Noufissa Benchehida

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Noufissa Benchehida
Ọjọ́ìbíOṣù Kẹ̀wá 23, 1975 (1975-10-23) (ọmọ ọdún 48)
Orílẹ̀-èdèMoroccan
Iṣẹ́Actress
Ìgbà iṣẹ́2004-present

Noufissa Benchehida (tí wọ́n bí ní 23 Oṣù Kẹẹ̀wá Ọdún 1975) jẹ́ òṣèrébìnrin ọmọ orílẹ̀-èdè Mòrókò.

Ìsẹ̀mí rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bí Benchehida ní Mòrókò ní ọdún 1975. Ó fẹ́ràn eré sinimá láti ìgbà èwe rẹ̀.[1] Ó kẹ́kọ̀ọ́ ní ilé-ìwé Cours Florent tí ó wà ní ìlú Paris. Benchehida gba oyè-ẹ̀kọ́ nínu ìmọ́ eré-ìtàgé láti ilé-ẹ̀kọ́ gíga Conservatory of Casablanca,[2] bẹ́ẹ̀ ló sì tún lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ Ecole supérieure d'hôtellerie et de tourisme à Montpellier.[3]

Benchehida kó àkọ́kọ́ ipa fíìmù rẹ̀ ní ọdún 2004 nínu eré tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Syriana tí olùdarí rẹ̀ síì n ṣe Stephane Cagan.[4] Ó di gbajúmọ̀ lẹ́hìn tí ó kó ipa Zineb Hejjami gẹ́gẹ́ bi ọlọ́pàá nínu eré tẹlifíṣọ̀nù tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ El kadia ní ọdún 2006. Ó sọ di mímọ̀ wípé òun gbádùn kíkó ipa náà ṣùgbọ́n òun kò fẹ́ láti máa ṣe irúfẹ̀ ipa bẹ́ẹ̀ ní gbogbo ìgbà, àti pé òun fẹ́ láti kópa nínu àwọn eré oníjà.[5] Bákan náà ní ọdún 2006, ó kópa nínu eré tẹlifíṣọ̀nù tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Moulouk Attawaif. Ní ọdún 2011, Benchehida kó ipa olú-ẹ̀dá-ìtàn nínu eré Agadir Bombay, gẹ́gẹ́ bi obìnrin kan tí ó n ṣe àgbàwí fún àwọn obìnrin ẹgbẹ́ rẹ̀. Myriam Bakir ló darí eré náà.[6] Ní ọdún 2015, ó kópa nínu fíìmù Aida.

Ní ọdún 2016, Benchehida kópa nínu eré tí àkólẹ́ rẹ̀ jẹ́ A la recherche du pouvoir perdu ("Ṣíṣe àwárí agbára tí ó sọnù"), èyí tí Mohammed Ahed Bensouda darí. Iṣé takuntakun rẹ̀ nínu eré náà ló fun ńi àmì-ẹ̀yẹ ti Golden Sotigui níbi ayẹyẹ Sotigui Awards ti ọdún 2017.[7] Benchehida tún gba àmì-ẹ̀yẹ òṣèrébìnrin tí ó dára jùlọ níbi ayẹyẹ Panafrican Film and Television Festival of Ouagadougou.[8]

Benchehida maá n sọ èdè Faransé, èdè Lárúbáwá àti èdè Gẹ̀ẹ́sì.[9]

Àṣàyàn àwọn eré rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  • 2004 : Syriana
  • 2006 : El kadia (TV series)
  • 2006 : Moulouk Attawaif (TV series)
  • 2009 : Elle
  • 2010 : Scars (short film)
  • 2010 : Une heure en enfer (TV series)
  • 2011 : Agadir Bombay
  • 2013 : Beb El Fella - Le Cinemonde
  • 2013 : Appel Forcé
  • 2015 : Aida
  • 2016 : Massafat Mile Bihidayi
  • 2016 : A la recherche du pouvoir perdu
  • 2018 : Wala alik (TV series)
  • 2020 : Alopsy (short film)

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Zerrour, Leila. "Benchehida Noufissa : «Je ne suis pas seulement une femme flic»". Maghress (in French). Retrieved 7 November 2020. 
  2. "Noufissa Benchehida". Agenzia Isabella Gullo (in French). Retrieved 7 November 2020. 
  3. "Retour de Noufissa Benchida au cinéma : Rôle principal dans le film “Agadir-Bombay”". Liberation (in French). Retrieved 7 November 2020. 
  4. "Noufissa Benchehida". Agenzia Isabella Gullo (in French). Retrieved 7 November 2020. 
  5. Zerrour, Leila. "Benchehida Noufissa : «Je ne suis pas seulement une femme flic»". Maghress (in French). Retrieved 7 November 2020. 
  6. "Retour de Noufissa Benchida au cinéma : Rôle principal dans le film “Agadir-Bombay”". Liberation (in French). Retrieved 7 November 2020. 
  7. "Moroccan actress Noufissa Benchehida wins Golden Sotigui". Moroccan Ladies.com. 2017. Archived from the original on 17 November 2021. Retrieved 7 November 2020. 
  8. Grira, Mohamed (5 March 2017). "Fespaco 2017: L'Étalon d'or revient à Alain Gomis pour son film "Félicité"". Anadolu Agency (in French). Retrieved 7 November 2020. 
  9. "Noufissa Benchehida". Agenzia Isabella Gullo (in French). Retrieved 7 November 2020. 

Àwọn ìtakùn Ìjásóde[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]