Olowe of ise
Olowe of Ise (Yoruba: Ọlọ́wẹ̀ ti Ìsẹ̀; c. 1873Àdàkọ:Spndc. 1938)[1][2] ní èrò àwọn òpìtàn iṣẹ́-ọnà tí wọ́n jẹ́ Òyìnbó àti àwọn olùgbàsílẹ̀ iṣẹ́-ọnà jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn tí ó ṣe pàtàkì jù ní sẹ́ntúrì 20 láàárín àwọn oníṣẹ́-ọnà ti àwọn ará Yorùbá tí ó jẹ́ Nàìjíríà òní, Áfíríkà .[3][4][5] Ó jẹ́ agbẹ́gilére igi a-gbẹ́-ère àti Ọ̀gá olùdásílẹ̀ nínú àrà ìṣelọ́ṣọ̀ọ́ Áfíríkà tí a mọ̀ sí ojú-ọnà.
Ọlọ̀wẹ̀, tí wọ́n mọ̀ láti ilẹ̀ sí Olowere, ni wón bí ní Efon-Alaiye, ìlú kan tí wọ́n mọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀gángán ibi àṣà ní ilẹ̀ Yorùbá, ṣùgbọ́n ó gbé púpọ̀ ayé rẹ̀ ní ìgboro Ise. Wọ́n gbà á láti ìbẹ̀rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ ní ààfin Ọba Arinjale, Oba ti Ise. Ó jẹ́ ọ̀rọ̀ àríyànjiyàn bóyá iṣẹ́ iṣẹ́-ọnà rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí i ọmọ ìkọ́ṣẹ́ tàbí ó dìde tààrà láti ẹ̀bùn rẹ̀ lásán. Òkìkí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí i agbẹ́gilére hàn láti bẹ̀rẹ̀ ní Ise lábẹ́ àtìlẹ́yìn Arinjale ṣáájú kí ó tó tàn ká apá ìlà-oòrùn ilẹ̀ Yorùbá. Wọ́n pé Olowe lọ sí Ilesa, Ikere, Akure, Idanre, Ogbagi àti àwọn ìlú Yorùbá mìíràn tí ó wà ní àárín máìlì ọgọ́ta (96.75 kilometers) láti ṣe àwọn ohun èlò ilé ńlá (gẹ́gẹ́ bí i àsè àti àgáraǹdì ) , ohun èlò ara àti ètùtù fún àwọn ìdílé olówó.
Ipò iyì Olowe gẹ́gẹ́ bí i oníṣẹ́-ọnà jẹ́ gbígbàsílẹ̀ láti ọwọ́ àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ nínú ewì alohùn Yorùbá tí a mọ̀ sí oríkì. Fún àpẹẹrẹ , èyí example tí ọ̀kan lára àwọn ìyàwó rẹ̀ kọ tí wọ́n gbàsílẹ̀ ní 1988.
- ↑ Christa Clarke; Rebecca Arkenberg (2006). The Art of Africa: A Resource for Educators. 1. Metropolitan Museum of Art (New York, N.Y.). ISBN 978-158-8391-902. https://books.google.com/books?id=6s6QN-rVWcIC&dq=Olowe+of+Ise+19th+century+artist+nigeria&pg=PA42.
- ↑ Fred S. Kleiner (2015). Gardner's Art through the Ages: Backpack Edition, Book F: Non-Western Art Since 1300. Cengage Learning. ISBN 978-1-305-5449-49. https://books.google.com/books?id=rofCBAAAQBAJ&dq=Olowe+of+Ise+19th+century+artist+nigeria&pg=PT122.
- ↑ http://www.nmafa.si.edu/exhibits/olowe/anon/anon2.htm National Museum of African Art, Smithsonian Institution exhibition of Olowe's art
- ↑ Art in World History, Mary Hollingsworth, 2003, Giunti, ISBN 88-09-03474-0
- ↑ Plundering Africa's Past, Roderick J. McIntosh & Peter Ridgeway Schmidt, 1996, Indiana University Press, ISBN 0-253-21054-2
Òkìkí òke-òkun
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ní 1924, wọ́n ṣe àfihàn iṣẹ́-ọnà Olowe ní òke-òkun fún ìgbà àkọ́kọ́ nígbà tí wọ́n yan àṣè olókè láti ààfin ọba ní Ikere fún pàfílíọ́nù Nàìjíríà ní British Empire Exhibition ní Wembley, London. Àwọn British Museum ra iṣẹ́-ọnà yìí lẹ́yìn náà .