Olumide Makanjuola
A bí Olumide Makanjuọla ní ọjọ́ keje oṣù kẹfà ọdún. Ó jẹ ọmọ bibi orilẹ-ede Naijiria, o si tun jẹ a ja fun ẹtọ ọmọniyan[1]. On s'ọtan ni[2], bakanna lo si je agbẹjọro fun agbekalẹ ti a n pe ni LGBTQI[3][4] ati gbajugbaja olokoowo. Oun ni oludari agba fun The Initiative for Equal rights (TIERS)[5], ile iṣẹ yii lo n ja fun iṣe deede ninu ẹtọ eniyan lawujọ ati pe lọwọlọwọ bayii, oun ni oludari eto fun Initiative Sankofa d’Afrique de l’Ouest (ISDAO) ti o je ile-iṣẹ ni agbegbe ti Faranse ni Afrika to ṣe aduroti fun awọn ẹgbẹ to n se agbatẹru ati atilẹyin fun awujọ ti ko ni iwa ipa ati irẹnijẹ laarin gbogbo awọn ara ilu, wọn ṣe eyi pẹlu iranlọwọ owo fun awọn irufẹ ile-iṣẹ bayii ni orilẹ-ede kọọkan[6][7].
Ni ọdun 2016, Makanjuọla gba ami ẹyẹ ọba'binrin fun awọn ọdọ to wa ni ipo aṣaaji (Queen’s Young Leaders Award) lori iṣẹ rẹ laarin LGBTI+[8] pẹlu awon agbegbe/adugbo, oun si ni o gba ami ẹyẹ fun ẹni ti o yẹ fun ọjọ ola ni ọdun 2012[9] ni ipo ẹni ti o le ṣe oniduro ti o da'nto (Future awards nominee in the best Use of Advocacy). Awọn iṣẹ ti Makanjuọla ṣe wọnyi ti fi ọpọlọpọ anfaani kun iṣẹ ẹtọ ọmọniyan ni orilẹ-ede Naijiria nipase LGBTIQ, a si ka a kun ẹni ti o bẹrẹ iṣẹ lori bi a ti le dẹkun ifẹtọ-ẹni dun ni nipasẹ LGBTIQ[10].
Ètò ẹ̀kọ́
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Makanjuọla kẹkọ gba imo nipa amojuto okoowo lati ile-ẹkọ imo nipa ijinlẹ nipa okoowo ni ipinlẹ Ogun, ni orilẹ-ede Naijiria, (Ogun state Institute of Technology). Ìmọ̀ nipa ete bi a ṣe le e sẹ amojuto lati Yunifasiti Anglia Ruskin (Strategic Project management at Anglia Ruskin University) ati ẹkọ ipilẹ nipa amojuto iṣe akanṣe lati Yunifasiti ti ilu ọba (introduction project management certificate at City University London)[11].
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ https://brittlepaper.com/2020/07/the-nigeria-prize-for-difference-and-diversity-announces-judges-and-advisory-council/
- ↑ https://therustintimes.com/tag/olumide-makanjuola/
- ↑ "Ẹda pamosi". Archived from the original on 2021-06-24. Retrieved 2021-09-02.
- ↑ https://businessday.ng/enterpreneur/article/business-must-think-beyond-profit-and-start-to-focus-on-people/
- ↑ https://www.pulse.ng/bi/lifestyle/olumide-makanjuola-a-nigerian-activist-shares-his-views-on-women-and-lgbti-rights-in/kt6qrfx
- ↑ "Ẹda pamosi". Archived from the original on 2021-07-08. Retrieved 2021-09-02.
- ↑ https://punchng.com/dont-do-good-things-just-for-accolades-olumide-makanjuola/[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
- ↑ https://www.queensyoungleaders.com/awardee/olumide-femi-makanjuola/
- ↑ https://ynaija.com/nominees-bowing-ministerial-screening-photos/
- ↑ https://www.bellanaija.com/2017/12/the-initiative-for-equal-rights/
- ↑ https://ynaija.com/standing-tide-olumide-makanjuola-making-world-safer-lgbts/