Ojà Àgbáláta (Badagry Market)

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Ojà Àgbáláta (Badagry Market) ni ojà tí ó tóbi jùlo ní agbègbè ìlú Àgbádárìgì tàbí Badagry. Ojà yìí ni ó wà ní ìtòsí àwon ilé ìfowó-pamó UBA,Zenith àti ìfowó-pamó Union. Ojà yìí ni ó jé wípé àwon èyà Ègùn tí osé òòjó won jé isé oko síse, ení híhun, àgbon títà àti epo síse ni ó wópò tí ó n nájà náà.

Àwon ojà tí ó súnmó Àgbáláta[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Lára àwon ojà tí ó súnmó Àgbáláta ni ojà Àjárá, Verekete, àti ojà Hunto, ni ó tún súnmó ojà àgbáláta sùgbón ojà àgbáláta ni ó gbajúmò jùlo nítorí wípé orísirísi àwon ìlú ni ó wá n ná ojà náà,pàápàá jùlo àwon olójà láti orílè èdè Bènè má n wá láti ná ojà náà nítorí wípé omi òsà tí ó sàn wo orílè èdè Bènè tí ìlú Àgbádárìgì sì tún jé ààlà láàrí orílè èdè Bènè.[1]

Ojà Àgbáláta gégé bí ònà ìdàgbà-sókè[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ojà Àgbáláta gégé bí àyè ìpéjo pò kan láàrín àwon òpò èyà gégé bí èyà Yorùbá,Ìgbò, Hawúsá, àti àwon èyà míràn láti ìlú òkèrè ni ó ti mú òlàjú àti ìdàgbà-sókè bá ìlú Àgbádárìgì nípa ètò orò ajé,ilé, ilè, àti béè béè lo.[2]

Àgbékalè ètò ojà náà[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wón se àgbékalè ààtò ètò ojà náà pèlú ìbámu àtò ìlú nípa kíkó ìsò àwon olójà áso lótò, ìsò àwon eléran lótò, tàwon aláta lótò àti béè béè lo.[3][4]

Àwon ìtóka sí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Adepeju, Adenuga (2017-07-31). "Where to buy Okrika clothes in Lagos. • Connect Nigeria". Connect Nigeria. Archived from the original on 2018-01-21. Retrieved 2018-11-07. 
  2. Okopie, Fredrick (2018-04-16). "N18bn mall project unveiled in Badagry - Vanguard News Nigeria". Vanguard News Nigeria. Retrieved 2018-11-07. 
  3. "Driving Directions Map to 84, Badagry Market Road, Badagry Expressway, Badagry for Biz Id 520116". VConnect™. Archived from the original on 2020-08-15. Retrieved 2018-11-07. 
  4. "Economic Analysis of Frozen Chicken Marketing in Badagry Local Government Area of Lagos State, Nigeria". Welcome. Retrieved 2018-11-07.