Àkúrẹ́
Àkúrẹ́ | |
---|---|
Country | Nigeria |
Ipinle | Ipinle Ondo |
Akure je ilu ni Naijiria ati oluilu ipinle Ondo ni apa iwo oorun.
A kò le sọ pàtó ọdún tàbí àkókò tí wọn tẹ ìlú Àkúrẹ́ dó, ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí Arífálò (1991) ṣe wòye, ó ní Àkúrẹ́ fẹ́rẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìlú tí ó pẹ́ tí wọn ti tẹ̀dó ni ilẹ̀ Yorùbá
Akurẹ si je okan lara àwon ilu atijo ni ile yoruba.
(Arífálò 1991; o,1.2)
Ìtàn sọ fún wa pé, Aga, ẹni tí a tún wá mọ orúkọ rọ̀ bí Alákùnrẹ́ ni ó kọ́kọ́ tẹ ìlú Àkúrẹ́ dó. Orúkọ̀ bàbá rẹ̀ ni ìyàngèdè. Ìtàn sọ fún wa pé, Ẹ̀pé, ní ẹ̀bá ìlú Òǹdó ni ó kọ́kọ́ fi ṣe ibùgbé lẹ́yìn tí wọn kúrò ní Ilé-Ifẹ̀. Alákùnrẹ́ tẹ̀ síwájú láti dá ibùgbé tirẹ̀ ní. Ní àsìkò yìí, ohun ọ̀ṣọ́ ọwọ́ rẹ̀ tí á ń pè ní ‘Àkún’ gé. Ó pe ibẹ̀ ní ‘Àkún rẹ́’ nítorí ìtumọ̀ ‘gé’ ni ‘rẹ́’ ní èdè Àkúrẹ́. Eléyìí ni ó wá di ‘Àkúrẹ́’ títí dòní yìí. Alákùnrẹ́ sì jókòó gẹ́gẹ́ bí olórí ìlú. A kì í pè é ní ọba ní àsìkò yẹn bí kò ṣe ‘Ọmọlójù’. Ó lo ipò rẹ̀ bí olórí ìlú àti ọmọ Odùduwà ní ìlú Àkúrẹ́.
Ní àsìkò yìí ni àwọn ọmọ Odùduwà ń jẹ ọba káàkiri ilẹ̀ Yorùbá. A gbọ́ pé, Àjàpadá Aṣọdẹ́bọ̀yèdé tí o jẹ́ ọ̀kan qlára àwọn ọmọ Odùduwà kúrò ní ìlú Òṣú, ó sì dúró sí ìlú kan tí wọn ń pè ní ‘Òyè’nítòsí Ẹ̀fọ̀n-Alààyè. Rògbòdìyàn, Ìṣòro, ogun àti àìfọkànbalẹ̀ kọ lu ìgbé – ayé Àjàpadá pẹ̀lú ara ìlú ‘Òyè’ náà. Ó wá di dandan fún Àjàpadá láti kúrò ní ìlú ‘Òyè’fún ààbò. Òun àti àwọn alátìlẹ́yìn rẹ̀ dórí kọ ilẹ̀ àìmọ̀rí fún ibùgbé.
Àjàpadá gbáradì, ó kó àwọn ènìyàn rẹ̀, ó sì ṣe gẹ́gẹ́ bí akíkanjú àti ògbójú ọdẹ. wọ́n rìn títí tí wọn fi dé igbó Àkúrẹ́, ibí ni wọ́n ti bá wọn pa erin. Erin tí Àjàpadá pa fún àwọn ará ìlú Àkúrẹ́ fún àwọn ará ìlú ní ìwúrí àti ìbẹ̀rù, nítorí pé, ọdẹ tí ó bá pa erin jẹ́ ọdẹ abàmì àti akíkanjú ọdẹ. Àwọn ará ìlú Àkúrẹ́ wá gba Àjàpadà gẹ́gẹ́ bí akíkanjú ọdẹ tí yóò lè ní agbára láti gba ará ìlú rẹ̀ ní ọjọ́ mìíràn tí ogun tàbí ọ̀tẹ̀ bá dé. Àwọn ará ìlú Àkúrẹ́ fún Àjàpadá ní orúkọ ‘Aṣọdẹbóyèdé’.
Àjàpadá tí à ń pè ní Aṣọdẹbóyèdé wá ní iyì gidi tí àwọn ará ìlú sì fẹ́ràn rẹ gan-an. Àwọn ará ìlú wá gbé Àjàpadá ga ju Alákùnrẹ́ tí o kọ́kọ́ dé ìlú Àkúrẹ́ lọ. Alákùnrẹ́ náà ṣàkíyèsí pé, àwọn ará ìlú fẹ́ràn Àjàpadá ju òun lọ, ó wa dàbí ẹni pé wọ́n rí ‘ọkọ́ tuntun gbé àlòkù èṣí dànù’. Alákùnrẹ́ wá já ọwọ́ rẹ̀ nínú irọ́kẹ̀kẹ̀ àti akitiyan láti jẹ́ ọba fún ìlú Àkúrẹ́ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun gan-an ni ẹni kìíní tí ó kọ́kọ́ tẹ ìlú Àkúrẹ́ dó. Itàn sọ fún wa pé Alákùnrẹ́ fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ kúrò fún Àjàpadá Aṣọdẹbóyèdé.
Àjàpadá Aṣọdẹbóyèdé wá jẹ́ ọba ìlú Àkúrẹ́ kìíní, gbogbo ayé gbọ́, ọ̀run sì mọ̀. Iwádìí fi hàn wá pé, Àjàpadá yìí jẹ́ ọmọ Ẹkùn, Ẹkùn sì jẹ́ ọmọ Òdùduwà1. Òdùduwà tí ó jẹ́ bàba Ẹkùn ni ó tọ́jú Àjàpadá dàgbà nítorí Ẹkùn tètè kú. Àjàpadé jẹ́ ọmọ rere, ó sì fẹ́ràn láti máa ṣeré káàkiri ààfin Òdùduwà, àwọn ènìyàn a sì máa pè é ní ‘Àjàpadá Ọmọ Ẹkùn. A gbọ́ pé Odùduwà fún Àjàpadá ní ẹ̀wù oògùn kan tí wọn ń pè ní ‘Ẹ̀wù Ogele’ tí Òduduwà fúnra rẹ̀ fi ń ṣe ọdẹ, nígbà tí Àjàpadá pinnu láti dá ibùgbé tirẹ̀ ní.
1. Oríṣiríṣi èrò ni ó wà nípa orúkọ àti iye ọmọ Òdùduwà.
Wo: T. A. Ládélé a.y. Àkòjọpọ̀ Iwádìí Ìjìnlẹ̀ Àsà Yorùbá. Ibadan’, Macmillan Nigeria Publishers Ltd. 1986, o.i. 1-2.
Ohun méjì ni ó mú kí Òdùduwà ṣe èyí, èkínní ni ìwà akíkanjú tí Àjàpadá fi hàn nígbà tí o fi ‘Àjà’1 kékeré pa eku ẹdá nínú ilé àìlujú nígbà èwè rẹ. Èkejì ni ìfẹ́ tí Òdùduwà ní sí Ẹkùn tí ó jẹ́ bàbá fún Àjàpadá. Ẹkùn sì tètè kú, ‘Ọmọ́rẹ̀mílẹ́kún’ ni Àjàpadá jẹ́ sí Odùduwà.
Ẹ̀bùn ẹ̀wù yìí nìkan kò tẹ́ Àjàpadá lọ́rùn, ó bẹ Odùduwà fún àwọn ohun ọrọ̀ míràn, èyí wá jẹ́ kí Òdùduwà tún rob í baba Àjàpadá ti jẹ́, ó sì wọ ilé lọ, nígbà tí o máa jáde, ó jáde pẹ̀lú ẹwà iwà mímọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba. Ó gbé adé kan lọ́wọ́, ó súre fún Àjàpadá, ó sì sọ fún Àjàpadá pé, ‘mo fi adé yìí jì ọ́’ Mo fi adé jì ọ́, ni ó wá di ‘Déjì’tí o jẹ́ orúkọ oyè ọba ìlú Àkúrẹ́, gẹ́gẹ́ bí ẹni tí Òdùduwà fi adé jì2. Adé yìí jẹ ìtọ́kasí pé ọmọ ọba ni Àjàpadá.
1. Ohun èlò ọdẹ ti wọn fi irin ṣe ni o ń jẹ́ ‘Àjà’. Ibi náà ni orúkọ Àjàpadá tí ṣúyọ tí o túmọ̀ sí ‘A fi ajà pá ẹdá (Àjàpadá)
2. Èyí tí ó túmọ̀ sí pé, mo fi adé yìí fún ọ láéláé.
Àjàpadá ọmọ Ẹkùn Aṣọdẹbóyèdé, Déjì kìíní ní ìlú Àkúrẹ́ jẹ́ akínkanjú ògbójú ọdẹ ni gbogbo ìgbésì ayé rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ Weir (1934)1 ogójì ọba ni ó ti jẹ ní ìlú Àkúrẹ́ láti ìgbà tí ìtàn ti bẹ̀rẹ̀. Ọba mẹrìn sì ti jẹ lẹ́yìn àkókò tí Weir ṣe ìwádìí tirẹ̀. Àpapọ̀ ọba tí ó ti jẹ ní Àkúrẹ́ jẹ́ mẹ́rìnlélógójì2. À rí igbọ́ pé obìnrin méjì ni ó wà nínú wọn.3 Obìnrin kìínì ni Èyé – Aró ti ó jẹ ọba ní ọdún 1393 títí di ọdún 1419 A.D. Ohun tí o fà á tí oyè fi kan obìnrin yìí nip é, òun nìkan ni ifá rẹ fọ rere láàrin àwọn tí wọn dárúkọ fún ifá rẹ fọ rere láàrin àwọn tí wọn dárúkọ fún Ifá. Àwọn Àkúrẹ́ sì fẹ́ tẹ̀ lé ohun tí Ifá sọ nítorí pé wọn ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọba jẹ tí wọn kò pẹ lórí oyè. Ifá sọ pé obìnrin yìí yóò pẹ́ lórí oyè àti pé àsìkò rẹ̀ yóò tuba tùṣẹ. Obìnrin kejì tí ó jẹ ọba ní Èyémọhin, ó wà lórí oyè ni ọdún 1705 títí di ọdún 1735. A gbọ́ pé nígbà tí wọn tún dá ifá ní àsìkò yìí, ifá kò mú ọmọkùnrin ọmọ-ọba kọọkan, bí kò ṣe ọmọ-ọba-bìnrin yìí. Eléyìí ni ó mú kí àwọn ará Àkúrẹ́ fi ọmọ-ọba-bìnrin yìí jẹ ọba.
1. Wo: N.A. C. Weir 1934 Akurẹ District Intelligence Report. Filo 41, 30014 Nigerian National Archives Ìbàdàn.
2. Wo Àfikún ‘I’ fún orúkọ àwọn ọba tí ó ti jẹ ní ìlú Àkúrọ́.
Ọba Adéṣidá Afúnbíowó ni a gbọ́ pé, ó pẹ́ láyé jù gẹ́gẹ́ bí ọba ìlú Àkúrẹ́. Ó lo bí ọgọ́ta ọdún láyé (1897 -1957.) Àkíyèsí: A ko iṣẹ́ yìí láti inú àpilẹ̀kọ fún Oyè Ẹ́mè ti F.A Àjàkáyé
A.F Àjàkáyé (1998) ‘Ìlò Orin Láwùjọ Àkúrẹ́ Àpilẹ̀kọ fún Oyè Ẹ́meè, DALL, OAU, Ifẹ̀ Nigeria. Àṣamọ̀
Èròngbà iṣẹ́ yìí ni láti ṣe ìwádìí sí ohun tí àwọn ará Àkúrẹ́ máa ń lo orin fún ní àwùjọ wọn. Ó jẹ́ ọ̀nà láti ṣẹ̀dámọ̀ àwọn orin àwùjọ Àkúrẹ́, láti ṣàlàyé ìṣẹ̀ṣe àwọn orin wọn àti láti ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn kókó tí orin máa ń dá lé.
Ìlò orin ní àwùjọ Àkúrẹ́ tí iṣẹ́ ìwádìí yìí dá lé ni èròngbà láti sí ọ̀nà titun sílẹ̀ fún àtúpalẹ̀ lítíréṣọ̀ lọ́nà láti mú kí àwọn orin wọ̀nyí yé ni dáradára. Ó tún jẹ́ ọ̀nà láti ṣí ọ̀nà titun sílẹ̀ fún ìwádìí lórí lítíréṣọ̀ alohùn pàápàá ti àwùjọ Àkúrẹ́ tí ó jẹ́ pé iṣẹ́ ìwádìí kò ì tí pọ̀ lórí rẹ̀.
À ṣe àkójọ-èdè-fáyẹ̀wò láti ọdọ̀ àwọn ọ̀kọrin. Apohùn ìṣẹ̀nbáyé àti àwọn abínà-ìmọ̀. A ṣe àdàkọ àwọn orin tí a gbà jọ, a sì ṣe àgbéyẹwò àwọn iṣẹ́ tí wọn ti wà nílẹ̀ lórí orin ní àwọn agbègbè mìíràn. A ka àwọn ìwá tí ọwọ́ wa tẹ̀ ní agbègbè náà, a sì rí ọ̀kọ́ tó wúlò fún wa lórí orí ọ̀rọ̀ tí iṣẹ́ wa yìí dá lé.
Iṣẹ́ ìwádìí yìí fi hàn pé àkọ́jinlẹ̀ orin nípa síṣe àtúpalẹ̀ kókó ohun tí à ń lo orin fún pọn dandan kí a tó le ní òye iṣẹ́ ọnà àti Ìtumọ̀ orin ní àpapọ̀.
Ìṣẹ́ yìí tún jẹ́ kí ń ní ìmọ̀ nípa ìtàn Ìṣẹ̀dálẹ̀, ẹ̀sìn àti ètò ìṣèlú àwọn ará Àkúrẹ́.
Iṣẹ́ yìí tún fi hàn pé ẹ̀sìn ní o máa ń bí àwọn orin ẹ̀sìn ní àwùjọ Àkúrẹ́ àti pé àṣà àti ìṣe àwùjọ ni ó máa ń ṣe okùnfà fún àwọn orin aláìjọmẹ́sìn.
Ojú Ìwé: Oókàn-dín-láàádọ́ọ̀sàn-án
Alámòjútó: Ọ̀mọ̀wé A. Akínyẹmí.
7°15′00″N 5°11′42″E / 7.25°N 5.195°E
Àyọkà yìí tàbí apá rẹ̀ únfẹ́ àtúnṣe sí. Ẹ le fẹ̀ jù báyìí lọ tàbí kí ẹ ṣàtúnṣe rẹ̀ lọ́nà tí yíò mu kúnrẹ́rẹ́. Ẹ ran Wikipedia lọ́wọ́ láti fẹ̀ẹ́ jù báyìí lọ. |