nígbà tí ó fi dári eré tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Soldiers for the Streets, èyí tí n ṣàlàyé nípa akitiyan Ras King láti kọ́ àwọn ọ̀dọ́ lẹ́kọ̀ọ́.[3] Ó ṣe adarí eré oníìrírí tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Literature Alive ní ọdún 2005. Yàtọ̀ sí ṣíṣe adarí eré, George tún ti ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bi olóòtú fún àwọn eré bíi I Want to Be a Desi (apà kejì), Something Beautiful, Arts & Minds, Food & Drink TV àti The Marilyn Denis Show fún ìkànnì CTV.[4] Láti ilé-iṣẹ́ rẹ̀ tí ó pè ní Mattru Media, ó ṣe àgbékalẹ̀ ètò tẹlifíṣọ̀nù kan tí a pè ní The Rhyming Chef Barbuda.[5]
Ní ọdún 2008, ó darí eré tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ The Circle of Slavery pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn ọ̀rẹ́ àti àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ ní Siẹrra Léónè. Eré náà dá lóri àwọn ìbátan àtijọ́ tí ó wà láàrin orílẹ̀-èdè Siẹrra Léónè ati Kánádà.[6] Ní ọdún 2014, George darí eré The Flying Stars pẹ̀lú owó tí Sundance Documentary Film Fund gbé kalẹ̀. Eré náà gba àmì-ẹ̀yẹ eré ìrírí tí ó dára jùlọ níbi ayẹyẹ BronzeLens Film Festival ti ọdún 2015.[7]
Àwọn àṣàyàn eré rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- Soldiers for the Streets (2004)
- Literature Alive (2005)
- The Circle of Slavery (2008)
- The Rhyming Chef Barbuda (2009)
- The Flying Stars (2014)
- Dudley Speaks for Me (2016)
- Mr. Jane and Finch (2019)
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Ngardy Conteh George" (PDF). CIBWE. Retrieved 12 October 2020.[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
- ↑ "Ngardy Conteh George - Biography". African Film Festival New York. Retrieved 11 October 2020.
- ↑ "Soldiers for the Streets". National Film Board of Canada. 15 August 2017. Archived from the original on 30 November 2021. Retrieved 11 October 2020.
- ↑ "Ngardy Conteh George - Biography". African Film Festival New York. Retrieved 11 October 2020.
- ↑ "OYA Media Group on Canadian Screen Awards Win, Mr. Jane and Finch, and Future Plans". Enspire. 3 August 2020. Retrieved 11 October 2020.
- ↑ "Ngardy Conteh George" (PDF). CIBWE. Retrieved 12 October 2020.[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
- ↑ "Ngardy Conteh George". Canadian Film Centre. Archived from the original on 30 November 2021. Retrieved 11 October 2020.