Orúkọ Àdúgbò ní Ọ̀fà, Ìpínlẹ̀ Kwárà, Nàìjíríà

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Ofa

Ofà[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

1. Àdúgbo: Atan Oba Ìtumò: Agbègbè yìí ni àwon ìdílé Oba máa ń de ilè àti ìdòtí sí ni ayé atijo. Sùgbón ìgbà tí ó yá ni ilé bèrè sí ní dé àdúgbò yíí. Bí wón se ń pe àdúgbò yìí ní Atan Oba.


2. Àdúgbo: Aponbi Ìtumò: Ní àyé àtijó àwon ara àdúgbò yìí máa ń gun igi obì láti ká obì, nítorí wón gbà pé obì yìí máa ń mówó wólé. Èyí ni àwon ènìyàn rí tí wóm fi so àdúgbò yìí ní apónbì

3. Àdúgbo: funfunleye ńsu Ìtumò: Igi ń lá kán wà ni agbègbè yìí tí àwon eye lékeléke máa ń bà le. Gbogbo àwon ilé tí ó wà níbè ni àwon lékelékèé yìí máa ń yàgbé sí tí asogbo ara ilé náà á sì funfun. Sùgbón ìgbà tí olájú wá dí òfà ni wón kó àgó olópàá sí àdúgbò yíi. Tí wón bá ti wá fe júwe àgó olópàá yìí wón máa ń so wi pe àdúgbò funfun leye ń sun. Bí orúko yìí se mó won lára títí dóní nìyí.