Wọ́n gba orin-ìyìn orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ "Arise O Compatriots" tí ìtumọ̀ lédè Yorùbá jẹ́ "Ẹ dìde Ẹ̀yin Ará" wọlé gẹ́gẹ́ bí orin-ìyìn orílẹ̀ èdè náà lọ́dún 1978, tí wọ́n sìn fi í rọ́pò orin ìyìn àtijọ́ tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ "Nigeria, We Hail Thee", tí ìtumò rẹ̀ lédè Yorùbá jẹ́ "Nàìjíríà, Ayìn Ọ́"
It was adopted in 1978 and replaced the previous national anthem, "Nigeria, We Hail Thee".[1]
Ohùn orin-ìyìn jẹ́ àpapọ̀ ọ̀rọ̀ àti awẹ́-gbólóhùn tí wọ́n pò pọ́ láti márùn-ún àwọn orin ìyìn orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tí wọ́n fi díje àpapọ̀ lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Ẹgbẹ́ akọrin àwọn Ọ̀lọ́pàá lábẹ́ ìṣàkóso Benedict E. Odiase ni wọ́n pawọ́n pọ̀ tí wọ́n sọ ọ́ di Orin-ìyìn orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tí à ń kọ́ báyìí. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé abala méjì ni Orin-ìyìn yìí wà, abala àkọ́kọ́ ni wọ́n sáàbà máa ń kọ, ṣùgbọ́n nígbà mìíràn ẹ̀wẹ̀, wọ́n máa ń kọ abala kejì gẹ́gẹ́ bí "Orin Ìwúre fún Nàìjíríà" ní àwọn ayẹyẹ mìíràn.[2][3]
Orin-ìyìn orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Lédè Yorùbá, Abala Àkọ́kọ́