Jump to content

Orúkọ Àdúgbò ní Ìjẹ̀bú-Igbó, Ìpínlẹ̀ Ògùn, Nàìjíríà

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Àdúgbò: Òkè Àgbìgbò – Òkè Àgbò Ìtumò: Ní ayé atijo, àdúgbò yìí wà nínú igbó kìjikìji, àwon eye àgbìgbò ni o sì pò si ibè. Àwon eye wònyí a máa fò káàkiri orí igi t’osan t’òru, bákan náà ni òkè pò sí àdúgbò ti a ń so nipa rè yìí. Ní ìgbà tì o se, àwon ènìyàn bèrè sì tèdó sí àdúgbò yìí, wón ń kó ilé mole síbè àwon eye wònyí kò fi àdúgbò náà sílè. Obinrin kan lára àwon ti ó kókó te ìlú náà dó ti orúko rè ń jé “Bèje” akíkanjú obìnrin ni, òun ni ó pa àwon eye àgbìgbò náà run. Wón sì so àdúgbò náà di oke àgbìgbò, ti wón wá ń pè ni “Òkè Àgbò” ni òde òní. Won sì máa ń ki àwon omo àdúgbò náà báyìí; “Omo òkè àgbò Bèje” ìdí ni wí pé Òun (Bèje) ni o pa gbogbo àwon eye àgbìgbò náà run.

2. Àdúgbò: Jàpara Ìtumò: Ní ìgbà láyéláyé ni ìlú Ìjèbú Igbó, ti wón bá ń jagun, ìbi ti ogun ti má a ń le ni won ń pè ni Jàpara, nitorí wí pé ni ibè ni wòn ti máa ń lérí mó ara won pé a o pa ara wa lónìí ni, won a sì jà titi won ó fi férè pa ara won tán. Ní gbà ti won wa bèrè sì te ibè dó, àwon àgbà wá so orúko àdúgbò ni “Jàpara” oríkì “Jàpara a kó obì se esà, a kérógbó bo ojú ogun. Ìjà ìpara – Jàpara”.

3. Àdúgbò: Itúndosà. Ìtumò: Àwon Yorùbá máa ń pe àdúgbò ní “itún nígbà míràn, àdúgbò ti won ń pè ni itún yìí wà ni Ìjèbú Igbo, se ni àwon ara àdúgbò dédé jí ni ojo kan, won rí i ti omi ti di odò nla sí apá kan itún won. Káwí káfò, àwon ara itún bèrè sì ni pa eja nínú odò náà. Báyìí ni wón so àdúgbò náà di “Itúndòsà”. Won a sì máa pe àwon ti won wá lati àdúgbò yìí ni “Omo Ìdósà maye”.

4. Àdúgbò: Igbáàìré – Igbáìre- Ìtumò: Àdúgbò yìí jé ibi ti igi igbá ti máa ń so, igi igbá pò sí àdúgbò yìí tó béè gee, ti awon eniyan sì máa ń seré lábé rè. Bí enikan báni àlejò ti ó wá a wá, won a ni kì won lo wòó ni abé igi igbá àìré- Ìgba ti won kò tii ré kúrò lórí Igi. Won wá so àdúgbò náà di Igbáìre.

5. Àdúgbò: Ojówò- Òjóò Ìtumò: Ibi ti ojó máa ń wò si ni won ń pè ni Ojó wò ti o wa di Òjóò loni yìí.

6. Àdúgbò: Itún alágbède-itúnlágbède Ìtumò: Itún ni èdè Ìjèbú je “Agbo ilé”. Ó sì jé ibi ti àwon alágbẹ̀dẹ pò sì, bí àwon enìyàn bá sì fé júwe àdúgbò lati agbo ilé yìí, won a ni e lo sí itún alágbède, tí ò sì di itúnlágbède di oni yìí.

7. Àdúgbò: Asìsgbìdì Ìtumò: Ní ayé àtijú won máa ń mo sìgìdì nú ni àdúgbò yìí, àwon ènìyàn ati àwon Ode, Babaláwo ati lébo lóògùn a máa be sìgìdì lówè fún isé ibi, a sì je isé náà fún won. Tí sìgìdì bá padà dé, won a sì se ètùtù, won a fún-un ni epo mu. Nítori ìdí èyí ni won se ń pe àwon ti won tèdó sí àdúgbò yìí ni

Omo Asìgìdì mode, Omo Mode ráàtà Omo atà je epo má pòn ón.

8. Àdúgbò: Imò alágbon-Imòàgbon-Imàgbon. Ìtumò: Ibi ti ìgi àgbon pò sí ni àdúgbò yìí, igi àgbon yìí pò to béè ti o fi je wí pe kò si ílé ti e kò tin i ríi. Béè sì ni imò wà lórí rè lópòlopò. Àwon eniyan Ìgbà náà sì ń pe ibè ni Imò àgbon, ti awon enìyan ode òní sì so ó di “Imàgbon”

9. Àdúgbò: Imòro Ìtumò: Àdúgbò yìí je ibi ti ìgi òro pò sí. Àwon ènìyàn a sì máa je òro yìí, Imó ni agbègbè ibi ti òro yìí ń so sí jìngbìnni. Àwon ènìyàn wá so àdúgbò náà di imó òro ìmòro ni won ń pe ibè lónì yìí. Oríki! “Imòro àláà, a rérun (enu) gé òrò bí òbe”

10 Àdúgbò: Òkè Erefòn Ìtumò: Ní ìgbà Ìwásè, Efòn ńlá kan wa ni Àdúgbò yìí ti o máa ń dààmú àwon ènìyàn ti won bá fe bojá lo sí oko. Odò nlá kan sì wà ni orí òkè ibì ti Efòn yìí máa ń lúgo sí. Bí àwon eniyàn ba ń darí bò lati oko won máa ń bu omi mu ninu odò yìí. Tí enikeni bá se ohun míràn yàtó sí mímu nínú omi náà, Efòn yóò fi imú onitòhún fon fèèrè. Sùgbón ti Efòn wáà bá ti rí wí pé won ń mu omi ni, kì yóò se ohunkóhun fun irú eni béè, won yóò sì la omu náà dúpé lówó Olódùmarè wí pé àwon gun òkè Efòn, ati wí pé omi ti àwon mu ninu odò ti re Efòn té lati má se ìjàmbá titi àwon fi gun òkè. Won wa so àdúgbò náà di òkè Odò re’fòn teti àgékúrú rè wá di “Òkè-erèfon”

11. Àdúgbò: Ládugbó Ìtumò: Ládugbó ni èdè Ìjèbú túmò sí ìkokò ni Yorùbá àjùmòlò. Ìtàn sò wí pé Odò ńlá kan wà ni àdúgbò yìí ti ìkòkò (ládugbó) àbáláyé kan wà nínú rè. Tí àwon enìyàn bá fé pon omi múmu, nínú Ládugbó yìí ni won ti máa ń pon-ón. Sùgbon bi o ba je ki a fo aso, ìwè ati ohun miran ni won a lo omi tí ó yí Ládigbó náà kà á. Nígbà ti o se won se àdúgbò náà di “Odò-o-Ládugbó” ti àgékúrú rè wá di Lágugbó.

12. Àdúgbò: Igà Eran Ìtumò: Ní ìgbà láyéláyé, Bàbá kan wà ti wón ń pè ni Òsígbadé Olómo òdo-nitori kò mo iye omo ti o bi, sùgbón ó jé onísòwò eran Màlúù. Ó ní àgbàlá ńlá ti ó máa ń da eran sí lati je pápá, kò si ohun òsìn míràn ti ó ń ba àwon màlúù náà gbé ni àgbàlá náà. Àgbàlá ńlá yìí ni àwon Ìjèbú máa ń pè ni Ugà eran ti o wa di “Igbà Eran’ lónìí

13. Àdúgbò: Ìdágòlu Ìtumò: Ní ayé àtijú won a máa sa ìgò jo sí àdúgbò yìí fún fífo lati tà á. Ìtán so wí pé èyìn odi ìlú ni ibè jé, wón tún máa ń da àwon àkúfó ìgò jo síbè, àwon tí ó bá jé odùndùn, won a fó won sí wéwé. Ìgbà tí ó se, àwon ènìyàn bèrè sí tèdó sì àdúgbò yìí. won wa ń pe ibè ní “Abúle Ìdágòlu” ti o wa di “idágòlu”lónìí

14. Àdúgbò: Ìdí Isin Ìtumò: Inú Igbó ni àdúgbò yìí jé nígbà àtijó, Igi ti o máa ń so èso isin ni ó pò nínú igbó yìí jù. Àwon eniyàn a máa sinmi labe àwon igi náà bí won bá ń ti ònà oko tàbí odò bò. Ìgbà tí ó se, ìgbó náà bèrè sí súnmó abúlé, nìtori àwon ènìyàn ń tèdó sí etí bè. Tí àwon àgbàlagbà ní abúlé pàápàá àwon Okùnrin bá jeun tan won a “tàtaré”sí abé igi yìí lati lo gba atégùn, ìbi ti wón bá ti ń tayò, tí won ń “tàkúrò so” won a wà níbè fún ìgbà pípé. Enikéni ti ò ba ni àlejò, won a ni kí ó lo wo eni ní ó ń bèèrè ni ìdí igi isin tí ó wa di “Ìdí Isin” lónìí.

15. Àdúgbò: Ìdí scale (síkéèlì) Ìtumò: Ní àdúgbò yìí, ìwòn tì àwon alágbède ro ni wón ń lò lati máa fi se òsù wòn kòkó. Gbogbo àwon onísòwò kòkó pátápátá ni won máa ń pàdé ni àdúgbò ti a ń so yìí lati wa rà ati ta kòkó won níbè. Ní ìdí èyí, won so ibè dí ìdí scale ti wón ti ń won kòkó, ti àgékúrú rè sì di “Ìdí scale” lónìí

16. Àdúgbò: Òkè sópen Ìtumò: Ní ìgbà atijo, àwon osó ati Àjé kò fi ìse won bò rárá, isé ibi won kò ni àfìwé, sùgbón àwon Àgbààgbà pinnu lati da sèríà fún enikeni ti owó won bá tè. Tí won bá mú enikeni ti o ni osó tabi Àjé ibi tì wón ti yàn sótò, ti won ti ń so òkò pa wón ni wón ń pè ní òkè ti osó pari emir è sí, tabí òkè tie mi osó pin sí. Èdè àdúgbò Ìjèbú ni “pen” – Yorùbá àjùmòlò ni “Pin” Nígbà ti ojú ńlà ti àwon enìyàn ń kólé sí bè won wa so àdúgbò náà dí “Orí òkè osópen”ti àgékúrú rè wá di “ÒKE SÓPEN”

17. Àdúgbò: Odò-Rámúuségun Ìtumò: Ìtàn so fún wa wí pé àdúgbò kan wà ti ogun máa ń jà wón lópòlopò, bí ogun bá sì ti wolé tò wón, won máa kó won lérú ni. Ní ìgbà ti o se àwon àgbaàgbà ti won kù ni ìlú náà fi orí kan orí won sì to “ifá” lo lati bèèrè ohun ti won tè se ti agbègbè àwon kò fin i parun lowo àwon ti o ń ko won lérú. Ifá ni kì won bo Odò ti o nà ni ìlú won, kì won sì máa pon omi Odò náà sí ilé, gbàrà tì won bá gbó wí pé ogun wòlú, ki oníkálukú bu omi náà mu. Láìpé Ogun miran wolé tò wón, wón se bi ifá ti wí, wón jagun won sì ségun. Wón wá ni odò ni awon fí ségun, ti ó wá di “Odò-rámúùségun”

18. Àdúgbò: Itún-Lógun Ìtumò: Itún ni èdè ìjèbú túmò sí “Agbólé”. Àwon jagunjagun ìlú ni ibi ti wón ti máa ń pàdé dira ogun ti won ba fe lo sí ojú ogun. Àkókò ti won bá fe lo jagun nikan ni won máa ń pàdé ni ibè. Tí àwon ènìyàn tì kò mo ohun ti o ń selè télè bá ti ń ri àwon jagunjagun ti won ń dé sí itún yìí, won a ni àwon Ológun ti dé sí itún won. Won wa so ibè di “itún Ológun” ti àgékúrú rè wa di “itún Lógun”.

19. Àdúgbò: Odò Asóyìn Ìtumò: Odò kan wà ni àdúgbò kan, ti èso Òyìn máa ń so repete ní bèbè rè. Àwon àgbàgbà a máa jókòó ta ayò ni abé àwon igi yìí, won a si máa fi èso òyìn panu bí ayò bá ń lo lówó. Báyìí ni wón so ibè di “Odò ti o ń so èso Òyìn” tí ó wá di “Odò asoyìn”.

20. Àdúgbò: Orímolúsì Ìtumò: Ní Ìgbà Ìwásè orúko àdúgbò ńlá kan ni ìjèbú Igbó ni “Orímolúsì”. Sùgbón, gégé bi a ti mò wí pé àwon Yorùbá máa ń ye ìpún tabi Àyàmó wò (ori). Àwon ènìyàn àdúgbò náà a da Obì won a wí pé “Orí ìwo lo mo Olùsìn, Olùserere, je kí ìgbésí ayé mi dára o. Báyìí ni eni ti o kókó je Oba ìlú náà wí pé òun ni Olórí ìlú, òun ni orí fún àwon ènìyàn ti o wà ni ìlú gbogbo ènìyàn yóò sì ma pe sin òun ni. Ní ìdí ènìyàn, won so Oba náà di “Orí-mo-Olùsìn” ti ó di “orímolúsì” lónìí.

21. Àdúgbò: Bógije Ìtumò: Ní ayé atijo okùnrin kan wà ti o kúrò ni àárin ìlú lati máa lo gbé inú Igbo nitori wí pé o ti ya wèrè, wèrè yìí pe lára rè to béè gè é ti o gbé òpòlopò odún nínú igbó náà. Ní ìgbà míràn ti kinní òhún bá wò ó lára tán, a bèrè sí yà èèpo igi a máa rún-un wòmùwòmù; Àwon èrò ti ó ń lo, tó ń bò lónà oko máa ń wòó tàánú-tàánú; nígbà tì o yá kò jo wón lójú mo. Wón wá ń pè é ni wèrè ti ó ń bó igi je, òun a sì máa le won bí wón bá ti pè é béè. Sùgbón nígbà tì àwon ènìyàn bèrè sí ko ilé ibè, won wa so ibè di àdúgbò wèrè tò ń bó igi je, àgékúrú rè wá di “bógije”


22. Àdúgbò: Òkè Idán Ìtumò: Àwon eléégún ati àwon abòrìsà ìlú máa ń se ayeye Odún won ni Odoodún ni ayé atiju. Orí Òkè ńlá kan ni won sì ti máa ń pa Idán Orísirísi fún àwon ara ìlú. Nígbà tì o se àwon ènìyàn kólé sí Orí Òkè yìí, won sí so àdúgbò náà di “Orí Òkè Idán pípa” tó wa di Òkè Idán” lónìí.

23. Àdúgbò: Iwáta Ìtumò: Ní ìgbà ti àwon ènìyàn bá je Oyè tan ní ìlú, àwon Ìjòyè a sì wá sí Iwájú ìta àafin Oba pèlú àwon ebí, ara ati òré won-lati wa jó, lati se àjoyò pèlú Olóyè tuntun. Nígbà ti ó so àwon ènìyàn féràn lati máa se ayeye orísirìsì ni iwájú ìta àafin Oba nitori pé enikeni ti o ba fe se ayeye ti Oba bat i gbó nipa rè ni yóò ri èbùn gbà lówó Oba. Báyìí ni won bèrè sì lo ìtà Oba fun ayeye, bí won ba sì fé se àpèjúwe ìbì ti won yóò ti se ayeye fun àwon ará, òré, ati ojúlùmò, won a ni kí wón wá bá won se ayeye ni iwájú ìta Oba. Níbo ni e o ti se ayeye? “iwáta Oba ni” kèrèkèrè wón so àdúgbò náà di “Iwátá”.

24. Àdúgbò: Òkè Ererú Ìtumò: Kí o tó dì wí pé a gba òmìnira, àdúgbò yìí ni wón ti máa ń ta erú, tì àwon ènìyàn sì ti máa ń ra àwon erú lo sí “Àgbádárìgì”. Nígbà ti ó se Ojà erú títà sá féré ni orí òkè yìí, àwon Olùtajà a sì wá so ibè di Òkè-Ererú

25. Àdúgbò: Òkè Tákò Ìtumò: Ní ìgbà àtijó, ti wón ba fe fi Oba je ni ìlú, àdígbò yìí ni won ti máa ń gbìmò eni ti Oba kan, lati ìdílé ti Oba kan. Tí ètò fífi Oba je yìí bá takókó ti o díjú tan pátá, àwon àgbààgbà afobaje á kó ara won lo si Ori Òkè kan lati lo tú gbogbo ohun ti o bá dìju palè. Ní orí òkè yìí won a dìbò, won a dá ifá, ohun gbogbo yóò sì ni ojútùú kì won tó padà sí ilé. Nitorí ìdí èyí ni wón se so òkè náà di “Òkè Tákò” Òkè ti a ti ń tú ohun lèrò ti ó ta kókó.

26. Àdúgbò: Òkè Àtààfíà Ìtumò: Léyìn Ìgbà ti àwon afobaje bá ti ri ojùtùú enì ti yóò joba, Okan won a balè, won a wá gun orí òkè kan lo lati lo gba atégùn sára, nìbe wón a mu emu, won a sì máa wí pé àlàáfíà ti dé bá ìlú. Orí òkè yìí ni o di àdúgbò ńlá lónì, ti won so di “Òkè àlààfíà”.

27. Àdúgbò: Òkè ìfé Ìtumò: Orí òkè kan wà ti àwon àlejò ti wón ba sèsè wo inú ìlú ti máa ń lo búra wí pé àwon kò ni se búburú sí Oba ati àwon omo onílùú Orisìrìsi àwon èyà enìyàn ni won máa ń pàdé ni orí oke yìí ni asìko ìbúra náà, Ègbá, ìbàdàn Òyó. Hausa, Ìgbò, abbl. Orò ajé ni ó gbe won wá sí ìlú náà (Ìjèbú Igbó). Ní gbà tí ó se Oba se akiyesi wí pé gbogbo àwon àlejò wònyí ń se bí omo ìyá kan náà, a fi bi eni pe ile kan ni gbogbo won ti wá. Láì fa òrò gùn, àwon àlejò yìí ń pò sí, won ń bí sí i, won ń rè sí, ìlú sì kún to béè géè tì onílé kò mo àlejò mó. Ní ojo kan, Ob ape gbogbo àwon àlejò ìlú jo tèbí tàráawon, Ó sì so fún won wí pé òun ríi pé won ni ìfé ara won, lati òní lo, òun (Oba) yàn-ǹ-da orí òkè tì wón tì bura ni ojósí fún won, ki won ko àwon enìyàn won ki wón lo tèdó sí ibè. Gbogbo àwon àlejò wònyí sì dupe lówó oba. Won sì se bi Oba ti wí. Lati Igba náà ni won ti so àdúgbò náà di orí òkè ìfé ti o di “Òkè Ìfé” loni yìí.

28. Àdúgbò: Atìkòrì Ìtumò: Ní ayé atijo, ìko tìí wón fi ń hun eni ni ó pò ni àdúgbò yìí. Bàbá kan wà ti o je ògbóǹtagí onísègùn; ìko ni o máa ń fi ríran sí àwon ènìyàn. ohun kohun ti ènìyàn bá bá lo si òdò rè ìko yìí ni ó máa kó kalè ti yóò sì máa ba sòrò bí ènìyàn; sùgbón ohun nìkan ni o máa ń gbo èdè tì ìko náà ń so, òun yóò wa túmò fún eni tí ó wa se àyèwò. Ní ìdí èyí, won so “Baba’yìí ni “Ati ìko ri ohun ti o ń sele si ènìyàn” ti o di “Atìkorí nigba ti awon ènìyàn tèdó si àdúgbò náà. Lónìí Atìkòrì ni àwon ènìyàn ń pè é.

29. Àdúgbò: Odòdóoróyè Ìtumò: Ní aye atijo, Okùnrin ken wà ni ìlú ó je alágbára atì alákíkanjú ènìyàn. Orúko rè ń jé “omódóríoyè” Ó se isé takun-takun fún ìlú Baba rè, ò sì jè omo Oba”. Ní ìgbà tì Oba tó wà lórí Oyè wàjà, Ìdílé rè ni Oba kàn òun sì ni o ye ki wón mú, nínú ìdílé náà. pàápàá tì o tún jé alágbára ènìyàn. Àwon afobaje gba àbètétè lowo elòmíràn won sì kojú “Omódoríòyè” sóòrù alé. Kàkà ki ilè kú, ilè á sá ni Omódérìoyè fi òrò náà se ati bi a se mò wí pé àwon alágbára kò kò Ikú Omodorioye se Okunrin, ò sì pinnu wí pé bí won kò tilè fi òun joba won kò ni gbàgbé òun láyéláyé. Báyìí ni “omódóríoyè tí àwon ènìyàn ti se àgékúrú orúko rè sí “Dóróyè” télè, di odò ńla kan sí odì ìlú náà, ó sì fi ohùn sílè wí pè, Oba tí ó ba je ti kò bá mu nínú omi náà kì ni pe lori oyè tí wón fi je, atì wí pé eníkéni tí ó bá ń mu omi náà yóò di alágbára. Bíí àwon ènìyàn se bèrè sí ni tèdó si eti odò náà ni yìí, ti won sí so àdúgbò náà ti “Odòdóoróyè” iyan nip e “Odò Omódórí oyè”.

30. Àdúgbò: Station (Sitésòn) Ìtumò: Léyìn Ìgbà ti awon Gèésì dé, ti Okò ayókélé ati irúfé okò mìran bèrè si won orile èdè wa, àwon Okò akérò tì o ba wo ìlú ìjèbú Igbó ni ibikan ti won ti gbódò ja awon èrò won sile, ti won yóò sì kó àwon èrò miran. Ibè ni won ń pè ni station, Ibikiri ti ènìyàn bá ń lo lati ìjèbú Igbó, Ibe nikan ni e ti lè ri oko wò.