Àkúrẹ́

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Lọ sí: atọ́ka, àwárí
Àkúrẹ́
Àkúrẹ́ is located in Nigeria
Àkúrẹ́
Location in Nigeria
Àwọn ajọfọ̀nàkò: 7°15′0″N 5°11′42″E / 7.25°N 5.195°E / 7.25; 5.195
Country Flag of Nigeria.svg Nigeria
Ipinle Ipinle Ondo

Akure je ilu ni Naijiria ati oluilu ipinle Ondo ni apa iwo oorun.

A kò le so pàtó odún tàbí àkókò tí won te ìlú Àkúré dó, sùgbón gégé bí Arífálò (1991) se wòye, ó ní Àkúré férè jé òkan lára àwon ìlú tí ó pé tí won ti tèdó ni ilè Yorùbá

Akure is probably lone of the oldest towns in Yorubaland.

(Arífálò 1991; o,1.2)

Ìtàn so fún wa pé, Aga, eni tí a tún wá mo orúko rò bí Alákùnré ni ó kókó te ìlú Àkúré dó. Orúkò bàbá rè ni ìyàngèdè. Ìtàn so fún wa pé, Èpé, ní èbá ìlú Òndó ni ó kókó fi se ibùgbé léyìn tí won kúrò ní Ilé-Ifè. Alákùnré tè síwójú láti dá ibùgbé tirè ní. Ní àsìkò yìí, ohun òsó owó rè tí á ń pè ní ‘Àkún’ gé. Ó pe ibè ní ‘Àkún ré’ nítorí ìtumò ‘gé’ ni ‘ré’ ní èdè Àkúré. Eléyìí ni ó wá di ‘Àkúré’ títí dòní yìí. Alákùnré sì jókòó gégé bí olórí ìlú. A kì í pè é ní oba ní àsìkò yen bí kò se ‘Omolójù’. Ó lo ipò rè bí olórí ìlú àti omo Odùduwà ní ìlú Àkúré.

Ní àsìkò yìí ni àwon omo Odùduwà ń je oba káàkiri ilè Yorùbá. A gbó pé, Àjàpadá Asodébòyèdé tí o jé òkan lára àwon omo Odùduwà kúrò ní ìlú Òsú, ó sì dúró sí ìlú kan tí won ń pè ní ‘Òyè’nítòsí Èfòn-Alààyè. Rògbòdìyàn, Ìsòro, ogun àti àìfokànbalè ko lu ìgbé – ayé Àjàpadá pèlú ara ìlú ‘Òyè’ náà. Ó wá di dandan fún Àjàpadá láti kúrò ní ìlú ‘Òyè’fún ààbò. Òun àti àwon alátìléyìn rè dórí ko ilè àìmòrí fún ibùgbé.

Àjàpadá gbáradì, ó kó àwon ènìyàn rè, ó sì se gégé bí akíkanjú àti ògbójú ode. wón rìn títí tí won fi dé igbó Àkúré, ibí ni wón ti bá won pa erin. Erin tí Àjàpadá pa fún àwon ará ìlú Àkúré fún àwon aré ìlú ní ìwúrí àti ìbèrù, nítorí pé, ode tí ó bá pa erin jé ode abàmì àti akíkanjú ode. Àwon ará ìlú Àkúré wá gba Àjàpadà gégé bí akíkanjú ode tí yóò lè ní agbára láti gba ará ìlú rè ní ojó mìíràn tí ogun tàbí òtè bá dé. Àwon ará ìlú Àkúré fún Àjàpadá ní orúko ‘Asodebóyèdé’.

Àjàpadá tí à ń pè ní Asodebóyèdé wá ní iyì gidi tí àwon ará ìlú sì féràn re gan-an. Àwon ará ìlú wá gbé Àjàpadá ga ju Alákùnré tí o kókó dé ìlú Àkúré lo. Alákùnré náà sàkíyèsí pé, àwon ará ìlú féràn Àjàpadá ju òun lo, ó wa dàbí eni pé wón rí ‘okó tuntun gbé àlòkù èsí dànù’. Alákùnré wá já owó rè nínú irókèkè àti akitiyan láti jé oba fún ìlú Àkúré bí ó tilè jé pé òun gan-an ni eni kìíní tí ó kókó te ìlú Àkúré dó. Itàn so fún wa pé Alákùnré fi tòwòtòwò kúrò fún Àjàpadá Asodebóyèdé.

Àjàpadá Asodebóyèdé wá jé oba ìlú Àkúré kìíní, gbogbo ayé gbó, òrun sì mò. Iwádìí fi hàn wá pé, Àjàpadá yìí jé omo Ekùn, Ekùn sì jé omo Òdùduwà1. Òdùduwà tí ó jé bàba Ekùn ni ó tójú Àjàpadá dàgbà nítorí Ekùn tètè kú. Àjàpadé jé omo rere, ó sì féràn láti máa seré káàkiri ààfin Òdùduwà, àwon ènìyàn a sì máa pè é ní ‘Àjàpadá Omo Ekùn. A gbó pé Odùduwà fún Àjàpadá ní èwù oògùn kan tí won ń pè ní ‘Èwù Ogele’ tí Òduduwà fúnra rè fi ń se ode, nígbà tí Àjàpadá pinnu láti dá ibùgbé tirè ní.


1. Orísirísi èrò ni ó wà nípa orúko àti iye omo Òdùduwà. Wo: T. A. Ládélé a.y. Àkòjopò Iwádìí Ìjìnlè Àsà Yorùbá. Ibadan’, Macmillan Nigeria Publishers Ltd. 1986, o.i. 1-2. Ohun méjì ni ó mú kí Òdùduwà se èyí, èkínní ni ìwà akíkanjú tí Àjàpadá fi hàn nígbà tí o fi ‘Àjà’1 kékeré pa eku edá nínú ilé àìlujú nígbà èwè re. Èkejì ni ìfé tí Òdùduwà ní sí Ekùn tí ó jé bàbá fún Àjàpadá. Ekùn sì tètè kú, ‘Omórèmílékún’ ni Àjàpadá jé sí Odùduwà.

Èbùn èwù yìí nìkan kò té Àjàpadá lórùn, ó be Odùduwà fún àwon ohun orò míràn, èyí wá jé kí Òdùduwà tún rob í baba Àjàpadá ti jé, ó sì wo ilé lo, nígbà tí o máa jáde, ó jáde pèlú ewà iwà mímó rè gégé bí oba. Ó gbé adé kan lówó, ó súre fún Àjàpadá, ó sì so fún Àjàpadá pé, ‘mo fi adé yìí jì ó’ Mo fi adé jì ó, ni ó wá di ‘Déjì’tí o jé orúko oyè oba ìlú Àkúré, gégé bí eni tí Òdùduwà fi adé jì2. Adé yìí je ìtókasí pé omo oba ni Àjàpadá.

1. Ohun èlò ode ti won fi irin se ni o ń jé ‘Àjà’. Ibi náà ni orúko Àjàpadá tí súyo tí o túmò sí ‘A fi ajà pá edá (Àjàpadá)

2. Èyí tí ó túmò sí pé, mo fi adé yìí fún o láéláé.

Àjàpadá omo Ekùn Asodebóyèdé, Déjì kìíní ní ìlú Àkúré jé akínkanjú ògbójú ode ni gbogbo ìgbésì ayé rè. Gégé bí àkosílè Weir (1934)1 ogójì oba ni ó ti je ní ìlú Àkúré láti ìgbà tí ìtàn ti bèrè. Oba merìn sì ti je léyìn àkókò tí Weir se ìwádìí tirè. Àpapò oba tí ó ti je ní Àkúré jé mérìnlélógójì2. À rí igbó pé obìnrin méjì ni ó wà nínú won.3 Obìnrin kìínì ni Èyé – Aró ti ó je oba ní odún 1393 títí di odún 1419 A.D. Ohun tí o fà á tí oyè fi kan obìnrin yìí nip é, òun nìkan ni ifá re fo rere láàrin àwon tí won dárúko fún ifá re fo rere láàrin àwon tí won dárúko fún Ifá. Àwon Àkúré sì fé tè lé ohun tí Ifá so nítorí pé won ti fi òpòlopò oba je tí won kò pe lórí oyè. Ifá so pé obìnrin yìí yóò pé lórí oyè àti pé àsìkò rè yóò tuba tùse. Obìnrin kejì tí ó je oba ní Èyémohin, ó wà lórí oyè ni odún 1705 títí di odún 1735. A gbó pé nígbà tí won tún dá ifá ní àsìkò yìí, ifá kò mú omokùnrin omo-oba kookan, bí kò se omo-oba-bìnrin yìí. Eléyìí ni ó mú kí àwon ará Àkúré fi omo-oba-bìnrin yìí je oba.

1. Wo: N.A. C. Weir 1934 Akure District Intelligence Report. Filo 41, 30014 Nigerian National Archives Ìbàdàn.

2. Wo Àfikún ‘I’ fún orúko àwon oba tí ó ti je ní ìlú Àkúró.

Oba Adésidá Afúnbíowó ni a gbó pé, ó pé láyé jù gégé bí oba ìlú Àkúré. Ó lo bí ogóta odún láyé (1897 -1957.) Àkíyèsí: A ko isé yìí láti inú àpilèko fún Oyè Émè ti F.A Àjàkáyé


A.F Àjàkáyé (1998) ‘Ìlò Orin Láwùjo Àkúré Àpilèko fún Oyè Émeè, DALL, OAU, Ifè Nigeria. Àsamò

Èròngbà isé yìí ni láti se ìwádìí sí ohun tí àwon ará Àkúré máa ń lo orin fún ní àwùjo won. Ó jé ònà láti sèdámò àwon orin àwùjo Àkúré, láti sàlàyé ìsèse àwon orin won àti láti se àgbéyèwò àwon kókó tí orin máa ń dá lé.

Ìlò orin ní àwùjo Àkúré tí isé ìwádìí yìí dá lé ni èròngbà láti sí ònà titun sílè fún àtúpalè lítírésò lónà láti mú kí àwon orin wònyí yé ni dáradára. Ó tún jé ònà láti sí ònà titun sílè fún ìwádìí lórí lítírésò alohùn pàápàá ti àwùjo Àkúré tí ó jé pé isé ìwádìí kò ì tí pò lórí rè.

À se àkójo-èdè-fáyèwò láti odò àwon òkorin. Apohùn ìsènbáyé àti àwon abínà-ìmò. A se àdàko àwon orin tí a gbà jo, a sì se àgbéyewò àwon isé tí won ti wà nílè lórí orin ní àwon agbègbè mìíràn. A ka àwon ìwá tí owó wa tè ní agbègbè náà, a sì rí òkó tó wúlò fún wa lórí orí òrò tí isé wa yìí dá lé.

Isé ìwádìí yìí fi hàn pé àkójinlè orin nípa síse àtúpalè kókó ohun tí à ń lo orin fún pon dandan kí a tó le ní òye isé onà àti Ìtumò orin ní àpapò.

Ìsé yìí tún jé kí ń ní ìmò nípa ìtàn Ìsèdálè, èsìn àti ètò ìsèlú àwon ará Àkúré.

Isé yìí tún fi hàn pé èsìn ní o máa ń bí àwon orin èsìn ní àwùjo Àkúré àti pé àsà àti ìse àwùjo ni ó máa ń se okùnfà fún àwon orin aláìjomésìn.


Ojú Ìwé: Oókàn-dín-láàádóòsàn-án

Alámòjútó: Òmòwé A. Akínyemí.7°15′00″N 5°11′42″E / 7.25°N 5.195°E / 7.25; 5.195