Nigeria Immigration Service

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Àdàkọ:Primary sources

Wọ́n ṣẹ̀dá àjọ Nigeria Immigration Service (NIS), àjọ aṣọ́bodè ìrìnkèrindò àwọn ènìyàn láti ara àjọ ọlọ́pàá, the Nigeria Police (NP) lóṣù kẹjọ, ọdún 1958. Ní ìbẹ̀rẹ̀, wọ́n ń pè wọ́n ní Immigration Department, Chief Federal Immigration Officer (CFIO) ni ó ń darí wọn nígbà náà.

Ìdásílẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n dá ẹ̀ka aṣọ́bodè ìrìnkèrindò àwọn ènìyàn, The Immigration Department sílẹ̀ pẹ̀lú òfin Act of Parliament (Cap 171, Laws of the Federation of Nigeria) lọ́jọ́ kìíní, lóṣù kẹjọ ọdún, 1963 lásìkò tí Alhaji Shehu Shagari jẹ́ Mínísítà Iṣẹ́ Abẹ́lé, Minister of Interior, tí wọ́n ń pè ní Ministry Of Internal Affairs lásìkò náà.

Ní ìbẹ̀rẹ̀, òfin tí ó ń darí iṣẹ́ àjọ aṣọ́bodè ìrìnkèrindò àwọn ènìyàn ni òfin Immigration Act ti ọdún 1963 tí wọ́n ṣàtúnṣe sí lọ́dún 2014 àti 2015 (Immigration Act, 2015).

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìyípadà àti àtúnṣe ló ti dé bá àjọ aṣọ́bodè ìrìnkèrindò àwọn ènìyàn láti ọdún 1963 tí wọ́n ti dá a sílẹ̀ títí di àkókò yìí tí ó fi bá ìṣe ìgbàlódé mú bí i tọjọ́ òní.

Oríṣiríṣi ìyípadà ni ó ti dé bá àjọ NIS, pàápàá jù lọ nípa lílo ìmọ̀ ẹ́rọ ìbára-ẹnisọ̀rọ̀ òde òní. Púpọ̀ nínú àwọn iṣẹ́ àti àwọn ìlànà wọn ní wọ́n tí ń fi ìmọ̀-ẹ́rọ ìgbàlódé ṣe. Lára wọn ni:

  • lílọ ìmọ̀ ẹ̀rọ láti ka ìwé-ìrìnnà, (Traveling Passport) lọ́dún 2007
  • Bíbẹ̀rẹ̀ sí ní lo ẹ̀rọ
  • Ṣíṣẹ̀dá pẹpẹ ayélujára ti àjọ náà (www.immigration.gov.ng) àti (portal.immigration.gov.ng)
  • Ṣíṣẹ̀dá Global Passport intervention pẹ̀lú ìlànà ètò Ìjọba-Àpapọ̀ lórí jíjẹ́ ọmọ-ìlú, (Federal Government Policy on Citizenship Diplomacy)
  • Ṣíṣẹ̀dá ilé-ìwádìí ìgbàlódé (Forensic laboratory services) fún ìwádìí àwọn ìwé ìrìnnà àti àwọn irinṣẹ́ ìnáwó.
  • Ṣíṣẹ̀dá ìwé àṣẹ ìgbélùú (Combined Expatriate Residence Permit and Aliens Card) (CERPAC)

Lábẹ́ ìlànà abala kejì ti òfin tí ó gbé òfin àjọ aṣọ́bodè ìrìnkèrindò àwọn ènìyàn ró, a ró àjọ yìí lágbára láti ṣe àwọn iṣẹ́ wọ̀nyí:

  • Dídarí ìrìnkèrindò àwọn ènìyàn tí wọ́n ń wọlé-jáde sí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà
  • Pípèsè àwọn ìwé ìrìnnà fún àwọn ojúlówó ọmọ Nigeria nílé lóko.
  • Pípèsè ìwé-àṣẹ ìgbélùú fún àwọn àrè tí wọ́n bá wá sí Nàìjíríà
  • Ẹ̀ṣọ́ ẹnu-ibodè.
  • Gbígbófinró àti ìlànà ró àti
  • Ṣíṣe àwọn iṣẹ́ agbofinro ní Nigeria àti ní àwọn orílẹ̀ èdè mìíràn tí òfin là kalẹ̀ fún wọn.

Àwọn adarí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, àwọn wọ̀nyí ni wọ́n tí dárí àjọ Nigeria Immigration Service:

  • E. H. Harrison, Esq (Chief Federal Immigration Officer) láti 1962 - 1966
  • J. E. Onugogu, Esq (Chief Federal Immigration Officer) láti 1966 - 1967
  • Alayedeino, Esq (Chief Federal Immigration Officer) láti 1967 - 1976
  • Alhaji Aliyu Muhammed (Director of Immigration) lati 1977 - 1979
  • Alhaji Lawal Sambo (Director of Immigration) lati 1979 -1985
  • Muhammed Damulak, Esq (Director of Immigration) láti 1985 - 1990
  • Alhaji Garba Abbas (last Director of Immigration, 1st Comptroller-General Immigration Service - CGIS) láti 1990 - 1995
  • Alhaji Sahabi Abubakar (Comptroller-General Immigration Service - CGIS) lati 1995 - 1999
  • Alhaji U. K. Umar (Acting Comptroller-General Immigration Service - Ag. CGIS) àti 1999 - 2000
  • Lady U. C. Nwizu (Comptroller-General Immigration Service - CGIS) láti 2000 - 2004
  • Mr. Chukwurah Joseph Udeh (Comptroller-General Immigration Service - CGIS) láti 2005 - 2010
  • Mrs. Rose Chinyere Uzoma (Comptroller-General Immigration Service - CGIS) láti 2010 - 2013
  • Rilwan Bala Musa, mni (Acting Comptroller-General Immigration Service - Ag. CGIS) 2013
  • David Shikfu Parradang, mni (Comptroller-General Immigration Service - CGIS) láti 2013 - 2015
  • Martin Kure Abeshi (Comptroller-General Immigration Service - CGIS) from 2015 - 2016
  • Muhammed Babandede, MFR (Comptroller-General Immigration Service - CGIS) láti 2016 - 2021
  • Idris Isah Jere , Acting (Comptroller-General Immigration Service - CGIS) láti 2021 to Date

[1] [2] [3] [4]

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Immigration Act, 2015
  2. About the Nigeria Immigration Service http://immigration.gov.ng/index.php?id=3
  3. About the Nigeria Immigration Service http://portal.immigration.gov.ng/pages/about Archived 2019-04-18 at the Wayback Machine.
  4. "Jere of NIS Pledges to Consolidates on Gain at Nigeria Immigration Service". 16 September 2021.