Jump to content

Àwọn èdè Niger-Kóngò

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(Àtúnjúwe láti Niger-Congo languages)
Niger-Kóngò
Niger–Kordofanian (obsolete)
Ìpínká
ìyaoríilẹ̀:
Sub-Saharan Africa
Ìyàsọ́tọ̀:one of the world's primary language families
Àwọn ìpín-abẹ́:
Katla (Kordofanian)
Rashad (Kordofanian)
Atlantic–Congo (noun classes)
ISO 639-2 and 639-5:nic

Map showing the distribution of Niger–Congo languages (yellow). The area is divided into B (Bantu) and A (rest) to show the extent of the Bantu subfamily.

Àkójọpọ̀ èdè tí a mọ̀ sí Niger-Congo dín mẹ́rin ni òjì-lé-légbéje. Grimes (1996) ríi gẹ́gẹ́ bíi èyí tí ó tóbi jùlọ ní àgbáyé àti wí pé àwọn èèyàn tí ó ń sọ ọ̀kan tàbí èkejì nínú. àwọn èdè yìí fọ́n ká orílẹ̀ ayé ju àwọn ìyókù akẹgbẹ wọn lọ. Ní orílè èdè Afíríkà, àwọn èdè tí ó ní èèyàn tí ó pọ̀ jùlọ ni wọ́n jẹ́ èyí tí a lè rí ní abẹ́ àkójọpọ̀ èdè Niger-Congo. Bí àpẹẹrẹ, èdè tí ó tóbi jùlọ ni Senegal, Wolof jẹ́ ọ̀kan lára àwọn èdè Niger-Congo; Fulfude tí ó tàn káàkirí ìwọ̀ oòrùn àti àárín gbùngùn Afíríkà, ọkan níbẹ̀ ni. Bẹ́ẹ̀ náà ni èdè Manding tí ó gbajú gbajà ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀ èdè ní ìwọ̀ oòrùn Áfíríkà bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé onikaluku ni ó ní orúkọ tí ó ń pe èdè yìí, oun náà sì ni a mọ̀ ṣí Bambara tí ó jẹ́ èdè orílè èdè àti ìjọba Mali àti Dyala, èdè Okòwò gbalé-gboko. A kò gbọdọ̀ gbàgbé Akan ní orílẹ̀ èdè Ghana. Yorùbá àti Igbo náà kò gbẹ́yìn níbẹ̀, èdè pàtàkì ni méjèèjì yìí ní orílẹ̀ èdè Nàìjiria. Ní àárín gbùngbùn Áfíríkà, èdè Sango ni wọ́n ń sọ. Àwọn èdè Bantu bíi Ganda, Gikuyu, Kongo, Lingala, Luba-Kasari, Luyia, Mbundu (Luanda), Northern Sotho, Sukuma, Swahili, Tsonga, Tswana, Umbundu, Xhosa ati Zulu. Ó tó èèyàn bíi Mílíọ̀nù lọ́nà ọtà-lé-lọ́ọ̀dúnrún sí Mílíònù irínwó tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ tí wọ́n ń sọ èdè Niger Congo ní Áfíríkà, gẹ́gẹ́ bí Grimes (1996) ṣe sọ.

IṢẸ́ ÌWÁDÌÍ LÓRÍ ÌPÍN ÈDÈ NIGER-CONGO

Ọkan gbòógì lára àwọn èdè tí a rí lára ìpín èdè Niger-Congo ni àkójọpọ̀ èdè Bantu jẹ́. Àwọn èdè yìí gbalẹ tààrà ní ilẹ̀ Áfíríkà, wọ́n sì jọra gidi. Ní abẹ́ gírámà rẹ, a ríi wí pé àwọn ọ̀rọ̀ orúkọ inú àwọn èdè yìí jọra gan-an, èyí ni ó sì mú àwọn onímọ̀ tí ó jẹ́ aláwọ̀ funfun fi ara balẹ̀ ṣe iṣẹ́ ìwádìí ní orí àwọn èdè wọ̀nyí. Koelle àti Bleek sọ wí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀yà èdè tí àwọn ènìyàn ìwọ̀ oòrùn Áfíríkà ń sọ ni ó ní ọ̀rọ̀ orúkọ tí a sẹ̀dá nípa àfòmọ́ ìbẹ̀rẹ̀. Nínú ìwádìí tirẹ̀, Meinhof sa awọn èdè kan jọ tí wọ́n fi ara pẹ́ ara wọn láti ara ọ̀rọ̀ orúkọ wọn ṣùgbọ́n tí gírámà wọn yàtọ̀ díẹ̀. Èyí ni òún pè ní ‘Semi-Bantu’. Westerman ṣe iṣẹ́ tí ó jọ mọ́ ti Meinhof díẹ̀. Ní tirẹ̀, ó se ìpìnyà láàrin àwọn èdè tí ó farahàn ní ìlà-oòrùn àti ìwọ̀-oòrùn ilẹ̀ Sudan. Ó ṣe àkíyèsi àwọn èdè kan tí a rí ní apá ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ Sudan; àwọn náà ni ó pín sí ìsọ̀rí mẹ́fà: Kwa, Benue-Cross, Togo, Gur, Mandingo, àti ti ìwọ̀ oòrùn Àtìláńtíìkì. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ sílébù nínú àwọn èdè wọ̀nyí ni wọ́n jé ‘CV’. Greenberg yapa díẹ̀ nínú èrò ti rẹ̀. Ó ṣe àtúnpín àwọn èdè wọ̀nyí láàrín ọdún 1949 sí 1954. Ní tirẹ̀, ó pín Bàntú àti ìwọ̀ oòrùn Sudan sí ọ̀nà kan ṣoṣo tí ó pè ní Niger-Congo, ó sì ṣe àdáyanrí ìlà oòrùn Sudan sí ìsọ̀rí mìíràn ọ̀tọ̀, ó pè é ni Nilo-Saharan. Iṣẹ́ rẹ̀ sì fi ara pẹ́ ti Westerman tààrà ní abẹ́ ìsọ̀rí yìí. Àwọn kókó inú iṣẹ́ Greenberg ni ìwọ̀nyí:

(a) Orúkọ Mandigo yí padà sí Mande

(b) Àárín gbùngbùn Togo di ara Kwa

(d) Benue-Cross yí padè di Benue-Congo

(e) Bantu di ìsọ̀rí kan lábẹ́ Benue-Congo

(ẹ) Fulfude di ara ìsọ̀rí ìwọ̀ oòrùn Àtìláńtíìkì; Serer àti Wolof sì di ara kan náà pẹ̀lú fulfude.

(f) Adamawa kún àkójọpọ̀ èdè yìí


(g) Ní ọdún 1963, Kordofanian kúrò ní èdè Kòtó-ǹ-kan ó di ọ̀gbà kan náà pẹ̀lú Niger-Congo. Orúkọ wá yí padà, ó di Niger-Kordofanian (tàbí Congo-Kordofanian).

Greenberg fura sí ipe èdè àwọn èdè wọ̀nyí, ó sì tọ́ka síi wí pé /ףּ/. Kordofanian ati /m/ Niger-Congo jọ ara wọn. Èyí sì máa ń jẹyọ dáadáa nínú àwọn àfòmọ́ ìbẹ̀rẹ̀ àti àwọn ọ̀rọ̀ Kòsemánìí kan nínú àwọn èdè yìí. Lẹ́yìn Greenberg ni Mukarovsky ṣe àtúpalẹ̀ àti àtúnpín àwọn èdè yìí, Ó yọ Kordofanian, Mande, Wolof-Serer-Fulfulde, Ijoid àti Adamawa kúrò níbẹ̀; àwọn ìyókù ni ó sì pè ní ‘Western Nigritic’. Ayé sí tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ yìí gan-an ni láàrín àwọn olùwádìí ìjìnlẹ̀. Àtúnṣe gbòógì wáyé láti ọwọ Bennett àti Sterk (1977), Wọ́n fi ojú lámèyítọ́ wo àwọn ọ̀rọ̣̀ orúkọ tí ó fara jọ ara wọn nínú àwọn èdè wọ̀nyí. Ìgbàgbọ́ wọn ni wí pé Kordofanian àti Mande ti yà kúrò lara wọn. Lẹ́yìn èyí ni ìwọ̀ oòrùn Àtìláńtíìkì yà kúrò lára ìsọ̀rí èdè yìí tí a sì fún àwọn tí ó kù ní orúkọ ààrín gbùngbùn Niger-Congo. Ara àwọn wọ̀nyí ni Ila-oòrùn Adamawa, Gur, Kru àti Ijọ wà. Ọ̀kan gbòógì iṣẹ́ lórí ìwádìí yìí ni The Niger-Cong Languages (Bender – Samuel 1989) jẹ́. Àgbékalẹ̀ ìsọ̀rí èdè Niger-Congo gẹ́gẹ́ bí a ti mọ lónìí ni a ṣe àtẹ rẹ̀ sí ìṣàlẹ̀ yìí (Boyd 1989) nípa lílò àlàyé fún ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn.


Nínú atẹ yìí a rí, ‘Proto-Niger-Congo’ nínú èyí tó jẹ́ wí pé ‘Kordofanian’ ni ìsọ̀rí àkọ́kọ́ tí ó kọ́kọ́ yapa. Mande àti iwọ oòrùn Atlantic ni ìsọ̀rí kejì tí ó tún yapa bẹ́ẹ̀, èyí tí wọ́n fi hàn wá lábẹ́ ‘Proto-Mande-Atlantic-Congo’. Àwọn èyí tí ó tún dàbí rẹ̀ ni àwọn tí wọ́n pín sí abẹ́ ìsọ̀rí ààrín gbùngbùn Niger-Congo. Láti ara ‘Proto-Ijo-Congo’ ni ‘Ijoid’ ti yapa, lábẹ́ rẹ̀ ni a tí rí Ijọ ati Defaka. Lábẹ́ ‘Proto-Ijọ-Congo’, a rí ‘Proto-Dogon-Congo’ èyí tí Dogon yapa láti ara rẹ̀. Lábẹ́ ‘Proto-Dogon-Congo’, a rí ‘Proto-Volta-Congo’ tí ó pín sí ìwọ̀ oòrùn Vota-Congo àti ìlà oòrùn Volta Congo (Proto-Benue-Kwa). Ní a pá ìwọ̀ oòrùn Volta-Congo ni a ti wá rí Kru, Pre, Senufo; ààrin gbùngbùn Gur àti Adawawa (Bikirin, Day, Kam ati Ubangi). A lè pè é ní Gur-Adamawa. Ní apá ìlà oòrùn, ni a ti rí ààrín gbùngbùn orílè èdè Nìjíríà tí òhun náà tún yapa, a sì rí Bantoid Cross lábẹ́ Ìlà oòrùn yìí. Lára Bantoid Cross yìí ni Cross River ti yapa, nígbà tí a wa rí Bantoid lábẹ́ Bantoid Cross.

KORDOFANIAN

Ní agbègbè orí òkè Nuba ní orílẹ̣̀ èdè Sudan ni àwọn ènìyàn tí ó n sọ èdè yìí wọ́pọ̀ sí jùlọ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ogun àti ọ̀tẹ̀ ti fọ́n ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn yìí ká. Àtẹ ìṣàlẹ̀ yìí ni ó ṣe àkójọpọ̀ àwọn ìsọ̀rí èdè tí ó wà ní abẹ́ ori èdè Kordofanian.

Nínú àtẹ yìí a rí ‘Proto-Kordofanian’ tí ó pín sí ìsọ̀rí mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀: Heiban, Tahodi, Rashad, Katla. Heiban pín sí Ìlà Oòrùn (Ko, Warnang); ààrín gbùngbùn (Koalib, Logol, Laru, Ebang, Utoro); lààrín ‘Central àti west’ a rí shirumba; Ní ìwọ̀ oòrùn (Tiro àti Moro). Talodi: lábẹ́ Tolodi, a rí Ngile (Masakin) àti Dengbebu, Tocho, Jomang, Nding, Tegem. Rashad: lábẹ́ rẹ̀ ni Tagoi àti Tagali wà. Katla: lábẹ́ rẹ̀ ni kalak (Katla) àti Lomorik (Tima).

MANDE

Ìwọ̀ oòrùn Áfíríkà ni àwọn ènìyàn tí ó ń sọ èdè yìí Sodo sí jùlọ. Àwọn ìhú tí a sì ti rí àwọn tí èdè wọn pẹ̀ka láti ara orí èdè yìí ni Mali, Cote d’Ivoire, Sierra Leone, Liberia, Burkina Faso, Senegal, Gambia, Guinea Bissan, Mauretania, Banin, Ghana, Togo ati Nigeria (Dwyer 1989; Kastenholz 1991/2). Ó tó ènìyàn bíi mílíọ̀nù mẹ́wàá sí méjìlá tí wọ́n ń sọ ọ́.

Nínú àtẹ yìíu a rí ‘Proto-Mande’ tí ó pín sí ìwọ̀ oòrùn àti ìlà oòrùn ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀. A wá rí ìwọ̀ oòrùn fúnrarẹ̀ tí ó tún wá pín sí ààrín gbùngbùn tàbí Gúúsù-ìwọ̀ oòrùn àti Àríwá ìwọ̀ oòrùn. Láti ara ààrín gbùngbùn tàbí Gúúsù-ìwọ̀ oòrùn ni a ti rí: Mandaing ati Koranko, Vai àti Kono, Jogo (Ligbi, Nnmu, Atumfuor, Wela) àti Jeri, Sooso àti Yalunka, Kpelle, Loomu, Bandi, Mande ati Loko. Láti ara àríwá-ìwọ̀ oòrùn ni a ti rí Sorogama àti Tieyaxo, Tiema Cewe, hainyaxo, Soninke (Azer), Bobo (Sya), Dzuun (Samogo-Guan) àti Sembia, Jo (Samogo-Don). Ní ìlà Oòrùn a rí : Mano, Dan (Yakuba, Gio) àti Tura (Wen), Guro (Kweni) àti Yanre, Mwa àti Wan (Nwa), Gban àti Beng (Gan). Bákan náà, ni a rí: Bisa, Sane (Samogo-Tongan, Maya) àti San(South Samo, Maka), Busa (Bisa, Boko), Shanga àti Tyenga.

ÀTÌLÁŃTÍÌKÌ

Gẹ́gẹ́ bí orúkọ rẹ̀ ti fi ara hàn ìwọ̀ oòrùn Áfíríkà, ní ẹ̀bá òkun Àtìláńtíìkì ni èdè yìí sodo sí jùlo. Ó fọ́nká láti ẹnu odò Senegal títí dé orílẹ̀ èdè Liberia. Díẹ̀ lára àwọn èdè tí ó pẹ̀ka sí abẹ́ orí èdè yìí ni a ti rí: Fulfulde, Wolof, Diola, Serer àti Remne. Sapir (1971) ni ó ṣe àgbékalẹ̀ àtẹ ìsàlẹ̀ yìí: Fig 2.4. Nínú àtẹ yìí a rí ‘Proto-Atlantic’ tí ó pín sí Àríwá àti Gunsu. Ní àríwá ni a ti rí Fulfulde àti Wolof, Serer, Cangin, Diola ati Pupel, Balanta, Bassari/Bedik ati Konyagi, Biafada/Pajade, Kobiana/Kasanga àti Banyin, Nalu, Bijago(Proto-Atlantic), Sua, Temne, Sherbro àti Gola, Limba. IJOID Apá gúúsù ilẹ̀ Nigeria ni a ti rí àwọn tí wọ́n ń sọ èdè yìí. Èdè náà ni a mọ̀ sí Defaka àti Ijọ. Jenewari àti Williamson (1989) ni wọ́n ṣe àgbékalẹ̀ àtẹ isálẹ̀ yìí Fig 2.5. Nínú àtẹ yìí, a rí ‘Proto-Ijoid’ tí ó pín sí Defaka ati Ijọ. Ijọ pín Ìlà-oòrùn àti ìwọ̀ oòrùn. Lábé ìlà-oòrùn ni a ti rí: Nkọrọ, Ibani, Kalabari, Kirike (Okrika), Nembe ati Akaha(Akassa). Lábẹ́ ìwọ̀-oòrùn ni a ti rí : Izon, Biseni, Akita (Okordia), Oruma.

DOGON

Àwọn ènìyàn bíi ìdajì mílíọ̀nù tí a bá pàdé ní ilẹ̀ Mali àti Burkina Faso ni wọ́n n sọ èdè yìí. Bendor-Samuel àti àwọn ìyókù (1989) ni ó gbé àtẹ yìí kalẹ̀. Fig 2.6. Ínú àtẹ yìí, a rí ‘Proto Dogon’ ti o pín ṣi ìsọ̀rí mẹfa. Àwọn ìsọ̀rí náà nìwọ̀n yìí (a) Plain - Jamsay tegu, Toro teju, Tene ka, Tomo ka (b) Escarpment - Toro sọọ, Tombaco sọọ, Kamba sọọ (d) West - Dulerí dom, Ẹjẹngẹ dó (e) North west - Bangeri Me (ẹ) North Platean - Bondum dom. Dogul dom (f) Ìsọ̀rí kẹfà ni Yanda dom, Oru yille àti Naya tegu.

ARIWA VOLTA-CONGO Kru, Gur àti Adamawa-Ubangi ni àwọn ẹ̀ka èdè tí a lè rí ní abẹ́ ìsọ̀rí ‘ARIWA VOLTA-CONGO’ bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé àwọn èdè yìí ti fọ́nká orílẹ̀ KRU Orílẹ̀-èdè Cote d’Ivoire àti Liberia ni a ti lè rí àwọn ènìyàn tí wọ́n ń sọ èdè yìí. Ó tó ènìyàn bíi mílíọ̀nù kan sí méjì tí wọ́n ń sọ èdè yìí. Tí a bá wo àtẹ ìsàlẹ̀ yìí, a ó ṣe alábápàdé àwọn èdè bíi Kuwaa, Tiegba, Seme àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ lára orí èdè ‘Kru’. Fig 2.7. Nínú àtẹ yìí a rí ‘Proto-Kru’ tí ó pín sí ìsọ̀rí mẹ́ta. Àwọn ìsọ̀rí náà nìwọ̀n yìí (a) Ìlà-oòrùn - Godie àti Kouya, Dida, Kwadia, Bakwe ati Wane. (b) Ìwọ̀-oòrùn - Grebo complex, Guere complex, Bassa, Klao (d) Ìsọ̀rí kẹ́ta ni àwọn bíi Kuwaa, Tiegba, Abrako, Seme. GUR Èdè yìí gbajú gbajà dáadáa àti wí pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ni ó ń sọ èdè yìí ní orílẹ̀ ayé. A lè rí àwọn ènìyàn tí wọ́n ń sọ èdè náà ní orílẹ̀ èdè bíi Cote d’Ivoire Ghana, Togo, Benin, Burkina Faso àti Nigeria. Ó tó èèyàn bíi mílíọ̀nù márùn-ún ati àbàbọ̀ tí wọ́n ń sọ èdè yìí gẹ́gẹ́ bí Manessy 91978) ti ṣe ìwádìí rẹ̀. Fig 2.8. Nínú àtẹ yìí a rí ‘Proto Gur’. Ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ó pín sí:- Ààrin gbùngbùn Proto; Kulango àti Loron (Proto-Gur); Viemo, Tyefo, Wara-Natioro, Baatonum, Win (Toussian). Ààrin gbùngbùn Proto: eléyìí tún wà pín sí ìsọ̀rí meji pere: Àríwá àti Gúúsù. Lábẹ́ àríwá, a rí : Kurumfe, Bwamu Buli-Konni, Ìlà-oòrùn Oti-Volta, Iwọ̀-oòrùn Oti Volta, Gurma, Yom-Nawdm. Lábẹ́ gúúsù, a rí: Lobi àti Dyan, Kirma àti Tyurama, Ìwọ̀-oòrùn Gurunsi, ààrin gbùngbùn Guruusì àti Ìlà-oòrùn Guruusi, Dogose àti Gan.


ADAMAWA-UBANGI Èdè tí ó gbòòrò ni èdè Adamawa-Ubangi. Ipẹ̀ka rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ láti apá Gúsù-Ìwọ̀ oòrùn Nàìjíríà títí dé Àríwá-Ìwọ̀ oòrùn Sudan. Àpapọ̀ iye àwọn tí ó ń sọ èdè Adamawa tó mílíọ̀nù kan àti ààbọ̀-Crozier àti Blench (1992); Grimes (1996). Mílíọ̀nù méjì lé lẹ́gbẹ̀rún lọ́nà ọ̀ọ́dúnrún ni Barreteau àti monino (1978) tọ́ka sí gẹ́gẹ́ bí àwọn tó ń sọ èdè Ubangi. Èyí túmọ̀ sí pé àpapọ̀ àwọn tí ó ń sọ èdè Adamawa-Ubangi ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ jẹ́ mílíọ̀nù mẹ́rindín ní ẹgbàá lọ́nà ọgọ́rùn-ún láì ka àwọ̣n tí ó ń sọ èdè Sango mọ́ ọ. Fig 2.9. Nínú àtẹ yìí a rí ‘Proto-Adamawa-Ubangi’ tí ó pín sí ọ̀nà méjì ní ìbẹ̀rẹ̀ àpẹẹrẹ̀. (a) Adamawa (b) Ubangi Adamawa - eléyìí tún pín sí àwọn àwọn ìsọ̀rí mìíràn bíi: Leko, Duru, Mumuye/Yendang ati Nimbari; Ubum, Bua, Kim, Day; Waja, Longuda, Jen, Bikwin, Yungur. Bákan náà ni a rí: Ba (Kwa), Kam, Fali. Ubangi - Gbaya; Banda, Ngbandi, Sere, Ngbaka àti Mba; Zande.

SOUTH VOLTA-CONGO Bennett ati Sterk (1977) pe ‘South Volta-Congo ni ààrin gbùngbùn àríwí Niger-Congo. Atọ́tọ́nu wáyé nípa yíyapa tí ó wá yé láàrin Kwa àti Benue Congo nítorí pé wọ́n sún mọ́ ara wọn pékípẹ́kí-Greenberg (1963). Pàápàá jùlọ yíyapa láàrin èdè kwa, Gbe àti Benue –Congo: Bennett àti Sterk (1977) àti síse àtúnṣe. Kranse (1895) ni ó ṣe ìfihàn orúkọ ‘Kwa’ fún ayé. Bíi mílíọ̀nù lọ́nà ogún ni Grimes (1996) fi yé wa wí pé ó ń sọ èdè náà. Greenbery (1963a) pín-in sí ìsọ̀rí mẹ́jọ, ó sì so àwọn èdè ààrin gbùngbùn Togo pọ mọ ìsọ̀rí tirẹ̀. Stewart 1994 ni o ṣe àgbékalẹ̀ àtẹ ìsàlẹ̀ yìí. Fig 2.10. Nínú àtẹ yìí a rí ‘Proto-Kwa’ tí ó pín sí ìsọ̀rí mẹ́fà ni ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀. Àwọn ìsọ̀rí náà nìwọ̀n yìí: (a) Ega, Avikan ati Alladian, Ajukru, Abidji, Abbey, Attie (b) Potou Tano (d) Ga ati Dangme (Proto-Kwa) (e) Na – Togo (ẹ) Ka – Togo (f) Gbe

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìsọ̀rí wọ̀nyí ni o tún jẹ́ àtúnpín sí ìsọ̀rí mìíran bí àpẹẹrẹ :- Potou-Tano, Na-Togo, Ka-Togo, Gbe. Potou-Tano: èléyìí pín sí Potou àti Tano.

Lábẹ Potou ni a ti rí Ebríe àti Mbatto 

Tano – eléyìí pín sí ìsọ̀rí mẹ́rin. (a) Krobu (b) Ìwọ̀-oòrùn Tano: Abure, Eotilé (d) Ààrin gbùngbùn Tano: Akan, Bia (Nzema-Ahanta) àti (Anyi, Banle, Anufo). (e) Guan – O tun pín si Gúúsù níbi ti a ti rí Efutu –Awutu ati Larten-Cherepong-Anum. Bákan náà ni Àríwá Guang. Na-Togo:- Ó pín sí Lelémi – Lefana, Akapatu-Lolobi, Likpe, Santrokofi; Logba (Na Togo); Basila, Adele. Ka-Togo ;- Ìsọ̀rí eléyìí pín sí Avatime, Nyangbo-Tafi; Kposo, Ahlo, Bowiri (Ka-Togo); Kebu, Animere. Gbe :- Lábẹ́ èyí ni a ti rí: Ewe ati Gen/Aja, Fon-Phla-Phera

BENUE CONGO Ẹ̀ka méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni èdè yìí ni: Ìwọ̀-oòrùn àti Ìlà oòrùn Benue-Congo. Àwọn orílẹ̀ èdè púpọ̀ ni ó ní àwọn èèyàn tí wọ́n ń sọ èdè yìí, ó sì sodo sí apá gúúsù ilẹ̀ Nigeria dáadáa. Bẹ́ẹ̀ náà ni ìlú bíi Cameroon, Congo, CAR, DRC, Tonzania, Uganda, Kenya, Mozambique, Angola, Rwanda, Burundi, Namibia, Zambia, Malawi, Zimbabwe, Gabon, Lesotho, Samalia àti àwọn èdè yìí kalẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí Grimes (1996) ṣe wádìí rẹ̀, èdè Yorùbá àti Igbo ni ó tóbi jùlọ nínú ẹ̀ka èdè tí a pè ní Benue-Congo, ìsọ̀rí ìwọ̀ oòrùn Benue-Congo ni ó sì pín àwọn èdè wọ̀nyí sí. Àtẹ náà nìyí. Fig 2.11. Nínú àtẹ yìí a rí ‘Proto-Benue-Congo’ ti o pín sí ìsọ̀rí meji pàtàkì.

(a) Ìwọ̀ oòrùn Benue Congo

(b) Ìlà oòrùn Benue Congo

Ìwọ̀ oòrùn Benue Congo:- Ó pín sí YEAI (Yoruboid, Edoid, Akokoid, Igboid); Akpes; Ayere-Ahan; NOI (Nupoid, Ọkọ, Idomoid). Ìlà oòrùn Benue Congo :- Ó pín sí ìsọ̀rí mẹ́ta pàtó.

(a) Àárín gbùngbùn orílẹ̀-èdè Nàìjíráà:- Ó pín sí: Kainji, Àríwá-Ìwọ̀ Plateane, Beromic, Àárín gbùngbùn Plateane, Ìlà-oòrùn Gúúsù Plateane, Tarok, Jukunoid.

(b) Ukaan

(d) Bantoid-Cross:- Lábẹ́ èyí ni Bantoid ti yapa. Nígbà tí a sì rí Cross River ní abẹ́ Bantoid-Cross. Láti ara Cross River ni Bandi ti wá yapa. Nígbà tí a wá rí Delta-Cross lábẹ́ Cross River.

Ní ìparí, ó fihàn gbangba wí pé èdè Niger-Congo tóbi tààrà àti wí pé orílẹ̀ èdè Áfíríkà ni ó pẹ̀ka sí ọ̀pọ̀ nínú àwọn èdè yìí ni ó gbalẹ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ ṣùgbọ́n a rí lára wọn tí ìgbà ti fẹ́rẹ̀ tan lórí wọn. Àwọn wọ̀nyí ni èdè mìíràn ti fẹ́ máa gba saa mọ lọwọ Àwọn ìdí bíi, òṣèlú, ogun, òlàjú àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ni ó sì ṣe okùnfà èyí. Ní pàtàkì jùlọ, gbogbo èdè yìí náà kọ́ ni àwọn Lámèyítọ́ èdè fi ohùn ṣe ọ̀kan lé lórí lábẹ́ ìsòrí tí wọ́n wa ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ‘ẹbí’ rẹ fi ojú hàn gbangba. Ní ìparí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀mọ̀wé ni wọ́n ti ṣe iṣẹ́ ìwádìí lórí rẹ̀ ṣùgbọ́n ààyè sì tún sí sílẹ̀ fún àwọn ìpẹ́ẹ̀rẹ̀ túlẹ̀ láti ṣe iṣẹ́ ìwádìí àti lámèyítọ́ lórí ẹ̀kà èdè Niger-Congo.