Oron Museum
Oron Museum[1] jẹ́ ilé tí àwọn ohun ìṣẹ̀mbáyé lọ́jọ̀ sí tí wọ́n da sílẹ̀ ní ọdún 1958, tí ó wà ní ìlú Oron [2] ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà . Wọ́n da ilé ìṣẹ̀mbáyé yí sílẹ̀ ní ọdún 1958 láti lè kò àwọn ohun ìṣẹ̀mbáyé àtijọ́ tí wọ́n tó ọgọ́rún mẹ́jọ, tí wọ́n ṣe pàtàkì sí àṣà àti ìṣe àwọn ẹ̀yà Oron tí wọ́n gbà wípé wọ́n wà lára àwọn ẹ̀yà tí wọ́n ti pẹ́ jùlọ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí wọ́n sì jẹ́ ẹ̀yà tí wọ́n mọ iṣẹ́ gbẹ́nàgbẹ́nà ṣe jùlọ ní ilé ilẹ̀ Adúláwọ̀.[3] Lásìkò ogun kan, wọ́n ṣe ìkọlẹ̀ sí ilé ìṣẹ̀mbáyé náà tí Won sì jí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn igi tí wọ́n ti ṣiṣẹ́ ọnà sí lára náà kó lọ, tí wọ́n sì ilé ìṣẹ̀mbáyé na jẹ́ pẹ̀lú.[4] ọdún 1975, ìjọba tún ilé ìṣẹ̀mbáyé náà dìde padà tí wọ́n sì ṣe àwọn igi tí wọ́n ti ṣiṣẹ́ alárambarà sí lára tí wọ́n ṣẹ́kù àti àwọn míràn káàkiri orílẹ̀-èdè Nàìjíríà síbẹ̀. Lára àwọn igi tí wọ́n pátá rẹ̀ síbẹ̀ ni odi tí wọ́n fi dáàbò bo àwọn ohun ìṣẹ̀mbáyé náà lásìkò ogun àti àwọn nkan míràn tó kú sínú ìlú náà lẹ́yìn ogun.
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Oron Museum". Academic Dictionaries and Encyclopedias. Retrieved 2023-08-14.
- ↑ "AFRICA". 101 Last Tribes. Retrieved 2023-08-14.
- ↑ Nigerian Embassy
- ↑ "CBCIU calls for repatriation of Nigeria’s cultural objects". Tribune Online. 2022-03-23. Retrieved 2023-08-14.