Opon Ifá

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Ọpọ́n Ifá Tí wọ́n ń pè ní (La Mesa de Ifá ní Látìnnì Amẹ́ríkà) jẹ́ àtẹ ìṣàyẹ̀wò nínú ìsẹ̀ṣe Adúláwọ̀ àti ẹ̀sìn àwọn ẹ̀yà Adúláwọ̀-Amẹ́ríkà, pàápàá jùlọ nínú Ifá àti ìsẹ̀ṣe Yorùbá. Babaláwo (oníyẹ̀míwò) ṣàmúlò ọpọ́n Ifá láti lè bá àwọn irúnmọlẹ̀ sọ̀rọ̀ tí wọ́n ó ṣàfihàn èrédìí àti ojútùú sí àdáni àti ìsòro àpapọ̀ àti mú ìdẹ̀rùn wá pẹ̀lú àwọn irúnmọlẹ̀. [1] Ọpọ́n máa ń tẹ́ pẹrẹsẹ tí ó sì máa ń sáábà jẹ́ roboto láàrin íṣí-ǹ-ìṣí mẹ́fà sí méjìdínlógún ní títóbi rẹ̀, pẹ̀lú àwòrán ère tàbí ọnà (àpéjúwe). Ọpọ́n Ifá tún lè jẹ́ onígun mẹ́rin tí kò dọ́gba, èyí tí kò rí roboto tán tàbí kí á sọ pé onígun mẹ́rin tí ó dọ́gba. Òkè àtẹ yìí ni orí tí ìsàlẹ̀ ọpọ́n náà jẹ́, ẹsẹ̀ tí ó súnmọ́ oníyẹ̀míwò jùlọ. Orí ọpọ́n ni àwòrán ère Èṣù máa ń wà, òjíṣẹ́ Ifá àti àwọn irúnmọlẹ̀ tókù. Àwọn àtẹ lè ní àlékún àwòrán ère Èṣù, a sì ti rí àtẹ tí ó ní ojú méjì, mẹ́rin, mẹ́jọ àti mẹ́rìndínlógún rí. Ní ibi tí ó bá ti wáyé báyìí owó ẹyọ ni a fi máa ń mọ orí ọpọ́n, owó ẹyọ yìí náà ni a fi máa ń tan ìyẹ̀ròsùn lójú ọpọ́n náà.[2] Nínú ọpọ́n, babaláwo á da ikin Ifá mẹ́rìndínlógún tàbí obì mẹ́rìndínlógún sí ibi pẹrẹsẹ igi yii, ó sì máa ń sọ mẹ́jọ tí yóò jáde nínú ọ̀tàlúgba-ó-dín-mẹ́rin ẹ̀yà odù tí ó lè fihàn. Àmì yìí ní orí tí wọ́n ṣe déédé ara tí wọ́n gbọ́dọ̀ kì, tí yóò sì wà ní ìbámu pẹ̀lú ìsòro ayé ẹni tí ó ṣe àyẹ̀wò. Nínú ọ̀pọ̀ ìsẹ̀ṣe ṣéènì àyẹ̀wò tí a mọ̀ sí ọ̀pẹ̀lẹ̀ ti rọ́pò ikin Ifá tàbí obì, tí a fi pamọ́ fún ìbéèrè tí ó ṣe kókó

Àwọn ìtọ́ka sí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "***Opon = Ifa Divination Board…". Chief Yagbe Awolowo Onilu. 2018-01-18. Retrieved 2018-11-26. 
  2. Pogoson, O. I.; Akande, A. O. (2011-10-01). "Ifa Divination Trays from Isale-Oyo". Cadernos de Estudos Africanos (21): 15–41. ISSN 1645-3794. http://journals.openedition.org/cea/196. Retrieved 2018-11-26.