Nollywood Reinvented tàbí ìsọdọ̀tun (isodotun Nollywood)

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Jump to navigation Jump to search
Nollywood Reinvented
Nollywood reinvented logo.png
URLnollywoodreinvented.com
Commercial?Yes
Type of siteFilm review and forum
RegistrationOptional
Launched22 January 2011
Current statusOnline

 Ìsọdọ̀tun Nollywood tàbí Nollywood Reinvented, tí a tún mọ̀ sí NR,   jẹ́ pèpéle ẹ̀rọ ayélujára t́i wọ́n dá sílè ní ọdún 2011, pèpéle yí wà fụ́n ìṣàgbéyẹ̀wò  àwọn fiímù àti sinimá ọlọ́kan ò jọ̀kan.[1]  ó  tún fúni níròó nípa àwọn fíímù, àwọn òṣèré, àti àwọn ènìyàn míiràn pẹ̀lú. Òun ni irú rẹ̀ àkọ́kọ́ tí yóò kọ́kọ́ bẹ̀ṛ̀ẹ̀ ifúfẹ́ iṣ́ẹ́ ̣àgbéyẹ̀wò yìí nípa  Nollywood. Iṣẹ́ àgbéyẹ̀wò méjì ni pèpéle yìí ń ṣe, àwọn ni:: * Ṣíṣàgbéyẹ̀wò Sinimá . * Ṣíṣàgbéyẹ̀wò fiímù Àgbéléwò. Bákan náà ni ó tún ń ṣe àgbéyẹ̀wò Ètò orí amóhùnmáwòrán àti ipò tí wọ́n wà..[2]

Ìtàn ìṣẹ̀dálè rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n dá pèpéle Nollywood Reinvented  kalẹ̀ ní ọjọ́ Kejìlélọ́gún oṣù Kínín, ọdún 2011.[3]  Wọ́n da sílẹ̀ lạ́ti lè mú ìdàgbàsókè bá sinimá ilẹ̀  Nàìjíríà  tí ọ́ wà ní orị́ ẹ̀rọ ayélujára, kí ó tún lè jẹ́ ìtọ́ka sí fún àwọn òǹwòran lápapò. Ó lé ní ọgọ́rùn òṣèré ilẹ̀ Nàìjíríà àti òṣèré ilẹ̀ Ghana tí pèpéle yí ti ṣàgbéyẹ̀wò gẹ́gẹ́ bí òṣèré. 

Pèpéle yí wà gẹ́gẹ́ bí atọ́ka nípa isagbeyewo ̣àti ipò àwọ́n òṣer̀é àti sinimá wọn wà fún àwọn olólùfẹ́ wọn, sísọ ipò yí náà tún dá lórí iṣẹ́ lámèyítọ́ nípa bí àwọn olólùfẹ́ eré sinimá Nollywood ṣe ń kópa nínú sísọ ipò tí oṣèré kan tàbị́ òmíràn, sinimá kan tàbí òmíràn wà lórí ayélujára. Bákan náà ni NR tún dúró gẹ́gẹ́ bí àká fún ìwádí àsìkò gẹ́gẹ́ bí: * Ìròyìn léréfèé àti *ìròyìn pípo eré náà pọ̀ nípa àwọn eré nollywood  fún àwọn òǹwòran wọn.

Àwọ̣́n Àmì Ẹ̣́yẹ NR[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Nollywood Reinvented má ń́ ṣe ìfilọ́ọ́lẹ̀ ayẹyẹ àmì ìdạ́́nilọ́lá tị́ wọ̣́n ma ń pè ní "NR Awards". Yínyan àwọn olùkópa sábà ma ń wáyẹ́ ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù Karùún tàbị́ Ìkẹfà tí ó sì jẹ́ wípé àwọn òǹwòran ni yóò yan àwọn enìyàn tàbí fí́ímù tí yóò kópa nínú ayẹyẹ àmì ẹ́yẹ náà tí ètò ìdìbò yí yóò sì tó oṣu mẹ́ta gbáko kí ó tó kásẹ̀ nílẹ̀. Lẹ́yìn èyí ni wọn yóò kéde àwọn tí yóò ḱopa ní osụ kejìlá ọdún.[4]

Ẹ tún le wo[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  • Rating site
  • YNaija
  • Awakening

Àwọn ìtọ́ka sí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn ìjásóde[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]