Nike Adeyemi

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Nike Adeyemi
Ọjọ́ìbíOṣù Kẹrin 11, 1967 (1967-04-11) (ọmọ ọdún 57)
Nàìjíríà
Orílẹ̀-èdèNàìjíríà
Iṣẹ́Olùṣọ́àgùtàn, òǹkòwé, olùtọ́ní nípa ayé gbígbé.
Olólùfẹ́Sam Adeyemi
Àwọn ọmọDavid Adeyemi, Sophie Adeyemi, Adora Adeyemi
Parent(s)Ọ̀jọ̀gbọ́n Gabriel Ogunmola àti Ọmọọba Aderonke Ogunmola
Websitehttps.//www.nikeadeyemi.com/

Nike Adeyemi, wọ́n bi ní ọjọ́ kọkànlá oṣù kẹ̀rin, ọdún 1967. Ó jẹ́ òǹkòwé ilẹ̀ Nàìjíríà, òjíṣẹ́ Ọlọ́run, olùkọ́ni nípa ilé-ayé gbígbé, igbákejì olùṣọ́àgùntàn, àti ọ̀kan lára àwọn olùdásílẹ̀ ìjọ Daystar Christian Centre. Òun náà ni olùdarí Real Woman International, àti aya olùṣọ́àgùtàn Sam Adeyemi, olùdarí gbogbogbò ìjọ Daystar Christian Centre.

Ọ̀jọ̀gbọ́n Gabriel Ogunmola ni bàbá Nike Adeyemi, bàbá rẹ̀ jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n Nàìjíríá nínú ìmọ̀ Kẹ́mísítírì, àti olórí ilé-ẹ̀kọ́ gíga ti Lead City University, Ìbàdàn.[1]

Ìwé-kíkà[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Nike Adeyemi kàwé gboyè àkọ́ọ́gbà ti fásitì, àti oyè másítá lẹ́sẹsẹ nínú yíya-àwòrán-àti-fífún-ilé-tí-a-fẹ́-kọ́-lẹ́wà ní fásitì Ifẹ̀ tí a mọ̀ sí Yunifásítì Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ ní òní. Adeyemi tún gba MBA láti Business Srudies Netherlands, ó tún túbọ̀ ní ìmọ̀ nípa níní ìrísí elétò fún ṣíṣàkóso aláìlérènínú ní Havard Buisness School, ọ̀kan lára àjọ alákóso àti àwọn aṣèwádìí ilẹ̀ Nàìjíríà ni Nike Adeyemi jẹ́, ó tún jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àjọ òṣìṣẹ́ àwùjọ ilẹ̀ Nàìjíríà, abbl.[2]

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Naija, TheFamous (2022-05-02). "Nike Adeyemi Biography, Pictures, Age, Husband, Net Worth, State, Siblings". TheFamousNaija. Retrieved 2022-05-23. 
  2. Naija, TheFamous (2022-05-02). "Nike Adeyemi Biography, Pictures, Age, Husband, Net Worth, State, Siblings". TheFamousNaija. Retrieved 2022-05-23.