Ojoma Ochai
Ojoma Ochai tí í ṣe ọmọ bíbí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà jẹ́ olùdarí Arts ti West Africa fún British Council. Ó ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ilé-iṣẹ́ àdáni àti ti ìjọba ní UK àti West Africa láti pèsè àwọn iṣẹ́ lóríṣiríṣi fún ìdàgbàsókè.[1][2]
Ìgbésí ayé àti ètò-èkó rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Iṣẹ́ Chemistry ni Ojoma kọ́kọ́ fẹ́ lọ kà nílé ìwé àmọ́ ó padà ṣe Arts. Ó gboyè Honours Diploma Network ní NIIT Abuja Centre ní ọdún 2004.Ní ọdún 2008, ó gba ìwé-ẹ̀rí Certificate Project Management ní APM, UK. Ó lọ sí DEVOS Institute of Arts Management, University of Maryland níbi tí ó ti gboyè Arts Management Fellowship Arts, Entertainment, àti Media Management ní ọdún 2015.[3]
Iṣẹ́ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Òun ni Arts and Administrative Assistant ní ìpínlẹ̀ Èkó ní ọdún 2006 wọ 2007.[4] Ó jẹ́ adarí connected Africa Arts Project ní Nàìjíríà ní ọdún 2007 wọ ọdún 2009. Ní ọdún 2009, ó jẹ olùdarí Diversity, Performance and Evaluation ní Nàìjíríà. Ó jẹ́ olùdarí Arts ní Nàìjíríà láti ọdún 2010 wọ 2017. Ó di olùdarí Arts ni West Africa lọ́dún 2017.[5][6]
Àwọn àmì-ẹ̀yẹ tí ó gbà
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ní ọdún 2014, ó gba àmì-ẹ̀yẹ "10 Most Powerful people, under 40" ní "Nigeria's arts and culture", a sì tún yàn - án fún "Young Person of the Year" fún "Future Awards Africa" ní ọdún 2010. Ní ọdún 2015, ó gba àmì-ẹ̀yẹ "100 Most Influential Nigerians", ó sì tún gba àmì-ẹ̀yẹ "100 most inspiring women in Nigeria" ní ọdún kan náà.[7]
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Ojoma Ochai". UNESCO. 2018-04-20. Retrieved 2020-04-30.
- ↑ "Meet Ojoma Ochai, Assistant Country Director, British Council • Connect Nigeria". Connect Nigeria. 2014-03-04. Retrieved 2020-04-30.[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
- ↑ "OJOMA OCHAI – Working Hard, Praying Hard & Delivering Exceptional Results". Woman.NG. 2015-06-24. Archived from the original on 2019-09-10. Retrieved 2020-04-30.
- ↑ "Board of Directors – Lagos Theatre Festival". Lagos Theatre Festival – Going out of bounds. Retrieved 2020-04-30.
- ↑ "Ojoma Ochai Archives - Nigeria and World News". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News. Retrieved 2020-04-30.[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
- ↑ "Cultural showcase: British Council Partner Filmhouse". British Council. 2014-07-25. Retrieved 2020-04-30.
- ↑ "LLA 50 leading ladies in corporate Nigeria - Nigeria and World News". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News. 2019-05-25. Retrieved 2020-04-30.