Jump to content

Nomsa Manaka

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Nomsa Manaka
Ọjọ́ìbí1962 (ọmọ ọdún 61–62)
Soweto, South Africa
Orílẹ̀-èdèSouth African
Iṣẹ́Dancer, choreographer, actress

Nomsa Kupi Manaka (tí a bí ní ọdún 1962) jẹ́ oníjó àti òṣèrébìnrin ọmọ orílẹ̀-èdè Gúúsu Áfríkà.

A bí Manaka ní ọdún 1962 ní Orlando, agbègbè Soweto ní ìlú Johannesburg. Lẹ́hìn tí ó ní àwọn ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ijó jíjó, òun náà maá n ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún àwọn elòmíràn ní ilé-ìṣeré Funda Center, èyítí ọkọ rẹ̀ tí n ṣe Matsemela Manaka dá sílẹ.[1] Ní ọdún 1989, ó kópa nínu eré kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Gorée. Eré náà dá lóri arábìnrin kan tí ó rin ìrìn-àjò lọ sí abúlé Gorée ní ibi tí ó ti pàdé ìyáàgbà kan tí ó n ṣe àlàyé fun nípa àjogúnbá rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi ọmọ ilẹ̀ Áfríkà.[2]

Ní ọdún 1991, Manaka dá ìwé ìròyìn kan sílẹ̀ tí ó wà fún ọ̀rọ̀ nípa ijó tí àkọ́lé rẹ̀ n ṣe Rainbow of Hope,[1] ó sì tún ṣẹ̀dá àwọn ijó tó fi mọ́ èyítí wọ́n jó nínu eré Daughter of Nebo ti ọdún 1993.[3] Níbi àwọn ijó tí ó ṣẹ̀dá, ó gbìyànjú láti ri wípé àwọn ijó náà ṣàfihàn àwọn àṣà ilẹ̀ Áfríkà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà ijó ti ìgbàlódé. Ó pàdánù ọkọ rẹ̀ ní ọdún 1998 nínu ìjàmbá ọkọ̀.[4]

Ní ọdún 2010, Manaka kópa nínu eré oníṣókí kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Exiled èyí tí Tiisetso Dladla ṣe adarí rẹ̀.[5] Ní àkókò àwọn ọdún 2010 sókè, ó n gbé pẹ̀lú akọrin Hugh Masekela, ẹnití ó ní àrùn jẹjẹrẹ. Òun fúnrarẹ̀ náà ti ṣe àyẹ̀wò ní ọdún 2016 tí wọ́n sì ti jẹ́ kí ó mọ̀ pé ó ní àrùn jẹjẹrẹ. Hugh Masekela pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ ní Oṣù Kíní Ọdún 2018, ṣùgbọ́n ara tirẹ̀ padà sípò lẹ́hìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ oṣú tí ó fi ní ìtọ́jú.[6] Ní àkókò ìtọ̀jù rẹ̀, Manaka ní ìròrí láti ṣètò eré ijó kan tí ó pè ní Dancing Out of Cancer láti fi wá owó fún àwọn tí ó ní àrùn jẹjẹrẹ.[7]

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. 1.0 1.1 pad Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; name "dico2013" defined multiple times with different content
  2. sí
  3. ìn
  4. pọ̀l
  5. ́ ti
  6. ó f

Àwọn ìtakùn Ìjásóde

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]