Orúkọ Àdúgbò ní Ila, Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, Nàìjíríà

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Jump to navigation Jump to search

Ila

ILA[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ilé-Àwòrò-òsé: ìtàn ti a gbo nipa adugbo tabi agbo-ile yì so fun wa pe ilé. Àwòrò-òsé je ibi pàtàkì ti won ti ma n se orò, ò sì tun je ile-Olorisa.

Ìlé-Olúóde: A gbó pe ode ni ìran àwon wònyí n se láti ìgbà ìwásà. Ibe sì nì Olórí àwon ode n gbe.

Ile-Olutojokun: Àwon ìdílé yi ni o ma ń joba ni ìlú-ìlá-òràngún.

Ile-Olorirawo: Adugbo ati Agbo-ile ni eyi je. Ìtan ti a si gbo nipa won núpé ìbè ni Olori awon awo tedo sì.

Ìjímògòdò: Akoni èdá kan ni o je, jagunjagun sin i pelu, oun lo te àdúgbò yì dó.

Ìgbonnìbí: jé òkan nínú àwon oba akíkanjú ti o wolè ni ìlá. Níbi ti o wolè sin i a n pe ni Ìgbonnìbí loni yìí.

Ajagúnlá: Ode ni ajagunle nigba aye re, o si je jagunjagun O si bínú wolè lo ni.

Ògbún Ìperin: Nibi ti a pa Erin sin i a n pe ni ìperin

Òkè-Èdè: túmò si ibi ti a pa elédè si

Ògbún ìsèdó: Eyi tumò si ibi ti isé sodo si. Agbègbè yin i ìlú ma n lo gégé bi ojúbo isé.

Ilé- Olóòsà! A gbo pe wón ma n ko òrìsà pamó sì adugbó yií.

Òkè-Alóyin: Odò kan ti o n san ni àdúgbò yì, wón ma n lo omi yì láti fi se ìmúláradá àwon omo wéwé.

Ilé-Agbérùkóó: A gbó pe ìdílé yì ma n gbe èrúkó tà, ni won fi ma n pé wón ni agbérùkóó.

Ilé-Alápìnni: Ìtàn so pe idile Oloje tabi eleegun ni won je. Àwon sin i Olórí gbogbo àwon eégún.

Ilé-Ìyálóde: Obìnrin ni o te idile yi do, O gbé fáàrí O sit un je akikanju obinrin láàrin ìlú.

Ilé-Akogun: Jagunjagun naa ni o te adugbo yi do Akogun sit un je Oloye pàtàkì ni ìlú

Ilé-Òjá-bèbè: Isé abèbè ni wón yàn láàyò ni àdúgbò yì.

Ìlé-Agbèdègbede: Àwon ìdílé Alágbède ni àwon wonyi n se.

Ilé-Òdú: Èfó òdú ni won ma ngbin ni akoko ti won so orúko ile yii.

Ilé-Ajengbe: Isé Ìsègùn ni won ma n se ni ìdílé yi. Won sit un je akoni èdá kan.

Ilé-Obajisun: Ìdílé oba ni won jé won sì tun je Olóyè ìlú. Èfó òsùn pò púpò nì àdúgbò yìí

Ilé-Onílù: Àwon àyàn ni o te ile yìí do, ìdílé onilu ni àwon wonyi je

Ilé-Awúgbo: àwon ìdílé yi saba ma n gbìn erè kan ti a n pen i awúje, èyítí o ti gbilè ti won fi n pe won lórúko loni.

Ile-Èelemukan : Èkan po ni àdúgbò yìí

Ìle-Obajoko: Idile yin i won ti ma n sábà fi Oba je, eyìti a mo si kugmaker.

Òkè-Ògbún: Nígbàtí ìlú ko ti làjú àdúgbò yin i wón ma sábà ko gbogbo àwon òhun ìdòtí pamó si, o si je ògbun eyìti wòn so di oke-ògbún lòni yì.

Ilé-Àtèéré

Ilé-Àbálágemo:

Ilé-Asóyòò:

Ilé-odogun: Ìdílé àwon jagunjagun ni won.