Jump to content

Nkiru Okosieme

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Nkiru Okosieme
Personal information
OrúkọNkiru Doris Okosieme
Ọjọ́ ìbí1 Oṣù Kẹta 1972 (1972-03-01) (ọmọ ọdún 52)
Ibi ọjọ́ibíNàìjíríà
Ìga1.67m
Playing positionAgbábọ́ọ̀lù agbede-méjì pápá eré-bọ́ọ̀lù
Senior career*
YearsTeamApps(Gls)
S.C. Imo State
Rivers Angels F.C.
2000–2005Charlotte Lady Eagles
National team
1991–2003Nigeria women's national football team
* Senior club appearances and goals counted for the domestic league only. † Appearances (Goals).

Nkiru Doris ''NK'' Okosieme (tí wọ́n bí ní ọjọ́ kínní oṣù kẹ̀ta 1972) ti jẹ́ adarí egbẹ́ bọ́ọ̀lù-afẹsẹ̀gbá àwọn obìnrin ti Nàìjíríà (Super Falcons) tẹ́lè rí, ó sì tún ti gbá agbede méjì pápá-bọ́ọ̀lù fún egbẹ́ agbábọ́ọ̀lù gbogbo àwọn obìnrin Nàìjíríà tí ó ti hàn nínú ìdíje bọ́ọ̀lù àwọn obìnrin ti gbogbo àwọn ìlú àgbááyé ní ẹ̀mẹẹ̀rìn (1991, 1995, 1999 àti 2003). àti orísiríṣi ìdíje bọ́ọ̀lù-afẹsègbá àwọn obìnrin ilẹ̀ Áfríkà pẹ̀lú ìdíje àwọn eré-ìdárayá ìgbà-òòrùn ti ọdọdún mẹ́rinmẹ́rin.[1] Wọ́n fún Okosieme ní orúkọ ìnagijẹ ''Olóri-obìnrin'' fún ìṣe rẹ̀ láti ma rí àwọn góòlù tí ó ṣe pàtàkì pẹ̀lú orí rẹ̀.[2]

Iṣẹ́ Àyanṣe rẹ̀.

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Okosieme jẹ́ adarí Nàìjíríà ní eré àkọ́kọ́ tí wọ́n gbá ní ìdíje bọ́ọ̀lù àwọn obìnrin ti gbogbo àwọn ìlú àgbááyé ti ọdún1991 nígbà yìí, ó ṣì jẹ́ ọ̀dọ́ kékeré. Ó gbá gbogbo ìṣéjú 90 tí ó sọ wọ́n di olùborí nínú àwọn eré mẹ́ta, ìyẹn, ìgbà tó ṣì wà pẹ̀lú ẹgbẹ́ S.C Imo.[3]

NÍ ìdíje bọ́ọ̀lù àwọn obìnrin ti gbogbo àwọn ìlú àgbááyé ti 1999, Okosieme ń gbá bọ́ọ̀lù fún Rivers Angels.[4] Kí ifigbagbága náà tó bẹ̀rẹ̀ ó sọ pé: ''A ò kì í ṣe ẹni tí ẹ lè fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn mọ́''.[5] O gbá góòlù mẹ́ta nínú ẹ̀mẹẹ̀rin tí wọ́n gbá bọ́ọ̀lù ní ọdún náà títí Nàìjíríà fi kan ẹgbẹ́ mẹ́ẹ̀rin sí ìparí, kí wọ́n tó pàdánù 4-3 fún Brasil. Okosieme gbádùn gbígbá bọ́ọ̀lù ní Amẹ́ríkà tó jẹ́ pé ó dara pọ̀ mọ́ ẹgbé-bọ́ọ̀lù USL W-League àti Charlotte Lady Eagles ó sìdara pọ̀ mọ́ ilé-ẹkọ́ gíga, níb i tí ó ti ń gbá bọ́ọ̀lù-afisẹ̀gbá ti fásiti.[6] Ẹgbẹ́ agbá bọ́ọ̀lù obìnrin tí ó dára jù lọ nígbà náà ni W-league jẹ́ ní gbogbo U.S. Ní 2001, ''NK'' jẹ́ ẹni kejì tó ní góòlù jù ní NCAA Div II. Ó ti gba agbábọ́ọ̀lù tó dára jù Peach Belt Conference ti ọdún kan rí, àti ti ẹgbẹ́ All-Regional fún ọdún mẹ́rìn. Ó tún fìgbà kan rí jẹ́ NSCAA All-American.

Okosieme ti yege nínú ìdíje bọ́ọ̀lù-afẹsègbá àwọn obìnrin ilẹ̀ Áfríkà pẹ̀lú àwọn akẹgbé rẹ̀ ''Super Falcons'' ní ìgbà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí ń se 1998, 2000, àti 2002.

Arákùnrin Okesieme jẹ́ Ndubuisi Okosieme tí ń ṣe agbábọ́ọ̀lù ilẹ̀-òkèrè.[7]


Àwọn Ìtọ́kasi

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. FIFA.com[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]Àdàkọ:Cbignore
  2. Sadjere, Clement (12 January 2011). "Top 4 Female Nigerian Footballers and Their Nicknames". E-Zine Articles. 
  3. "FIFA Women's World Cup China '91 – Technical Report & Statistics" (PDF). FIFA. p. 82. Archived from the original (PDF) on 27 December 2011. Retrieved 19 June 2016.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  4. "OKOSIEME Nkiru". FIFA. Archived from the original on 10 February 2001. Retrieved 19 June 2016.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  5. "USA 1999: Nigeria". SoccerTimes.com. Archived from the original on 14 March 2016. https://web.archive.org/web/20160314093830/http://www.soccertimes.com/worldcup/1999/capsules/nigeria.htm. 
  6. Jones, Grahame (12 October 2003). "U.S. Is a Shoe-in for Bronze". Los Angeles Times. http://articles.latimes.com/2003/oct/12/sports/sp-wwcthirdplace12/2. 
  7. Otitoju, Babajide (22 April 2002). "Ndubuisi Okosieme: Abuja's Garincha". allAfrica.com. Archived from the original on 24 January 2003. Retrieved 19 June 2016.